You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alága àdúgbò dá baálé ilé dọ́bálẹ̀, fi pankẹ́rẹ́ dá sẹ̀ríà ìyà fún un torí pé ó sọ̀rọ̀ lórí àṣepatì àkànṣeiṣẹ́ àjọ NDDC, ọlọ́pàá ní iléẹjọ́ yá
Eeyan mẹta, ninu eyi ti Alaga agbegbe Emevor, nipinlẹ Delta, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Lucky Okeremu, wa lara wọn, ti n jẹjọ bayii lori ẹsun lilu araalu kan to koro oju si akanṣe iṣẹ ọna ti ajọ Niger Delta Development Commission (NDDC) ṣe pati niluu naa.
Yatọ si alaga ti ọlọpaa mu lori ẹsun yii, awọn meji mi-in ti wọn tun jọ foju ba kootu ni Okiemute Oyibo ati Karo Akamakusi .
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta fi sita lo fidi ẹ mulẹ, pe awọn eeyan naa huwa to lodi sofin, igbejọ si ti bẹrẹ lori ọrọ wọn.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Fidio kan lo bẹrẹ si i kari ayelujara, nibi ti awọn kan ti jokoo yika, ti awọn kan si duro, ti wọn da ọkunrin kan to wọ awọtẹnu ati ṣokoto lasan dubulẹ, ti wọn si n fi igi lu u kikankikan.
Ọkunrin ti wọn n lu naa n sunkun ninu fidio ọhun, bẹẹ lo n bẹbẹ, amọ awọn ti wọn n lu u ko ṣiwọ lilu naa.
Lilu naa pọ to bẹẹ ti wọn pada da apa si I lara, ti wọn si ṣe e leṣe.
Ohun ti a gbọ pe wọn n tori rẹ lu u ni pe ọna kan wa ti ajọ Niger Delta Development Commission (NDDC) n ṣe lọ ni agbegbe naa, amọ ti wọn ti dawọ iṣẹ duro lorii rẹ lai ṣe nnkan kan si i mọ.
Aṣepati iṣẹ oju ọna naa n fa idiwọ fun araalu nipa irinna, kaluku wọn ni ko si tẹ lọrun bi iroyin ṣe sọ.
Eyi ni ọkunrin to pada koju ifiyajẹni yii naa sọrọ nipa rẹ, to koro oju si idaamu ti aṣepati iṣẹ naa n mu ba araalu, to si di ọran si i lọrun.
Iroyin sọ pe Alaga agbegbe Emevor, Lucky Okeremu,nijọba ibilẹ Isoko, ni Delta, paṣẹ pe ki wọn lọ gbe ọkunrin naa wa, wọn si gbe e lọ si ile itura kan ti wọn ti da sẹria fun un lori ohun to sọ.
Ifiyajẹni naa pọ, to mu ki awọn ma-jẹ-o-bajẹ aarin ilu fi to ọlọpaa atawọn ajafẹtọọ ọmọniyan leti.
Bakan naa ni fidio iṣẹlẹ naa tun n tan ka ori ayelujara, to mu ki Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Delta, CP Yemi Oyeniyi, paṣẹ fun ọga ọlọpaa agbegbe Ozoro, lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa kia.
Ọlọpaa gbe Alaga atawọn meji mi-in, ọrọ de kootu
Ninu atẹjade ọlọpaa ipinlẹ Delta ni wọn ti ṣalaye, pe iwadii ati ifisun awọn ajafẹtọọ ọmọniyan fi han pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ karun-un,oṣu Keje ọdun 2026.
Nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni atẹjade naa sọ pe awọn afurasi yii huwa to lodi sofin naa, pẹlu ikunwọ awọn kan ti wọn ti sa lọ bayii.
Atẹjade naa sọ pe awọn afurasi yii mu ẹni ti wọn lu naa lọna ti ko ba ofin mu, wọn gbe e lọ sile itura kan, nibi ti wọn ti fi oju rẹ gbolẹ, ti wọn lu u lalubami, ti wọn tun dunkooko iku mọ ọn.
Ọlọpaa sọ pe iwa yii le da omi alaafia ilu ru, o si tun lodi si abala 516, 355, 249(e), ati 86 ofin iwa ọdaran ipinlẹ Delta, eyi ti wọn gbe kalẹ ni 2006.
Ẹsun igbimọpọ huwa aitọ, dida omi alaafia ilu ru, didunkooko mọ ẹmi eeyan, dida apa si ẹni ẹlẹni lara ni wọn n jẹjọ rẹ ni kootu bi ọlọpaa ṣe sọ, igbẹjọ ṣi n tẹsiwaju pẹlu bi wọn ṣe sọ.