You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹgbẹ́ City Boys tó ń ṣàtìlẹyìn fún Tinubu l‘Oyo ṣàbẹ̀wó sí Esinele, gbé ohun èlò ìwòsàn kalẹ̀, àmọ́ ẹbí Tíṣà tí agbébọn pa kọ àpò ìrẹsì àti owó Ìyálọ́jà, tíí ṣe ọmọ ààrẹ
Adari ẹgbẹ City Boys Movement ni ipinlẹ Oyo, Olufemi Onireti ti ṣagbekalẹ awọn ohun elo etom ilera fawọn eeyan ilu Esinele ni ijọba Oriire, ni ipinlẹ Oyo.
Wọn ṣe agbekalẹ awọn ohun elo naa lasiko ti wọn ṣe abẹwo ibanikẹdun si ilu naa lori ijinigbe awọn olukọ atawọn akẹkọọ to waye ni awọn ilu naa laipẹ yii.
Nigba to n sọrọ lasiko abẹwo ọhun, Onireti fi ireti han pe wọn maa ṣawari awọn akẹkọọ atawọn olukọ tawọn ajinigbe naa ji gbe laipẹ, bi o ṣe ni pe ijọba n sapa wọn lati gba itusilẹ awọn eeyan naa.
O rọ awọn ilu naa lati ma ṣe ko aarẹ ọkan, ki wọn si maa gbadura, pe gbogbo akitiyan awọn ẹṣọ aabo atawọn tọrọ kan ko ja si pabo, to si fi idaniloju han pe akitiyan wọn n so eso rere.
"A ni aridaju rẹ pe awọn olukọ ati akẹkọọ naa maa pada sile layọ ati alaafia. Ijọba n ṣiṣẹ lai sinmi lati gba itusilẹ wọn. A wa sibi lati ṣe iranwọ ati ibanikẹdun fun awọn eeyan Esinele ni iru asiko ti nnkan le bayii ni."
Niṣe ni Onireti naa ko le ẹkun mọra nigba ti awọn obi awọn ọmọ to w ani ahamọ ajinigbe naa bẹrẹ si nib u omi loju, to si rọ wọn lati ma ṣe sọ ireti nu pe awọn ọmọ naa maa pada sile laipẹ lai jina.
"Awọn ọmọ yin maa pade de ayọ ati alaafia. A maa tẹsiwaju lati maa ṣe iranwọ fun-un, ti a o si maa gbadura pẹlu yin titi ti awọn ọmọ naa fi maa pada de."
Onireti fi kun pe awọn ohun elo ilera ti wọn gbe fawọn eeyan ilu naa yoo pese irọrun fawọn araalu, ti yoo si tun mu idẹkun ba wọn.
Lẹyin naa lo pese owo miliọnu kan naira fun awọn ebi oloogbe Michael Oyedokun, ọkan lara awọn olukọ to padanu emi rẹ lasiko ikọlu naa.
Bakan naa lo tun kede fifun awọn ọmọ meji ti olukọ naa fi saye, Oyedokun Abiodun ati Samuel Oyedokun ni ẹkọ ọfẹ ki eto ẹkọ wọn le tun tẹsiwaju.
Nigba to n sọrọ, Elesinele ti Esinele, Oloye Tajudeen Abioye gboriyin fun ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo fun akitiyan wọn lati igba ti iṣẹlẹ laabi naa ti waye.
Abioye ni awọn aṣoju ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ ni wọn ti yọju si ilu Esinele lẹyin ikọlu naa, ti wọn si jẹjẹẹ pe iṣẹ n lọ lati gba itusilẹ awọn ọmọ to wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.
O wa rọ ijọba atawọn ẹṣọ aabo lati tete gbe igbesẹ bi awọn ọmọ naa ṣe maa tete pada sile ni kopẹkopẹ.
Idile Michael Oyedokun ṣe kọ apo irẹsi ati owo ti ọmọ Tinubu fun wọn
Ṣaaju ni iroyin fidio kan ti gba ori ayelujara lọjọ Iṣẹgun pe awọn ẹbi oloogbe Michael Oyedokun kọ apo irẹsi meji ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ti ọmọ aarẹ Naijiria, Folashade Tinubu-Ojo fi ranṣẹ si wọn.
Ninu fidio naa ni ọkunrin kan ti sọ pe bi o tilẹ jẹ pe awọn iroyin kan n gbe pe ẹbi gba owo ati ounjẹ naa, ọkunrin naa ni irọ to jina si ootọ ni.
O ni loootọ ni Tinubu-Ojo fi ounjẹ ati owo naa ranṣẹ amọ iyawo oloogbe naa kọ wọn pe oku ọkọ oun ni oun n fẹ ki o le jẹ sinsin ni ilana to tọ.
Ọkunrin naa ni kawọn eeyan yago lati maa gbe iroyin ofege nitori inu ibanujẹ ni ẹbi naa wa ko si yẹ kawọn araalu maa dakun.
"Irọ patapata gba a ni, ko si ootọ ninu ọrọ naa, gbogbo awọn to n gbe iroyin yii, ẹ jẹ ka ṣọra wa o, ẹ ma tun dakun ibanujẹ to ti wa ninu idile yii.
"Ṣe raisi apo meji ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira lo maa da ẹmi ọmọ wọn ti wọn pa pada?
"Gbogbo awọn to n beere fun nọmba aṣuwọn banki iyawo oloogbe ni ko da lohun, pe awọn ko nilo owo lasiko yii."