Mọ̀ nípa ìbejì Oguntoye tí wọ́n fẹ́ ìbejì ọmọ ìyá kan náà

Awọn ibeji Oguntoye pẹlu awọn iyawo wọn wọ aṣọ igbeyawo funfun ati kootu, wọn n rẹrin-in
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni opin ọsẹ to kọja ni awọn ibeji meji ṣe ohun ara ọtọ, ibeji meji gbe ara wọn niyawo.

Taiwo ati Taiwo fẹ ara wọn nigba ti Kehinde ati Kehinde naa gbe di tọkọtaya.

Awọn Taiwo ati Kehinde Oguntoye ti wọn jẹ ẹni to maa n ṣe agbatẹru ayẹyẹ ọdun ibeji to maa n waye ni ọdọọdun ni ilu Igbo Ora ṣe igbeyawo pelu awọn ibeji mii to jẹ obinrin meji.

Ọpọlọpọ awọn ibeji kaakiri agbaye lo darapọ mọ wọn lati bawọn kopa nibi ayeyẹ naa.

Awọn ibeji Oguntoye ti wọn jẹ ọmọ bibi Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, ti ọjọ ori wọn ti le logoji ọdun lo ti maa n sọ pe ibeji ni awọn maa fẹ nigba ti awọn ba maa di ẹni to n ni aya nile.

Gẹgẹ bi aṣa nile Yoruba, ọmọ to ba kọkọ waye ninu awọn ibeji ni wọn maa n pe ni Taiwo tabi Taye nigba ti Kehinde si jẹ ẹnikeji ti wọn bi.

Ta ni awọn Taiwo ati Kehinde Oguntoye?

Taiwo ati Kehinde Oguntoye ni oludasilẹ ileeṣẹ Twins World Creations International Limited, ileeṣẹ ti wọn da silẹ nibii ọdun mẹwaa sẹyin lati mu igbega ba ipa awọn ibeji kaakiri agbaye.

Ileeṣẹ yii lo bi ayẹye ọdun ibeji ti wọn maa n ṣe ni ilu Igbo Ora, ilu ti igbagbọ wa pe ibe ni ibeji pọ si julọ kaakiri agbaye.

Ni ilẹ ẹkọ giga fasiti Ibada, University of Ibadan ni Taiwo ati Kehinde ti kẹkọọ gboye ninu imọ amojuto ẹranko, ayika ati inaju.

Bakan naa ni wọn kẹkọọ gboye Diploma ninu imọ irinna ati inaju "Travel & Tourism" ni ile ẹkọ Institute of Business Technology Management of Nigeria.

Ni ọdun 2014 ni The African Sun Times ni Amẹrika fun awọn Taiwo ati Kehinde Oguntoye ni ami ẹyẹ awọn ibeji to gbajumọ julọ lẹka eto inaju Africa.

Awọn naa ni ibeji to kọkọ maa ṣoju ẹkun Africa nibi ayẹyẹ ọdun ibeji, Mojiang International Twins festival, China lọdun 2016.

Ọpọlọpọ awọn ami ẹyẹ mii bẹẹ naa ni wọn ti gba ni orilẹ ede Amẹrika ati ilẹ Africa.