Kí ló dé tí ẹnu ń kun Bàbá Ijesha lẹ́yìn tó kéde ọmọ tuntun?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni alẹ ọjọ Aje, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹfa ọdun 2026 ni ori ayelujara bẹrẹ si ni mi titi lẹyin ti iroyin gbode pe gbajumọ oṣere tiata Olarenwaju Omiyinka ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha di baba ikoko.

Ninu fidio kan ti Baba Ijesha fi soju opo Instagram rẹ lo ti kede iroyin pe oun ati iyawo oun, Ceoluminee ti bi ọmọkunrin to pe orukọ rẹ ni King Kagar.

O ni awamaridii ni iṣẹ Ọlọrun to si ṣe iṣẹ ọwọ rẹ ni idakẹjẹjẹ ninu aye oun pẹlu bo ṣe fun awọn ni ọmọkunrin lantilanti.

Ikede yii lo n waye nib ii oṣu meje lẹyin ti Baba Ijesha pari ẹwọn ti ile ẹjọ ni ipinlẹ Eko ju u si fun ẹsun biba ọmọde lopọ.

Ọpọ eeyan ni iroyin naa ya lẹnu nitori Baba Ijesha ati iyawo rẹ, Abiodun Folashade Tokunbo ti ọpọ mọ si CEO Luminee ko figba sọ ọ sita ri pe ajọṣepọ kankan wa laaarin wọn titi di ọjọ Aje ti wọn kede bibi ọmọ naa.

Niṣe ni awọn eeyan mii ti ẹ n sọ pe boya awọn mejeeji kan gbe fidio naa jade lati fi polowo ọja kan tabi boya awọn fidio ori ayelujara lasan ni.

Amọ o jọ pe ọrọ naa di ootọ mọ gbogbo eeyan lọwọ lẹyin ti fidio igba ti awọn ọrẹ Luminee ṣe ayẹyẹ fun-un nigba to wa ninu oyun.

Bẹẹ naa ni gbajumọ oṣere Yomi Fabiyi ti o jẹ ọrẹ Baba Ijesha fun igba pipẹ naa gbe fidio naa soju opo rẹ, to si ki awọn tọkọ taya naa ku oriire.

Bakan naa ni Luminee ninu ohun to ko soju opo Instagram rẹ sọ pẹ ayọ ọjọ pipẹ ti oun n reti ni ọmọ tuntun ti awọn ṣẹṣẹ bi naa, to si fi ọmọ tuntun sabẹ abo Ọlọrun.

Ta ni iyawo Baba Ijesha to ṣẹṣẹ bimọ tuntun?

Ọkan ninu awọn gbajumọ to maa n ran aṣọ fun awọn gbajugbaja oṣere paapaa awọn oṣere fiimu Yoruba ni Abiodun Folashade Tokunbo.

Orukọ ileeṣẹ aranṣẹ rẹ ni CEO Luminee, ohun si ni ọpọ eeyan mọ ọn si.

Oun ati Baba Ijesha ko sọ igba ti ifẹ aarin wọn bẹrẹ tabi igba ti wọn ṣe igbeyawo, o pe Baba Ijesha ninu atẹjade to kọ soju opo Instagram rẹ nigba ibi ọmọ wọn.

Ṣé ẹlẹ́wọ̀n le ní ìbálòpọ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?

Lati igba ti Baba iIjesha ti kede ayọ ọmọ tuntun naa ni oniruuru ibeere ti n jade nipa igba ti Baba Ijesha kuro lọgba ẹwọn ati iye oṣu ti obinrin fi n gbe oyun.

Eyi lo n waye nitori inu oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni Baba Ijesha kuro ni ọgba ẹwọn to tumọ si pe ko tii ju oṣu meje lọ.

Ibeere to gba ẹnu ọpọ eeyan ni pe ṣe igba ti Baba Ijesha wa ni ọgba ẹwọn lo ni ibalopọ pẹlu iyawo rẹ ni abi leyin to jade.

Amofin Abdulfatai Adabaale sọ fun BBC News Yoruba pe ofin Naijiria ko fi aaye gba ibalopọ fun ẹni to ba wa lẹwọn.

Adabaale ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ajafẹtọ ọmọniyan kan ti n dide lati beere fifi aaye gba awọn ẹlẹwọn ti wọn ba ṣi w ani ọjọ ori lati ni ibalopọ lati maa ṣe bẹẹ nitori ilera wọn, o ni ijọba ko i tii buwọlu ofin bẹẹ.

"Ko si ofin kankan labẹ ofin Naijiria to fi aaye gba ẹlẹwọn lati maa ni ibalopọ nigba to ba n ṣẹwọn lọwọ."

Nigba ti Amofin Ademola Owolabi n sọrọ ni tirẹ, o ni ọpọ ẹtọ ni awọn to ba wa ni ọgba ẹwọn maa n nib ii ẹtọ si ounjẹ, ohun mimu, igbe aye to rọrun atawọn mii.

Owolabi ni awọn ẹlẹwọn tun ni ẹtọ si lati dibo lasiko ibo amọ wọn ko ni ẹtọ lati ni ibalopọ yala pẹlu ara ita tabi ẹlẹwọn bii ti wọn.

O ni eyi ri bẹẹ nitori ẹlẹwọn obinrin to ba jẹ pe idajọ iku ni wọn da fun-un le tara ibalopọ to ba ni loyun, ti wọn ko si ni le pa a mọ titi to maa fi bi ọmọ naa.