Ìfẹ̀hónúhàn wáyé káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, bèèrè fífi òpin sí ìjínigbé

Bi ọ̀ọ̀dẹ̀ araalu ko ba dun, bi ìgbẹ́ ni gbogbo ilu pata yoo maa ri lojuu wọn, wọn yoo si maa fi ẹhonu han bi anfaani rẹ ba ti yọ.
Latari bi nnkan ko ṣe fararọ kaakiri lorilẹede Naijiria bayii, paapaa lẹka aabo ati ọrọ aje, ọpọ araalu ni inu wọn ko dun.
Eyi lo mu wọn tu jade layaajọ ijọba Demokresi to waye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Wọnyi ni awon ipinlẹ tawọn eeyan ti jade fẹhonu han, ohun ti wọn wi atawọn ohun to ṣẹlẹ nibẹ
Abuja: Ẹ sọ fun Tinubu ko fi ipo silẹ, o ti rẹ̀ ẹ́ - Omoyele Sowore

Bi iwọde ṣe bẹrẹ ni deede aago mẹjọ aarọ oni, ni awọn oluwọde lẹgbẹ-lẹgbẹ-lọgba ati ọgọọrọ eyan ti ya wọ ilu Abuja lati fi ẹhonu wọn han nipa ohun ti wọn n la kọja .
Ki eto iwọde ọhun too bẹrẹ ni agbegbe Berger to wa niluu Abuja ni oludari ẹgbẹ 'Take-It-Back Movement', Omoyele Sowore, ti sọrọ nipa àìsi ààbò, íjínigbé, ìṣòro ọrọ̀ ajé,ai si ìdàgbàsókè, ọwọngogo ọjà àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni Sowore sọ pe bii igba ti ijọba awaarawa yii n pada sẹyin ni, ko si ilọsiwaju lẹyin ọdun mẹtalelogbọn ti Demokresi ti wa.
Sowore sọ pe o ti rẹ Aarẹ Bola Tinubu, niṣe lo yẹ ko ko ẹru rẹ ko maa lọ.
"Kekere leleyii o, bi ko ba si ayipada, ọpọ araalu ṣi maa jade ti wọn maa ṣe ohun ti a mọ si Revolution, to lagbara ju eyi lọ."
Bẹẹ ni Ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore wi.
Ohun ti awọn oluwọde n beere:
Gẹ́gẹ́ bí Ọmọyẹle Sọwọrẹ atawọn miiran se sọ, ohun ti wọn n beere ni :
- Kí ìjọba gbe igbesẹ lori íjínigbé.
- Kí ààbò àwọn aráàlú túbọ̀ dára sí i.
- Kí iṣoro ọrọ aje kasẹ nilẹ patapata, ki owo ounjẹ walẹ lọja.
- Ifagile awọn ètò ti ko mú ìgbésí ayé rọrun.
- Kí àwọn akẹkọọ ati awọn olukọ ti wọn ji gbe pada sile kaakiri orilẹ ede Naijiria.
Lasiko kan laarin iwọde naa, awọn agbofinro ati ikọ ọmọ ogun bẹrẹ si i yin ẹrọ tajutaju sawọn olufẹhonuhan naa.
Eyi ṣẹlẹ nigba ti wọn de oju popo to lọ si Eagles Square, ati ọ̀nà tó lọ sí Ilé Ààrẹ Tinubu.
Osun: A ko fẹ ipaniyan ati ijinigbe mọ ni Naijiria, ki ijọba Bola Tinubu fopin si iya yii kia

Deede aago mẹwaa ku iṣẹju mọkandinlogoji ni awọn ọdọ ipinlẹ Osun bẹrẹ iwọde ifẹhonuhan lori eto aabo to mẹhẹ lorile-ede Naijiria.
Orisiirisii ẹgbẹ lo parapọ nibi iwọde ifẹhonuhan naa, awọn bii Civil Society Organization ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ninu ọrọ Waheed Lawal, Alaga ẹgbẹ Civil Society Organization, o bu ẹnu atẹ lu ìṣèjọba Aarẹ Bola Tinubu latari bi ko ṣe si eto aabo to peye, ati bi ọwọn gogo ounjẹ ṣe di wahala niluu.
Lawal tẹsiwaju pe kijọba Tinubu tete wa gbogbo ọna lati gba awọn akẹkọ ati olukọ tawọn ajinigbe ko lọ ni Ogbomoso, ati ni awọn ipinlẹ miran silẹ.
Ẹlomin-in lara awọn ọdọ naa, Saka Lawal, sọ fun BBC News Yoruba pe:
"A ko ti i gbadun ijọba awaarawa rara lorile-ede Naijiria latigba ti ijọba awarawa ti bẹrẹ.
Saka salaye pe awọn eeyan Naijiria ko ti I ni iriri ijọba awarawa rara, ohun ti wọn n dojuko lasiko yii pọ.
"Ipaniyan ati ijinigbe ti pọ ju ninu iṣejọba awaarawa lorilẹ-ede Naijiria yii.
"Ohun ti a fẹ ni pe ki Aarẹ Bola Tinubu tete ṣe atunṣe si rudurudu to gba orile-ede Naijiria lasiko yii, ki nnkan ma baa bajẹ kọja bo ṣe yẹ."
Nibi iwọde ọhun, orisiirisii patako ni awọn oluwode gbe lọwọ, ti akọle naa ṣe afihan ko si eto aabo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni awọn kan n pe aarẹ lawọn orukọ to tabuku iṣejọba rẹ, wọn ni awọn ko faramọ bo ṣe n lọ rara.
Oyo: Bi isejọba ba le fun ọ, kọwe fipo silẹ
Awọn olugbe ilu Ibadan to ṣe iwọde nitori aisi isejọba awaarawa to tọ rọ aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati kọ we fiṣẹ silẹ ti isejọba ba ti daru mọ loju.
Awọn olufẹhonuhan naa ti Amofin Femi Aborisade ati awọn ajafẹtọọ ọmọniyan mi kowọpọ pẹlu ṣe iwọde ni, ilu ko rọgbọ bẹẹ si ni eto aabo Orilẹ-ede yii ko gbopọn rara.
Awọn olufẹhonuhan naa lo bẹẹrẹ ifẹhonuhan wọn lati iwaju Fasiti Ibadan titi lọ si agbegbe Makola nibiti wọn ti fi adagba iwọde wọn rọ.
Amofin Aborisade ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ṣalaye wi pe, bi eto aabo ati bi awọn ohun elo ṣe n gbowo lori fihan wi pe ijọba ko mo ohun to yẹ ko se.
O woye pe, ko fẹẹ si iyato laarin ijọba ologun ti awọn ṣe iwọde le lori ati ijọba awarawa to wa lode oni.
"Ta ba fẹ ki igbesunmomi dopin, ki Ijọba fopin si, airilegbe, ai romi lo, ai rounjẹ jẹ, ai risẹ ṣe lo n fa ti awọn kan fi n gbe awọn eeyan.
"Nigba ijọba ologun ao jade lati sọ wi pe a n ṣe iwọde pe wọn pa eeyan, nigba ijọba tiwatiwa ni a wa jade pe ki ijọba ko ṣe gbogbo oun to le ṣe ki awọn ọmọ ile ẹkọ ati awọn olukọ wọn ti wọn gbe, ki wọn fi wọn silẹ, ki ṣe ilẹ Yoruba nikan, kaakiri Orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti jii awọn eeyan gbe.
Nigba ti o n ṣe afọmọ iyatọ laarin ijọba Ologun ati ijọba Tiwa Tiwa, Aborisade ni "ko si iyatọ laarin ijọba Ologun ati ijọba tiwa tiwa nissininyi nitori, awọn ijọba n fi ebi paa ara-ilu"
O ku o ku nibon n ro, ni awọn to n ṣe iwọde naa sọ, wọn ṣeleri lati tesiwaju ninu iwọde wọn titi ti ijọba apapọ yoo fi fopin si igbeṣumọmi, ati igbe aye alafia fun gbogbo ọmọ orile-ede yii.

























