Amẹrika fòpin sí ìrànwọ́ rẹ̀ láti gbógun ti àrùn HIV/AIDS ní South Africa

Awọn to n ṣe ayẹwo ẹjẹ

Oríṣun àwòrán, Hoberman Collection/Universal Images Group via Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ilẹ Amẹrika ti kede pe oun yoo ṣẹwọle fifi owo ranṣẹ si South Africa lati gbogun ti itankalẹ aarun HIV ati AIDS.

O le ni miliọnu mẹjọ awọn ọmọ ilẹ South Africa to n gbe pẹlu aarun HIV, eyii to jẹ orilẹede ti aarun naa pọ si julọ ni gbogbo agbaye.

Igbesẹ ajọ US State Department yii ni o jọ pe o ni nnkan lati ṣe pẹlu bi ijọba South Africa ṣe kuna lati daabo awọn Afrikaner, iyẹn awọn alawọ funfun kereje to n gbe nibẹ.

Titi di ọdun 2025 ni Amẹrika fi tẹsiwaju lati maa ṣeranwọ fun South Africa titi di asiko ti ikede yii jade.

Ijọba South Africa ti fesi pe bo tilẹ jẹ Amẹrika ko tii bun oun gbọ nipa igbesẹ yii, oun naa ti n ṣiṣẹ lati wa ọna mii ti ko ni fi maa gbẹkẹle iranlọwọ Amẹrika mọ.

Lati igba ti wọn ti burawọle fun Aarẹ Donald Trump ni alangba ti wọ inu ogiri ibaṣepọ South Africa pẹlu Amẹrika.

Ko pẹ ti wọn burawọle fun Trump to kede pe South Africa n gbogun ti awọn Afrikaner ti wọn ni ọpọ ilẹ oko nibẹ lọna ati gba awọn oko wọn.

Ṣaaju asiko yii ni Amẹrika ti maa n fi owo ti iye rẹ to $400m ṣọwọ si South Africa lọdọdun labẹ asia eto President's Emergency Fund for Aids Relief (Pepfar).

Amẹrika ni lẹyin agbeyẹwo awọn iwa ibi ti South Africa n wu si awọn alawọ funfun naa, asiko ti to fun oun lati wọgile iranlọwọ ti oun n ṣe fun un.

Ọpọ lo ti fẹsun kan South Africa pe wọn fẹ pa ẹya awọn alawọ funfun run nibẹ.

Amọ ṣa, ijọba ilẹ naa ti sọ pe ọrọ ko ri bi awọn eeyan ṣe n gbe kiri.

Oṣiṣẹ US State Department kan sọ pe diẹdiẹ ti imu ẹlẹdẹ n wọ ọgba lawọn yoo maa fopin si iranlọwọ naa.

Wayi o, yatọ si ẹsun pe wọn n gbogun awọn alawọ funfun, South Africa tun ti ṣe awọn ọmọ ilẹ adulawọ mii bii Naijiria, Zimbabwe ati Ghana lẹyin ti wọn bẹrẹ si n le wọn kuro lorilẹede ọhun.