You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo wà nínú ilé nígbà táwọn DSS ń yìnbọn lákọ lákọ láti pa mí, àmọ́ wọn ò rí mi - Sunday Igboho
Ajijagbara ati ajafẹtọọ ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ti wọn ko fi ri oun mu lasiko tawọn DSS ya wọ ile rẹ niluu Ibadan lọjọ kinni oṣu Keje ọdun 2021.
Igboho sọrọ yii lasiko to n gbalejo ẹgbẹ awọn onimọ nipa ẹsin Islam nile rẹ to wa lagbegbe Soka n'Ibadan.
Owo Baba Dami ni awọn ẹṣọ DSS wa gbogbo inu oun, ṣugbọn wọn ko ri oun; bo tilẹ jẹ pe oun wa ninu ile.
O ni wọn ro pe oun loun di ologbo ti wọn ri, bakan naa ni Igboho sọ pe nigba to ya ni wọn mu ayederu Babalawo kan wọle pe ko wa ṣe etutu ki wọn le ri mi.
Igboho fi idi rẹ mulẹ pe ninu ile loun wa lati igba tawọn ẹṣọ DSS de ile oun titi ti wọn fi lọ.
''Mo gbọ iro wọn nigba ti wọn de ni nnkan bii ago kan aabọ loru, mo si beere wi pe awọn wo lo wọle.
Bayii ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn sinu yara, lẹyin ti wọn gbọ ohun mi.
Bi wọn ṣe fo fẹnsi wọle ni wọn ju ado oloro dynamite si irin to wa lori ferese ati ilẹkun ti gbogbo rẹ si ṣi silẹ.
Bayii ni ṣe wọle, ihoho ni mo wa ṣugbọn nigba ti mo gbọ ohun wọn ni mo wọ ṣokoto ati ẹwu.
Ọkan kan n sọ fun mi pe ki n jọwọ ara mi fun wọ, ọkan tun ni ki n ma ṣe bẹẹ tori wọn maa pa mi.
Nigba to ya ni mo pariwo pe ki lo de ti wọn fi wa sile mi, wọn tun tẹsiwaju lati maa yinbọn lai ri mi soju.
Bi wọn ṣe wọle ti wọn n pariwo ni wọn gbebọn si ori Dudu, amugbalẹgbẹ mi.
Lasiko naa ni mo pe wọn ja ilẹkun wọle ni, ọpọ eeyan lo tiẹ n purọ wi pe mo salọ ni nigba ti ibọn ba mi,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
''Awọn alfa ṣe adura nile mi ṣaaju ikọlu ajọ DSS lati dena iran buburu kan ti wọn ri nipa mi''
Owo Baba Dami tun fi idi rẹ mulẹ pe oun ko di ologbo gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ kiri.
O ni awọn ẹṣọ DSS pa ologbo ti wọn ri naa, lẹyin ti wọn ro pe oun ni.
Ọgbẹni Adeyemo ni gbogbo nnkan ti wọn n ṣe ninu ile oun loun n wo pata, bo tilẹ jẹ pe wọn o ri oun.
Igboho Ooṣa ni buọda oun kan ti ko riran daadaa to jade sita fara gbọta awọn ẹṣọ DSS naa tori wọn ro pe o fẹ ṣe atako fawọn.
O ni gbogbo oku awọn ti wọn pa nile oun ni wọn gbe lọ ko ba si ẹri lati le sọ pe wọn pa eeyan nile oun.
Ọlọrun lo da ẹmi mi si lẹyin tawọn adura tawọn alfa kan ṣe adura nile oun ṣaaju lati dena iran buburu kan ti wọn ri nipa mi ki o ma baa ṣẹ lori mi.
Awọn ẹṣọ DSS yabo ile Igboho lẹyin faakaja to waye laarin rẹ nigba to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ati Aarẹ Muhammadu Buhari nigba naa.
Ijọba apapọ sọ nigba naa wi pe awọn nnkan ti Igboho n ṣe le ṣakoba fun eto aabo orilẹede Naijiria.
Idi niyii tawọn ẹṣọ DSS ṣe fẹ fọwọ ofin mu un.
Ajọ DSS kede lẹyin ti wọn ya bo ile Igboho tan wi pe awọn ri oriṣiiriiṣi nnkan ija oloro nile rẹ.
Wọn si tun fọwọ ofin mu ọmọlẹyin rẹ mẹtala, DSS tun fidi rẹ mulẹ pe meji ninu awọn ọmọ ẹyin Igboho padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn doju ibọn kọ awọn ẹṣọ DSS.
Lẹyin o rẹyin, Igboho fi orilẹede Naijiria silẹ, amọ, awọn agbofinro mu un ni Cotonou lorilẹede Benin lọna irinajo rẹ si orilẹede Germany.
Nigba to ya ni ile ẹjọ ati awọn alaṣẹ Benin Republic tu u silẹ ti o si gbominira.
Lasiko ti Aarẹ Bola Tinubu gori aleefa ni ijọba fagile ikede ijọba Buhari pe Igboho wa lara awọn eeyan ti ijọba n wa gẹgẹ bi ọdaran.