Ìtàn Mánigbàgbé: Ìdí tí Ọba alayé nílẹ̀ Yorùbá kìí ṣe dúró níbi tí wọn ti ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú

Oríṣun àwòrán, ooniadimulaife/Instagram
Eewọ ni fun ọba nilẹ Yoruba lati foju ri oku tabi duro nibi ti wọn ti n pa eeyan.
Kii se pe wọn se eewọ yii fun wọn amọ isẹlẹ kan lo waye laye ijọun ti eyi se ri bẹẹ.
Ilu Oyo si ni itan naa ti waye laye ọba Alaafin Ajaka tii se arakunrin Sango.
Lara awọn Aláàfin to tí jẹ́ nilu Oyo, tí ìtàn kò lè gbàgbé wọn ní Aláàfin Àjàká wá.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtàn Yoruba ti Àlùfáà Samuel Johnson kọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ṣe fi ye wá, ẹẹmeji ni Aláàfin Àjàká jọba.
Inu iwe naa si lo ti salaye idi to se di eewọ fun awọn ọba nilẹ Yoruba lati fi oju ri oku tabi wa nibi ti wọn ti n pa eeyan.
Nígbà tó jẹ́ ọba nígbà àkọ́kọ́, ó jẹ ọba oníwà pẹ̀lẹ́, tí ìwà rẹ tútù pupọ èyí tí kò dùn mọ́ àwọn èèyàn ìlú Oyo nínú.
Ìdí rèé tí wọn ṣe rọ̀ ọ́ lóyè, tí wọ́n sì fi Sango, tíí ṣe arákùnrin rẹ jẹ Aláàfin dípò rẹ.
Sango jẹ alágbára àti oníwà líle àmọ́ lẹ́yìn tí Sango kú tán, Àjàká padà jẹ Aláàfin fún ìwà kejì, to si di eeyan lile.
Nígbà ayé Aláàfin Àjàká, onírúurú ogún lo ja nínú ilé àti lẹ́yìn odi.
Aláàfin Àjàká yìí sí ní àwọn ìjòyè tó jẹ́ jagunjagun tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́ta (1,060).
Lara awọn ìjòyè náà ni a ti rí àwọn ọba ìlú kereje kereje bíi Onikoyi, Olugbon àti Aresa.
Yàtọ̀ sí èyí, Aláàfin Àjàká tún ní àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ pupọ to máa ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn fún.
Lara wọn la ti rí Atagbọin, ọmọ Onikoko, Abitibiti Oníṣègùn, Paku, Tẹtẹ-oniru, Yana, Oko-Adan Ẹgbẹji, Alari baba ìṣègùn àti Elenre.
Àwọn ìtàn ni oriṣiiriṣii ni ó wà ní àkọsílẹ̀ nípa Aláàfin Àjàká èyí tó ṣòro láti fi idi rẹ mulẹ, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì lo ṣeeṣe ko jẹ ìtàn arosọ lásán.
Lara ìtàn náà ni ìtàn nípa ìdí tí ọba ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe dúró síbi tí wọn ti ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú.
Alaafin Ajaka kọ lati jẹ ki awọn onisegun rẹ lọ bẹ ile wo
Ni ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí Aláàfin Àjàká àtàwọn jagunjagun pẹlu oníṣègùn rẹ tí ojú ogún de, wọn bẹ Kabiyesi pé kó jẹ́ kí àwọn máa lọ sílé.
Àmọ́ Aláàfin Àjàká kò gbà láti fi wọn silẹ nítorí ìbẹ̀rù pé wọn lé ṣe àwọn òògùn tí wọn ti ṣe fún òun, fún àwọn ọba miran.
Lẹyin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀ àmọ́ tí Aláàfin Àjàká kò dá wọn lóhùn, àwọn oníṣègùn yìí wa fárígá pé àwọn kan ṣe apọnle ọba lásán ni.
Wọn ni Aláàfin Àjàká kò tó láti dá àwọn dúró láti máṣe lọ sílé àwọn.
Paku lo kọkọ ṣubú lulẹ̀ laarin awọn oníṣègùn náà, tó sì pòórá níwájú ọba.
Atagbọin, ọmọ Onikoko, Abitibiti Oníṣègùn, Tẹtẹ-oniru, Yana áti Alari baba ìṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn pòórá níwájú ọba bakan naa.
Ẹgbẹji ń tìẹ ju òwú tí wọ́n ti tà, tó tóbi bíi bọọlu sókè, òwú náà rọ wá silẹ láti orí ofurufu to dúró sí.
Ṣé ni Ẹgbẹji so mọ òkun náà, ó rọ lọ soju òfurufú, to si pòórá.
O wa kú Elenre nìkan níwájú ọba.
Iyawo Elenre tu asiri agbara ọkọ rẹ, Alaafin ni ki wọn bẹ Elenre lori
Aláàfin Ajaka wá sọ fún Elenre pé kó jẹ́ tètè ṣe báwọn yoku rẹ tí se, bí bẹẹ kọ, òun yóò gbẹ̀san ohun tí àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ ṣe lára rẹ torí inú wọn tí ń bí òun.
Elenre wá fèsì padà fún Aláàfin pé ko wa pa òun, bí Kabiyesi bá to bẹẹ.
Aláàfin Ajaka wá pàṣẹ pé kí wọn ṣa a ní ọ̀kọ̀, títí tí yóò fi kú.
Àmọ́ ni igbá méjèèjì tí wọn fi ọkọ sa a, ṣe ni ọkọ náà ń ṣẹ́ sì méjì lai wọnú ara Elenre.
Aláàfin Ajaka tún pàṣẹ pé kí wọn fi idà ṣa àmọ́ bí wọn ṣe gbé idà sókè láti sá a, ní idà kan sì méjì, tí ọwọ́ ẹni tó gbé idà náà sì rọ.
Ọba tún pàṣẹ pé kí wọn yí òkúta ńlá lu Elenre, kò sì lọ ọ womuwomu àmọ́ ṣe ni òkúta náà dabi ìdì òwú lásán lara rẹ, tí kò sì tú irun kankan.
Ìyàwó Elenre to n jẹ Ijaẹhin wá gba ọba nimọran pé irin kankan kò le rán Elenre.
O ni ohun kansoso to lè ṣẹgun rẹ ni kí wọn lọ yọ ẹyọ koríko kan lára ilé koríko tí wọn ń gbé lásìkò náà.
Ijaẹhin ni ẹyọ koríko yìí ni kí wọn fi na Elenre láti ṣẹgun rẹ.
Wọn ṣe bí Ijaẹhin tí gba ọba nimọran, tí orí Elenre sì ré bọ lọrun rẹ àmọ́ dípò kí orí náà bọ silẹ, ṣe ló fo lọ sí atẹlẹwọ Aláàfin Ajaka, tí kò sì sí kúrò nibẹ.
Ori Elenre ati aya rẹ di odo nilu Oyo
Gbogbo ipa ni ọba ṣa, orí Elenre kò sì kúrò lọ́wọ́ Ọba.
Gbogbo oúnjẹ, omi àti ọtí tí wọn ba si gbe wa fún Aláàfin Ajaka, orí Elenre lo n jẹ gbogbo rẹ.
Nígbà tó pẹ díẹ̀, Aláàfin Ajaka tí ru kan eégún torí àìrí oúnjẹ jẹ, tí èmi sì fẹ́ bọ́ lẹ́nu rẹ.
Wọn lọ bẹ gbogbo àwọn oníṣègùn to wa nilu pé kí wọn wá gbé orí Elenre àmọ́ bí wọn ba ṣe wọlé ní orí Elenre yóò ká àwọn èròjà tí wọn fi ṣe oogun fún wọn.
Orí Elenre yóò wà bí wọn pé ṣe wọn ró pé àwọn èròjà isegun náà lè ràn òun bí?
Àmọ́ ni ọjọ́ kan, oníṣègùn alágbára kan tí wọn ń pè ní Aṣawo de sí ààfin Ajaka.
O lọ bá Orí Elenre to wa lọ́wọ́ Ọba, dípò kó ṣe akọ tàbí ìgbéraga táwọn oníṣègùn to síwájú rẹ ń ṣe, ṣe ni Aṣawo dọbalẹ, to si n bẹ orí náà pé òun kan wà jẹ ìpè ọba lásán ni, òun kọ́ tó bẹ́ẹ̀ láti yọ orí náà.
Inú orí Elenre dùn sí ìwà irẹlẹ Aṣawo yìí, ó ní òun òun yóò bọ̀wọ̀ fún un torí pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí kò sì gberaga níwájú òun.
Kia ni ori Elenre náà bọ silẹ fúnra rẹ lọ́wọ́ Aláàfin Ajaka, to si di odò nla ti wọn n pe ni odo Elenre nilu Oyo titi di òní yìí.
Bákan náà, aya Elenre to n jẹ Ijaẹhin, to tú àṣírí agbára ọkọ rẹ, náà fò sanlẹ, ó sì di odò ńlá.
Àmọ́ orí Elenre pàṣẹ fún odò tí ìyà wo rẹ dà pé ko gbọdọ san, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Odò náà sì jẹ adágún odò títí di òní olónìí.
Kia ni ọba Ajaka sì pàṣẹ pé láéláé, ọba kankan nílẹ̀ Yorùbá kò gbọ́dọ̀ máa dúró níbi tí wọn ba ri ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú mọ.


























