You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìdájọ́ tó pàṣẹ kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ Atiku kúrò nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀
Ile ẹjọ kọtẹmilọrun ilu Abuja ti wọgile idajọ to paṣẹ fun ajọ INEC lati fa orukọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ati ẹgbẹ oṣelu mẹrin mii yọ ninu akọsilẹ rẹ lori pe awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ko ni awọn amuyẹ to to.
Ninu idajọ igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta ti wọn gbe idajọ naa kalẹ, wọn ni idajọ ti ile ẹjó giga gbe kalẹ ṣaaju ko lẹsẹ nilẹ.
Gẹgẹ bii ile ẹjọ ọhun ṣe sọ, ko si igbẹjọ kankan niwaju ile ẹjọ giga naa to fi yẹ ko paṣẹ fun INEC pe ko yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ninu akọsilẹ rẹ.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa tun ṣalaye pe ile ẹjọ naa kuna lati yẹ gbogbo awọn ẹri to wa niwaju rẹ wo nitori o kuna lati naani awọn ẹri to fi han pe awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ti jawe olubori ninu awọn eto idibo kan.
O sọ siwaju pe ile ẹjọ giga naa tun kọ eti ọgbọin si aṣẹ to ti waye ṣaaju wi pe ko ma da si ọrọ ọhun rara.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ni niṣe lo yẹ ki ile ẹjọ giga naa da ẹjọ ọhun nu larari pe ko lẹsẹ nilẹ ati pe ko lagbara lati gbọ ẹjọ naa.
Idajọ tuntun yii lo n waye lẹyin ti awọn ẹgbẹ oṣelu ti ọrọ kan gbe ọrọ naa wa siwaju rẹ.
Lẹyin naa lo sọ pe ki ajọ to pe ẹjọ naa ṣaaju, National Forum of Former Legislators (NFFL), san owo fun awọn ẹgbẹ oṣelu naa.
Yatọ si ADC, awọn ẹgbẹ oṣelu mii ti ọrọ naa kan ni Action Peoples Party (APP), Action Alliance (AA), Accord Party (AP), ati Zenith Labour Party (ZLP).