Mà á ri dájú pé ààbò tó péye wà fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ọmọ Nàìjíríà – Tinubu

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti jẹjẹẹ pe oun maa ṣe aridaju rẹ pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn ọmọ orilẹ ede yii.
Tinubu sọrọ yii nigba to n kopa nibi ayẹyẹ ayajọ ileeṣẹ ologun Naijiria eyi ti aṣekagba rẹ waye ni Bareke Odogbo, ìlú Ibadan ni ipinlẹ Oyo.
Aarẹ Tinubu ẹni ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima ṣoju fun nibi ayẹyẹ naa ni ijọba to wa lode labẹ idari oun ti ṣetan lati ṣe ikunpa fun ileeṣẹ ologun Naijiria ki wọn le ṣe iṣẹ bo ti tọ.
O ni gbogbo iranlọwọ to wa ni ikawọ ijọba ni awọn maa ri daju pe awọn ṣe fun wọn ki aabo to daju le wa fun ẹmi ati dukia awọn ara ilu, ki awọn eniyan le fi oju le oorun lalẹ.


O ṣalaye pe ileeṣẹ ologun jẹ ọkan lara igbọkanle awọn ọmọ Naijiria fun aabo to yanranti ati lati ri daju ijọba awaarawa duro ire ni orilẹ ede yii.
Tinubu ni lati ọdun 1863 ni ileeṣẹ ologun ti wa, ti wọn si ṣe iṣẹ takuntakun lasiko ti a wa labẹ awọn oyinbo amunisin nipa pipese aabo to daju labẹle ati loke okun lati ogun agbaye keji.
Bakan naa lo ni ti a ba n sọrọ ipẹtu saawọ ni awọn orilẹ kan si omiran, ileeṣẹ ologun Naijiria ko kẹrẹ rara ti wọn si maa n fakọyọ ninu iṣẹ wọn.
O tẹsiwaju pe a gbọdọ ṣe ara wa ni ọkan lai ẹya tabi ẹsin ṣe ti ẹ ba fẹ ki orilẹ ede Naijiria ni ilọsiwaju ati idagbasoke to peye.
O rọ àwọn ọmọ Naijiria lati jina si awọn iwa tabi iṣe eyi to fẹ to le da omi alafia ilu ru tabi fa ipinya laaarin wa.
Awọn ohun ija igbalode lo wa ni ikawọ wa lati fopin si ipenija aabo - Lagbaja
Ninu ọrọ rẹ, olori ileeṣẹ ologun Naijiria, Taoreed Lagbaja ni awọn ọmọ ogun ti ṣetan lati koju gbogbo ipenija ati idojukọ to n ba eto aabo Naijiria.
Lagbaja ni awọn ohun elo ija igbalode ni o ti wa ni ikawọ awọn ti awọn yoo si ri daju pe awọn ṣe iṣẹ awọn bii iṣẹ paapaa tako awọn ti wọn maa n bẹ ọpa epo lọna aitọ.
O ni awọn nnkan to n ṣẹlẹ ni ẹkun Niger Delta lo maa jẹ afojusun awọn ni ọdun yii amọ awọn ko ni gbagbe awọn ẹkun orilẹ ede yooku pẹlu iṣẹ ti ijọba to wa lode gbe le awọn lọwọ.
O ṣalaye pe o pọn dandan fun awọn lati wa ojutuu ti awọn to n ji epo rọbi ti wọn n bẹ ọpa epo lọna aitọ nitori lati ẹka epo rọbi ni owo ida aadọrun-un owo to n wọ orilẹ ede yii ti n wa.
O fi ikọnilominu han pe iṣẹ laabi awọn to n bẹ ọpa epo yii ti ṣokunfa bi owo to n wọle labẹnu fun ijọba ti dikun jọjọ.
Bakan naa lo fi kun pe ileeṣẹ ologun labẹ idari oun ko ni diju si iwa igbeṣumọmi to n waye ni awọn apa ariwa Naijiria naa to si sọ aridaju rẹ pe gbogbo rẹ ni awọn maa rẹyin laipẹ ọjọ.
Lara awọn lookọ looki to ba peju síbi ayẹyẹ naa ni awọn ọba alade kaakiri Naijiria, àwọn gomina àti bẹẹbẹẹ lọ.
























