Kí ló dé tí aráàlú fi ń ṣe ìwọ́de torí ìfilọ́lẹ̀ Naira tuntun?

Lati ipari osu Kinni ọdun 2023 ti banki apapọ ilẹ wa ti bẹrẹ amulo Naira tuntun, ni eku ko ti ke bi eku mọ, ti ẹyẹ ko si fọhun bii ẹyẹ.
Awọn beba Naira tuntun naa ni beba alapapọ igba Naira (N200), ẹlẹẹdẹgbẹta Naira (500) ati ti ẹlẹgbẹrun kan Naira(N1000).
Awọn araalu ni ko ri awọn owo tuntun naa gba, ti ijọba si ti gba Naira atijọ lọwọ wọn.
Eyi si lo tun mu ki ijọba sun gbedeke nina owo Naira atijọ siwaju di ọjọ Kẹwa osu Keji ọdun 2023.
Amọ lẹyin ti gbedeke February 10 yii wa sopin, ọwọn gogo Naira yii n peleke si ni, eyi to n mu inira nla bawọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn olokoowo.
Se si lawọn araalu n ra beba Naira lọwọ awọn eeyan to n lo ẹrọ POS pẹlu ele ida ogun, eyi to mu ki isẹ ati osi tubọ peleke si lawujọ wa.
Ibinu airi Naira tuntun na yii ati bawọn eeyan se n kọ Naira atijọ, lo mu kawọn araalu fọnmu, ti wọn si bẹrẹ iwọde lawọn ilu nlanla lẹkun guusu Nairia.
Awọn ilu naa ni Ibadan, Benin, Warri, Portharcourt ati Ilorin, bi wọn se n sun taya mọto loju popo, koda, awọn iwọde naa lo ti mu ẹmi awọn eeyan kan lọ.

Bayii ni ọwọn gogo Naira se tan ka gbogbo Naijiria:
Ireti awọn araalu ni pe awọn yoo ko iye Naira atijọ lọ si banki, ti wọn yoo si gba Naira tuntun iye owo naa pada.
Sugbọn se ni banki apapọ ilẹ wa, CBN fi ikede sita pe araalu ati ileesẹ kọọkan ko le gba ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira lọ ni ojumọ ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ni ọsẹ kan ni banki.
Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba tawọn ile ifowopamọ yika Naijiria ko fi owo tuntun paarọ Naira atijọ mọ , ti wọn si n fi owo atijọ san owo fawọn araalu nigba ti gbedeke February 10 si ku ọjọ perete.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Mary Temitope nilu Osogbo, tii se olu ilu ipinlẹ Osun ni ipo ti gb ogbo nnkan wa buru jai.
“Se ni ọpọ eeyan n jiya nitori aisi Naira lati na. Emi gan to sori ila to gun lọ gbọrọrọ ni ọpọlọpọ banki, ki n le ri ẹrọ ATM wọn lo.
Nigba miran, se ni maa to awọn eeyan sori ila, lati lọ to de mi nitori emi nikan ko le duro sori ila ni ọna pupọ.
Inira nla si ni ki eeyan to fun ọpọlpọ wakati lati gba ẹgbẹrun mẹwa Naira atabi ẹgbẹrun marun pere, Iranu gbaa ni, o si gbọdọ tete wa sopin.”
"Mo fi N100 ransẹ lori ayelujara lati sanwo kẹkẹ Maruwa, n ko ro pe mo le se bẹẹ laye mi"
Amọ o dabi pe ilana banki CBN ni lati mu adinku ba iye beba Naira to wa laarin ilu, ki wọn si mu idagbasoke ba ilana fifi owo ransẹ lati ori ayelujara to sẹsẹ sefilọlẹ rẹ.
Lati igba ti beba Naira si ti di imi eegun, lawọn eeyan ti siju si amulo ilana fifi owo ransẹ lori ayelujara bi o tilẹ jẹ pe ariwo ti gbalẹ kan pe igbesẹ naa ko ni dangajia to tori ikuna intanẹti.
Steve Odumukwu, to n gbe nilu Awka jẹ ọkan lara awọn eeyan to yan ilana fifi owo ransẹ lori ayelujara laayo, titi debi pe o n fi sanwo mọto.
“Mo fi ọgọrun Naira ransẹ lori ayelujara lati sanwo kẹkẹ Maruwa, n ko lero pe mo le se bẹẹ laye mi."
Niwọn igba ti ijọba fẹ se iwuri fun ilan a fifi owo ransẹ lati ori ayelujara, amọ ko yẹ ki ohun gbogbo buru to bayii.
Itumọ awọn isẹlẹ to n waye yii ni pe ilana ti wọn gbe kalẹ ko sisẹ, bẹẹ ni akoko ti wọn kede lati se ifilọlẹ ilana naa kere jọjọ.”

Awọn eeyan n binu gidigidi
Ọpọ araalu lo ti fa ibinu yọ lawọn ilu kan lorilẹede Naijiria nitori ọwọn gogo Naira yii, ti gomina CBN, Godwin Emefiele si ni Naira atijọ to to Trilliọnu meji o din diẹ ni wọn ti da pada sọdọ oun.
Awọn eeyan tinu n bi lori isẹlẹ yii lo si di oju ọna agbegbe Ozuoba ati Rumuosi nilu Port Harcourt.
Nilu Benin, se lawọn iyalọja gba oju popo kan lati fi ẹhonu han lori ọwọn gogo Naira naa, ti awọn ero naa si gbiyanju lati yabo banki CBN, bi kii ba se awọn ọlọpaa to fi afẹfẹ tajutaju ati iro ibọn tu wọn ka.
Awọn fidio kan fidi rẹ mulẹ pe ibọn ba ọkunrin kan nikun, amọ a ko le sọ boya o ye isẹlẹ naa.
Iwọde naa lo tun tan de ilu Ilorin,tii se olu ilu ipinlẹ kwara amọ ohun gbogbo ti n pada bọ sipo bayii.
Aarẹ Muhammadu Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọrọ
Aarẹ Muhammadu Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọrọ nitori pe ifẹhonuhan naa le fọnna soju, to si n bẹbẹ fun alaafia.
O wa seleri lati wa ojutu si ọwọn gogo Naira naa laipẹ laijinna.
Buhari ni wọn yoo da beba igba Naira atijọ npada saarin ilu, ki wọn si maa na owo atijọ naa papọ mọ Naira tuntun titi ọjọ Kẹwa osu Kẹrin ọdun yii.



























