You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ gbas-gbos, ìjọba Oyo tẹ́wọ́gba bàlúù méjì fún ètò àbò
Baalu ti wọn n lo fun eto aabo lati oju ofurufu ti balẹ siluu Ibadan, nipinlẹ Oyo.
Ọkọ ofurufu meji naa wa lara ileri ti gomina ipinlẹ ọhun, Seyi Makinde ṣe faraalu lori eto aabo.
Ṣaaju ni ariyanjiyan ti kọkọ n waye lori ọrọ baalu naa lẹyin ti Makinde ni ọpọlọpọ owo dọla ni ijọba ra baalu ọhun amọ ti araalu ko ri.
Ọrọ ibi ti baalu naa wa tunbọ fẹ loju si lẹyin iṣẹlẹ ijingbe to waye ni Yawota ati Ahoro Esinele.
Awọn araalu kan sọ lasiko naa pe to ba jẹ pe ijọba ti gbe baalu naa wa ni, yoo rọrun lati tete ṣawari awọn akẹkọọ ati olukọ ti agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire.
Bẹẹ lawọn mii n sọ pe irọ ni Makinde n pa ati pe o ti ko owo baalu ọhun sapo ara rẹ.
Ṣugbọn laarin gbas-gbos naa ni gomina Makinde ṣeleri pe awọn baalu ọhun yoo balẹ si ipinlẹ Oyo ko to di opin oṣu Keje ọdun 2026 yii.
Seyi Makinde ti mu ileri rẹ ṣẹ
Wayi o, ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin ni ipinlẹ naa, Dotun Oyelade fi lede, o fidi rẹ mulẹ pe awọn baalu ọhun to de siluu Ibadan.
Oyelade ni pẹlu bi baalu naa ṣe balẹ siluu Ibadan, o n fi han pe Seyi Makinde ti mu ọrọ rẹ ṣẹ lori ọrọ awọn baalu naa.
O ni ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni ijọba Oyo ra baalu naa lọna ati mu ki eto abo ipinlẹ Oyo ṣe dede.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọgba ileeṣẹ ọmọ ogun Nigerian Air Force to wa niluu Eko lawọn baalu naa wa nibi ti wọn ti n to wọn pọ ko to gbera lọ siluu Ibadan.
Ọmọ Ọba Oyelade pari ọrọ rẹ pe baalu ọhun yoo wulo lati ṣe iranlọwọ eto aabo fun awọn ikọ eleto aabo, to fi mọ ikọ Amotekun atawọn ileeṣẹ eto aabo mii nipinlẹ Oyo.