Ọkọ olùkọ́ tí àwọn agbésùnmọ̀mí ń lò nínú fídíò ìjínigbé Oriire sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ ìyàwó rẹ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọjọgbọn Wole Alamu, to jẹ ọkọ olukọ ti awọn agbesunmọmi maa n fi oju rẹ han ninu fidio wọn ati ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Oyo ti ba BBC sọrọ lẹyin itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ Oriire.

Alamu sọ pe inu oun dun pe iyawo oun atawọn akẹgbẹ rẹ, to fi mọ awọn akẹkọọ rẹ ti gba itusilẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o ni ijọba ko ti pe oun lati sọ fun oun pe iyawo oun ti wa lakata wọn titi di asiko ti a n ba oun sọrọ amọ inu oun dun.

Ọkurin naa ti oun funra rẹ jẹ ogbontarigi olukọ sọ pe awọn eeeyan ọhun ti wa lakata ijọba bayii ti ijọba si n ṣe itọju wọn lọwọ.

O ni "Ijọba ko tii sọ fun mi, amọ wọn wa lakata ijọba bayii, ijọba n tọju wọn lọwọ.

"Inu wa dun pe wọn ti gba itusilẹ, a si dupẹ lọwọ gbogbo awọn to lọwọ si bi wọn ṣe gba itusilẹ.

"Inu ibanujẹ nla ati ipaya ni mo wa ni gbogbo asiko ti wọn fi wa lakata awọn ajinigbe naa amọ inu mi dun pe o pada ja si ọpẹ."

A fẹ ki ijọba fi agbofinro ṣọwọ si gbogbo awọn ile ẹkọ Oyo – NUT

Ninu iroyin kan naa, ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Oyo ti sọ pe inu awọn dun fun itusilẹ awọn olukọ ati akẹkọọ naa.

Alaga NUT ipinlẹ Oyo, Hassan Ajibola Fatai, ti sọ pe ijọba gbọgọ ṣe amulo eto idaabo awọn akẹkọọ "Safe School Initiative" ti wọn ba a sọ ṣaaju.

Fatai sọ pe to ba ṣeeṣe ki ijọba fi awọn agbofinro ṣọwọ si gbogbo ile ẹkọ to wa nipinlẹ naa ki irufẹ iṣẹlẹ bayii ma ba a waye mọ inu awọn yoo dun.

O ni ijọba agbọdọ ṣe awọn odi yi awọn ile ẹkọ Oyo ka, ki awọn agbofinro maa ṣọ awọn ile ẹkọ ki ọkọ awọn agbofinro si maa yi awọn ile ẹkọ ipinlẹ naa ka loorekoore.

Wo ohun tí Ààrẹ Tinubu, Seyi Makinde àti ẹgbẹ́ àwọn gómìnà sọ lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Oriire

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, gomina ipinlẹ Oyo, Aarẹ ẹgbẹ awọn Musulumi ilẹ Yoruba atawọn araalu mii ti bẹrẹ si n ki awọn olukọ ati akekọọ Oriire ku oriire lẹyin itusilẹ wọn lakata ajinigbe.

Nnkan bii oṣu meji sẹyin ni wọn ji awọn akẹkọọ mọkandinlogoji ati olukọ mẹfa gbe lọ nile ẹkọ wọn to wa ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.

Lẹyin ti wọn ti lo ọjọ to le ni aadọta lakata ajinigbe ninu igbo, awọn ọmọ ogun ti pada doola wọn ti ẹnikẹni ninu wọn ko si farapa.

A gbọ pe mẹjọ ninu awọn ajinigbe naa ni ọwọ awọn ọmọ ogun tẹ nigba ti pupọ awọn akẹgbẹ wọn mii gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ Bola Tinubu sọ pe ijọba ko san owo itusilẹ fun awọn ajinigbe naa ko to doola wọn.

Tinubu gboriyin fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn agbofinro mii fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati doola awọn eeyan naa lakata awọn ajinigbe ọhun.

Aarẹ Tinubu fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ égbẹ agbesunmọmi Ansaru lo wa nidi ikọlu naa.

Nigba to n sọrọ, gomina Seyi Makinde ni inu oun dun ati pe gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni ayọ wọn kun fun idoola awọn eeyan naa.

Ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, NGF, ki Aarẹ Boa Tinubu, gomina Seyi Makinde atawọn mọlẹbi awọn ti ọrọ naa kan ku oriire itusilẹ awọn eeyan ọhun.

Awọn gomina tun gboriyin fun awọn ọmọ ogun fun iṣẹ takuntakun wọn lati doola awọn eeyan naa lai farapa.

Yatọ si awọn to ti sọrọ, ọpọ ọmọ Naijiria naa ni wọn ti n ki awọn eeyan naa ku oriire bi wọn ṣe bọ lataka awọn ajinigbe ọhun lẹyin ọpọ ọjọ.

Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Esinele gba ìtúsílẹ̀

Gbogbo awọn akẹkọọ ati olukọ tawọn agbebọn ji gbe ni ilu Esinele ati Yawota ti gba itusilẹ.

Agbẹnusọ aarẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ.

Onanuga ninu atẹjade naa sọ pe ọwọ awọn ẹṣọ aabo tẹ awọn afurasi agbebọn mẹjọ lasiko tawọn ẹṣọ aabo gba itusilẹ awọn akẹkọọ naa.

O fi kun pe awọn ko fun awọn agbebọn ni nnkan ti wọn n beere fun iyẹn itusilẹ ọga wọn kan to n koju igbẹjọ lọdọ ijọba apapọ fun awọn ẹṣẹ rẹ.

Onanuga ni awọn ẹṣọ aabo maa to fi iroyin lede lori bi wọn ṣe gba itusilẹ awọn eeyan naa

Ninu fidio kan ti Onanuga fi soju opo rẹ, ọlukọ agba ilẹ ẹkọ Esinele Rachael Alamu dupẹ lọwọ aarẹ fun akitiyan wọn lati gba itusilẹ wọn.

Alamu ni awọn dupẹ lọwọ aarẹ nitori awọn mọ riri bo ṣe mu aabo awọn ni ọkunkundun.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ aabo fun gbogbo iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, eyi to ni o ṣokunfa idi ti awọn ṣi fi wa laaye di asiko yii.

Ẹ o ranti pe Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti iye wọn jẹ mẹrindinlaaadọta lọ nibi ikọlu naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Lẹyin naa ni awọn agbebọn tun gbe fidio kan jade nibi ti wọn ti ṣafihan bi wọn ṣe bẹ ori olukọ mii lara awọn ti wọn jigbe.

Aarẹ Tinubu fi idunnu sawọn eeyan to gba itusilẹ kuro ni ahamọ ajinigbe

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti fi idunnu rẹ han lori bi awọn ẹṣọ aabo ṣe gba itusilẹ awọn akẹkọọ ati oluko tawọn agbebọn ji gbe ni Ogbomoso, ijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo.

Tinubu ninu atẹjade ti agbenusọ rẹ, Bayo Onanuga to kọkọ kede itusile awọn eeyan naa sọ pe gbogbo akitiyan awọn ẹṣọ aabo ileeṣẹ Ologun, ọlọpaa, DSS, ti wọn ti n ṣiṣẹ lati ọjọ mẹrindinlọgọta (56) tawọn eeyan naa ti w ani ahamọ ajinigbe ko ja si asan.

O ni inu oun dun pe wọn gba itusilẹ awọn eeyan naa lai padanu ohunkohun, ti wọn si tun ri mẹjọ mu ninu awọn ajinigbe naa.

Aarẹ ni o ṣeni laaanu pe awọn akẹkọọ ati olukọ naa, to fi mọ awọn ẹbi wọn koju irufẹ idaamu yii lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Bakan naa ni aarẹ tun gboriyin fun ijọba ipinlẹ Oyo fun bi atilẹyin ti wọn ṣe fun ijọba apapọ lori gbogbo erongba lati doola awọn eeyan naa.

Aarẹ tun ni parọwa si ijọba Oyo lati pese aabo to nipọn si gbogbo awọn ile ẹkọ to wa ni ipinlẹ naa lati dena irufẹ ikọlu bẹẹ lọjọ iwaju.

O fi kun pe ijọba oun maa sa gbogbo ipa lati fiya to tọ ati gbigba idajọ ododo lori fun awọn eeyan naa ati ẹbi olukọ Michael Oydeokun tawọn agbebọn pa si ahamọ wọn.

Aarẹ Tinubu tun dari awọn oṣiṣẹ ilera atawọn to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo lati pese itọju to peye fun awọn eeyan to ṣẹṣẹ gba itusilẹ naa.