Makinde dárúkọ èèyàn márùn ún táwọn ajínigbé pa lásìkò tí wọ́n fẹ́ dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Oríire, kéde ìgbésẹ̀ tó kàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti sọ pe loootọ lawọn eeyan ipinlẹ naa le gbe igba ọpẹ bayii lẹyin tawọn olukọ atawọn akẹkọọ tawọn ẹṣọ eleto aabo doola lọwọ ajinigbe ti darapọ mọ ẹbi wọn tan, amọ, gomina ni ibanujẹ wa ninu idunnu to ṣubu layọ naa.

Makinde sọrọ yii nigba ti ileeṣẹ ologun ko awọn eeyan naa wa fun ijọba ipinlẹ Oyo lati fi wọn le ẹbi wọn lọwọ lẹyin ti wọn ti gba itọju tan nile iwosan ologun niluu Ibadan.

Gomina ni bo tilẹ jẹ pe inu onikaluku dun nipinlẹ Oyo lori awọn akẹkọọ atawọn olukọ Ahoro Esinele ati Yawota ti wọn gba ominira lọwọ ajinigbe, Maknide ni iroyin ayọ naa tun ni ibanujẹ ninu tori pe awọn eeyan kan padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n gbiyanju lati doola awọn ti wọn ti wọn ji gbe.

Makinde sọ pe lara awọn eeyan to ku ni olukọ meji wa, Ọgbẹni Joel Adesiyan, ti wọn pa lọjọ ti ijinigbe naa ṣẹlẹ ati Diakoni John Olaleye to ku si akata awọn ajinigbe.

''Ọpọ ọmọ Naijiria lo ri fọnran to ṣafihan bi wọn ṣe pa Ọgbẹni Michael Oyedokun, olukọ to jara mọṣẹ tawọn janduku ajinigbe yii pa ni ifana-fọnṣu.

A o le gbagbe awọn ẹṣọ eleto aabo, awọn ọlọdẹ atawọn ẹṣọ Amotekun nipinlẹ Oyo to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ọmogun F.A. Isaac, Ọgbẹni Adigun Shuaibu, Ọgbẹni Isa Saliu, Ọgbẹnu Rafiu Ayuba, ati ọmogun kan ti n ko mọ orukọ rẹ.

Mo tun gboṣuba fun Ọgbẹni Bamidele Paul to farapa yanayana to n gba itọju lọwọ yii,'' Makinde lo sọ bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Oyo wa rọ araalu wi pe ki wọn si wa lojufo bi wọn ti n dunnu wi pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ Oriire ti gba ominira tori awọn agbesunmọmi ki i ṣe ẹran rirọ.

Makinde ni bi awọn agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ lawọn ẹkun mii kaakiri orilẹede Naijiria fi han pe wọn kii tete kuro nibi ti wọn ba ti n ṣọṣẹ.

Mo n fi asiko yii kepe lẹgbẹ lẹgbẹ ati lajọ lajọ lati ṣe iwadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijinigbe Oriire - Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo tun sọ pe o ṣe pataki lati ri wi pe eto aabo to peye wa lawọn ilu to wa lagbegbe igbo ọba Old Oyo National Park.

Gomina ipinlẹ Oyo fikun ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ lo n ṣakoso igbo ọba, ṣugbọn o ni ijọba oun yoo sa ipa rẹ lati daabo bawọn eeyan ipinlẹ Oyo.

''A o bẹrẹ sii tọpinpin bi ẹnikẹni ṣe rin bayii lagbegbe igbo Old Oyo National Park.

A o si tun maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn olugbe awọn ilu to wa lagbegbe igbo ọba naa.

Bi awọn akẹkọọ atawọn olukọ Oriire ṣe darapọ mọ ẹbi wọn bayii ko tumọ si pe iṣẹ ti pari, koda, iṣẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo, mo n fi asiko yii kepe lẹgbẹ lẹgbẹ ati lajọ lajọ to maa n ja fun ẹtọ ọmọniyan to fi mọ ajọ iṣọkan agbaye UNO lati ṣe iwadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijinigbe yii gan an.

Eyi kii ṣe lati bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹ tawọn ẹṣọ eleto aabo n ṣe, amọ, iwadii yii ṣe pataki lati le mọ awọn to wa nidii iṣẹlẹ laabi yii ni.

Ojuṣe ijọba apapọ ni lati pese eto aabo to peye fun araalu, idi niyii ti a fi gbọdọ mọ awọn to ṣiṣẹ laabi yii ki iru rẹ ma baa le ṣẹlẹ mọ.

Eyi kii ṣe ọrọ oṣelu, amọ, o ni ṣe pẹlu idajọ ododo fawọn ti wọn ji gbe atawọn ti wọn ṣekupa.

Mo wa n fi gbogbo obi ni ipinlẹ Oyo loju wi pe ijọba ko ni beṣu bẹgba lati pese eto aabo to peye ni gbogbo awọn ile ẹkọ wa.

Ijọba mi si maa ri pe gbogbo awọn to wa nidii ọrọ yii lo foju wina ofin,'' Makinde ṣalaye.