Fọ́nrán bí Abacha ṣe kú wà lọ́wọ́ mi, arúmọjẹ lásán ni ìtàn táwọn kan ń kọ sínú ìwé kiri - Al-Mustapha, olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún Abacha

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọrọ ohun to ṣokunfa iku olori orilẹ ede tẹlẹ ri ni Naijiria, Ọgagun Sani Abacha ṣi n fa awuyeyuwe lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti ọgagun naa ti jade laye.

Laipẹ yii ni igbakeji ọga agba tẹlẹ ri nileeṣẹ ẹṣọ aabo ọtẹlẹmuyẹ nilẹ Naijiria, Dennis Amachree gbe iwaju kan jade to si sọ ohun to mọ nipa iku Abacha.

Amọ olori ẹṣọ aabo tẹlẹ ri fun Abacha, Hamza Al-Mustapha ti ni irọ to jina si ootọ ni awọn ohun ti oṣiṣẹ tẹlẹ ri nileeṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ, Department of State Services, DSS, Dennis Amachree, gbe jade lori ohun to ṣekupa Abacha.

Aarin oṣu Kọkanla, ọdun 1993 si oṣu Kẹfa, ọdun 1998 ni Abacha ṣakoso ijọba Naijiria lasiko ologun.

Latigba ti iku Ọgagun Abacha ti jade sita, ni ariyanjiyan ti wa kaakiri agbaye, paapaa nilẹ Naijiria to ti jẹ adari, ti awọn eeyan ko si gbagbe titi di asiko yii.

Oniruuru ọrọ ni awọn eeyan ti sọ, ti wọn tun ṣi n sọ nipa iṣakoso oloogbe Abacha, to si jẹ pe bi awọn kan ṣe n fi ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ kan an, bẹẹ ni awọn miran n sọ pe ọwọ lile lo fi ṣakoso orileede naa.

Inu iwe tuntun ti Amachree ṣẹṣẹ gbe jade, eyi to fi sọri irin ajo rẹ ninu iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tii ṣe DSS, to pe akọle rẹ ni 'DSS @40: My journey behind the shield', lo ti sọ nipa ohun to ṣokunfa iku olori Naijiria naa.

Amachree, ni igbakeji alakoso agba ni ẹka amuṣẹṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nipinlẹ Eko nigba ti Abacha n ṣe ijọba lọwọ.

Àtakò dìde lórí àlàyé ikú tó pa ọ̀gágun Sani Abacha tó gba orí ayélujára, àlàyé rèé

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ipinlẹ Naijiria, Al-Mustapha sọ pe awọn nnkan ti Amachree kọ sinu iwe rẹ to gbe jade lori iku Abacha kii ṣe ootọ rara, to si ni awọn kan lo ni ko kọ gbogbo ohun to kọ naa.

Al-Mustapha ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ lasiko naa ni o wa ni ikawọ oun nitori gbogbo awọn fọnran ti ẹrọ ayaworan to wa ninu ile naa ka silẹ wa lọwọ oun.

O tẹmpẹlẹmọ pe ohun ti Amachree kọ sinu iwe naa kii ṣe ohun to ṣẹlẹ rara nitori awọn ẹri to wa lọwọ oun yatọ si gbogbo nnkan ti o kọ sinu iwe rẹ.

"Awọn kan lo ni ki ọmọkunrin naa kọ gbogbo irọ to kọ. Mo ni fidio CCTV gbogbo ohun to ṣẹlẹ lọwọ, nitori naa gbogbo ohun to kọ naa kii ṣe ootọ."

O wa rọ awọn eeyan lati ma gba gbogbo ohun to kọ sinu iwe naa gbọ, to si tun woye pe ohun ti ko dara ni lati maa kọ ohun tik ii ṣe ootọ lori ẹni ti ko laye mọ, ti ko ni le sọ ti ẹnu rẹ.

Irọ́ tó jìnnà sí òtítọ́ – Shehu Sani

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Shehu Sani naa ti sọ pe ko si otitọ kankan to wa ninu itan bi olori ologun ilẹ Naijiria nigba kan ri, Sanni Abacha ṣe jade laye.

Sani sọ pe gbogbo awọn ọrọ to wa ninu bi Abacha ṣe ku naa ni ki awọn eeyan ma gbagbọ, nitori pe ko si otitọ kankan nibẹ.

Ninu ọrọ ti Sani gbe soju opo 'X' rẹ, o ni:

"Gbogbo ọrọ ti wọn gbe jade lori iku Abacha lo wa lati ṣi awọn eeyan lọkan.

Ẹni to kọ itan naa ko fi awọn ẹri to fidi mulẹ sie, bi ko ṣe ọrọ ẹnu lasan. O yẹ ki wọn ko o danu ni."

Kí ni Amachree kọ sínú ìwé tó ń fa awuyewuye?

O sọ pe iwjau ọmọbinrin kan ni olori orileede naa ti dakẹ ni nnkan bi agogo mẹrin kọja iṣẹju marun-un owurọ, lasiko ti wọn n ni ibaṣepọ lọwọ ninu ile aarẹ to wa niluu Abuja.

Igbakeji alakoso tẹlẹ naa sọ pe loju ẹsẹ ni ọmọbinrin ọhun ti na papa bora, to si lọ wọ ọkọ baalu lọ siluu Eko, ki aṣiri ma ba a tu.

Amachree ṣalaye pe ọmọbinrin naa ati ẹgbọn rẹ obinrin toun jẹ ọrẹbinrin Abacha ni wọn jọ wọ aso Rock to jẹ ibujoko agbara lọjọ ti iṣẹ naa ṣẹlẹ

O ni lẹyin ti wọn sọrọ tan, ni ọrẹbinrin Abacha jade, toun si ba tiẹ lọ, ṣugbọn to fi aburo rẹ ati Abacha silẹ lọ.

"Ni deedee agogo mẹta ku ogun iṣẹju oru, ko pẹ ti Ọgagun Useni lọ, ọrẹbinrin Abacha to jẹ ọmọ Igbo de si ie igbalejo Aso Rock lati otẹẹli Nicon Nogs Hilton," ọrọ yii o jade lati inu iwe naa.

"Pẹlu rẹ ni aburo rẹ, ẹni to jẹ onimọ nipa oogun toun naa wa fun ipagọ niluu Abuja. Olori orileede ṣẹṣẹ ra ọkọ ayọkẹlẹ SUV fun ọrẹbinrin rẹ ni, ti wọn si pinnu lati ya ki 'Ọga'."

Báwo ni olórí ilẹ̀ Nàíjíríà ṣe dákẹ́?

Iwe naa ṣalaye siwaju pe "Wọn mu Abacha ati aburo naa lọ, ko si pẹ, ọrẹbinrin naa pada si otẹẹli, o fi akọṣẹṣẹmọṣẹ onimọ nipa oogun naa silẹ pẹlu olori orileede.

"Ni nnkan bi agogo mẹrin kọja iṣẹju marun-un owurọ, wọn ni ajọṣepọ lọwọ, asiko naa ni onimọ nipa oogun yii ṣakiyesi pe Abacha ko mira mọ. O pe e, ṣugbọn ko gbọ nnkankan, o si ti gan pa. O yẹ ẹ wo boya o ṣi n min, ṣugbọn rara.

"Pẹlu ibẹrubojo, o sare mura, o si fi ile igbalejo naa silẹ, o sọ fun ologun to wa lẹnu iṣẹ wi pe 'Ọga' ni ki wọn fi ọkọ gbe oun pada lọ si otẹẹli oun.

"Ologun naa ti ko mọ pe nnkan ti ṣẹlẹ, sare palẹmọ fun ọkọ ti yoo gbe e. Ọmọbinrin naa pada si otẹẹli Hilton, o si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun ẹgbọn rẹ.

"Lẹyin eyi ni wọn sare gbe e lọ si papakọ ofurufu Abuja lati lọ wọ ọkọ baalu Okada to n gbera lọ si Eko ni agogo meje.

"Asiko yii ni Major Al-Mustapha padanu. Nigba ti wọn fi to o leti nipa wi pe Abacha ko min mọ ni agogo marun-un, o beere ẹni to wa pẹlu Ọgagun. Wọn sọ fun un pe aburo ọrẹbinrin rẹ ni, ẹni ti wọn ṣẹṣẹ lọ ja silẹ ni otẹẹli Hilton.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, SSS sare lọ sibẹ lati fọwọ ofin gbe ọrẹbinrin naa, ṣugbọn o jẹ iyalẹnu pe onimọ nipa oogun ti wọn nilo ni pajawiri ko si nibẹ, o si ti wa loju ọna Eko."

'Orí mi ló dákẹ́ sí' - Onímọ̀ nípa òògùn jẹ́wọ́

Amachree jẹ ko di mimọ pe oun lẹni to fi ọrọ wa onimọ nipa oogun naa lẹnu wo ni ileeṣẹ wọn to wa ni Ogudu nipinlẹ Eko, lẹyin ti aṣẹ wa lati ọdọ alakoso eto amuṣẹṣe ni olu ileeṣẹ DSS.

Lasiko ifọrọwerọ ati iwadii naa, igbakeji alakoso agba naa sọ pe ọrọ akọkọ ti onimọ nipa oogun naa sọ ni pe 'Emi kọ ni mo pa a, o dakẹ si ori mi ni."

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọrọ ti ọmọbinrin naa sọ lo tako "iwadii igbimọ papọ ati awọn idaji otitọ" – to fi mọ awọn eyi ti wọn n sọ nipa "ọmọbinrin India ati Apple ti wọn fi majele si" – eyi to ti waye lori iku Abacha.

"Ikọ mi lo ṣawari rẹ, ti wọn si mu wa si ọfiisi mi. Emi funra mi ni mo fi ọrọ wa a lẹnu wo," Amachree sọ bẹẹ.

"Ohun to kọkọ sọ fun mi ni pe: 'Emi kọ ni mo pa a, o dakẹ si mi lori ni.' Lẹyin to sọ gbogbo ọrọ rẹ tan, Mo pe alakoso agba niluu Abuja, a si gbe e pada lọ.

"Obinrin onimọ nipa oogun naa, ẹni ti Abacha ni idaduro ọkan niwaju rẹ, nikan lo mọ okodoro ohun to ṣẹlẹ, to si fi opin si gbogbo ohun ti wọn n sọ lori ohun to ṣokunfa iku Abacha ti wọn n gbe kaakiri,"

Ko ju bi oṣu kan ti Abacha jade laye ni MKO Abiola, ẹni to jawe olubori ninu eto idibo aarẹ to waye lọjọ kejia, oṣu Kẹfa, ọdun 1993 naa jade laye.

Abiola ni wọn fi si atimọle lẹyin ẹsun ti wọn fi kan an nipa wi pe o tapa si ofin, lẹyin ti wọn da gbogbo eto idibo aarẹ nu.