You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Kò síná, kò sómi, àfi bí pé ìhòhò la wa ni, ọmọ ọdún méje kò fojú rínà ọba rí nílùú yìí'
Ilu Ifọn ni ipinlẹ Ondo ni BBC news Yoruba tẹkọleti lọ nibi ti awọn olugbe ilu naa ti n kerora ati gbajare sita pe ihoho lawọn wa nitori pe gẹgẹbi ọkan lara awọn olugbe naa ṣe sọ "ko sina ko si omi, ko si ọba, ko si ijoye, o dabi igba ti eeyan w ani ihoho.
Awọn olugbe ilu Ifọn ṣalaye pe asiko idibo ti awọn oloṣelu ba fẹwa polongo ibo nikan lawọn maa n mọ pe awọn jẹ ara ipinlẹ Ondo ati orilẹede Naijiria.
Wọn ni o ti to ọdun mẹfa si meje ti wọn ti ri ina mọnamọna kẹyin ni ilu naa,
Alagba Ọlaniyi Ẹniolo ṣalaye pe ile ifowopamọsi to wa niluu naa ti kogba wọle, ileẹjọ giga, majisireeti ati ileẹjọ ibilẹ to w ani ilu naa lo ti w ani titi pa ti wọn si ti kogba lọ si ilu Ọwọ.
Ẹ wo fidio yii lati mọ siwaju sii ohun ti oju awọn eeyan ilu Ifọn n ri bayii.