You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ làwọn agbésùnmọ̀mí Lukarawa láti Apá Àríwá ti wọ inú igbó lọ l'Ogbomoso? Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo ti sọ̀rọ̀
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti ṣalaye wi pe irọ nla ni fidio kan to ṣafihan awọn afurasi agbebọn lori alupupu loju popo eyi tawọn eeyan kan sọ pe awọn agbesunmọmi Lukarawa lo n rinrin ajo lati apa ariwa Naijiria lọ sinu igbo ilu Ogbomoso ati igbo ọba Old National Park nipinlẹ Oyo.
Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo sọ ninu atẹjade kan to fi sita loju opo X rẹ wi pe fidio naa ati ohun to wa nibẹ ko lẹsẹ nlẹ rara.
Gẹgẹ bi alaye ti ile ileeṣẹ ọlọpaa ṣe, wọn ni fidio naa ti pẹ, ati pe awọn kọlọnbiti eeyan kan lo n pin fidio ọhun kiri lati da ipayan silẹ nipinlẹ Oyo.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ araalu wi pe ki wọn yago fun iwa pinpin iroyin ofege lori eto aabo kaakiri, papaa julọ iroyin ti wọn ko ba ṣe iwadii lori rẹ.
Amọ, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa Oyo ni awọn ko ni kaarẹ nipa pipese aabo to peye fawọn eeyan ipinlẹ naa.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ikọ ọlọpaa ti wa lawọn ibode ipinlẹ Oyo lati le koju awọn to ba fẹ wọ ipinlẹ naa lati ṣe iṣẹ ibi.
Wọn ni awọn ọlọpaa naa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọdẹ, awọn fijilante atawọn lọbalọba lawọn igberiko lati le jẹ ki iṣẹ idaabo bo araalu kẹsẹjari.
''Awọn agbofinro ti wa kaakiri ilu Ogbomoso to fi de inu igbo ọba Old Oyo National Park''
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo tun sọ loju opo X rẹ pe awọn agbofinro ti wa kaakiri ilu Ogbomoso to fi de inu igbo ọba Old Oyo National Park.
Wọn ni igbesẹ yii ṣe pataki lati fi dawọn araalu loju pe ijọba ko ni kaarẹ lati daabo bo wọn ati lati le awọn ọdaran jina.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa kepe awọn eeyan ti wọn n gbe ni igberiko atawọn ilu to wa leti ibode ipinlẹ Oyo wi pe ki wọn wa lojufo ni gbogbo igba.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun rọ wọn lati fi to awọn ọlọpaa leti ti wọn ba kẹéfin ẹnikẹni ti iṣesi rẹ ba mu ifura dani.
Ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe iwa ọdaran ni ki eeyan maa gbe iroyin ofege kaakiri, eyi ti ijiya wa fun labẹ ofin.
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo wa kilọ fun gbogbo ẹni to n gbe iroyin ofege kaakiri lati da ipaya silẹ wi pe ki wọn lọ so ewe gbejẹ mọ ọwọ, bi bẹẹ kọọ, wọn o foju wina ofin.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni oun yoo ṣe iwadii ẹnikẹni to ba n gbe iroyin ofege kiri, ati pe iru ẹni bẹẹ yoo foju wina ofin.