You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Saudi Arabia yẹgi fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Africa márùn-ún lórí ẹ̀sùn gbígbé egbòogi olóró
Ileeṣẹ to n ri sọrọ abẹle lorileede Saudi Arabia ti sọ lọjọ Aje, ọsẹ yii, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 wi pe awọn ti yẹgi fun awọn ọmọ orileede Ethiopia marun-un lori ẹsun gbigbe egboogi oloro.
Ẹkun Asir la gbọ pe wọn ti ṣeku pa awọn marun-un naa, lẹyin idajọ to waye.
Gbigbe egboogi oloro jẹ ọkan lara awọn eewọ to ṣe pataki lorileede Saudi Arabia, to si jẹ idajọ iku ni fun ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ.
Idajọ iku yii lo ti jẹ ọmọ orileede Ethiopia mẹtadinlogun ti ijọba Saudi Arabi ti yẹgi fun, lẹyin awọn marun-un ti wọn pa lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa; ọjọ mẹrin lọjọ kẹjọ ati ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa; to fi mọ awọn mẹta lọjọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ eto abẹle fi sita naa, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe, "Awọn ileeṣẹ eleto aabo rọwọ to awọn oniṣẹ buruku yii, ti wọn si foju wọn ba ile-ẹjọ lori iwa ọdaran naa."
O fi kun un pe idajọ ọhun waye lẹyin ti wọn pe ẹjọ kotẹmilọrun, eyi ti ile-ẹjọ agba fontẹ lu ni ibamu pẹlu ofin Ṣẹria (Sharia).
Ileeṣẹ naa jẹ ko di mimọ pe awọn mọ-ọn-mọ gbe idajọ naa kalẹ ni, "lati le daabo bo awọn araalu ati olugbe orileede lọwọ egboogi oloro, ati lati gbe ijiya to tọ kalẹ lori awọn to n ṣe fayawọ wọle ati awọn to n gbe e larugẹ."
Ajọ ajafẹtọọ ọmọniyan HRW sọrọ
Ajọ ajafẹtọọ ọmọniyan, HRW ninu atẹjade rẹ ti sọ pe ko din ni ọmọ orileede Ethiopia marundinlaadọrin ti wọn n gbe ni Saudi Arabia ni wọn n koju idajọ iku nla lori ẹsun to nii ṣe pẹlu egboogi oloro, bo tilẹ jẹ pe mẹrinla ninu wọn ni wọn ti pa.
Awọn ileeṣẹ iroyin naa ti kọ o sita pe awọn ọmọ Ethiopia to le ni igba ni wọn ti n duro lati gba idajọ iku ni ọgba ẹwọn Khamis Mushatt, bo tilẹ jẹ pe ajọ HRW ko tii fidi rẹ mulẹ.
Gẹgẹ bi awọn alakoso ilẹ Saudi ṣe sọ, wọn ni awọn ajoji to n wa si orileede wọn ni wọn n gba idajọ iku lori egboogi oloro 'hashish'.
"Bi ijọba Saudi Arabia ṣe n murasilẹ lati pa awọn ajoji nipa idajọ iku fun awọn ẹsun ti ko ni iwa ipa, lẹyin awọn igbẹjọ ti ko fun wọn ni awọn ẹtọ idajọ ododo to ṣe pataki, fi aikansi to jinlẹ han si ẹtọ ati ẹmi wọn," Nadia Hardman, to jẹ oluṣẹwadii afgba ni ajọ HRW sọ eyi i mimọ, to si n rọ awọn alabaṣiṣẹpọ agbaye lati da si i.
Ẹgbẹ awọn ajafẹtọọ agbaye ati nilẹ Ethiopia, awọn olori ẹleṣin, awọn ajọ to n ri sọrọ araalu, ati awọn ijọba ti rọ ijọba Ethiopia lati foju aanu wo awọn ajoji naa, lati le jẹ ki wọn pada sile wọn.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere lorileede Ethiopia ti wa jẹ ko di mimọ ninu atẹjade ti wọn fi sita pe, awọn ti n ni ajọsọ pẹlu iṣakoso ilẹ Saudi lori awọn ọmọ wọn to n gbe ni Saudi Arabia, iyẹn awọn to n dojukọ idajọ iku.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2026, ileeṣẹ naa sọ pe ijọba Ethiopia ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn alakoso tọrọ naa kan ninu ijọba Saudi Arabia lori ọrọ to nii ṣe pẹlu awọn ọmọ orileede Ethiopia to n gbe ni Saudi Arabia, to fi mọ awọn to n koju ofin ati idajọ iku.