Àwọn ajínigbé ṣekúpa sọ́jà, Amotekun, ọlọ́dẹ àti olùkọ́ méjì nínú igbó, Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ Esinele sọ ìdí tí wọ́n fi pa àwọn olùkọ́

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọga agba ile ẹkọ girama Esinele, Arabinrin F.R. Alamu ti sọ pe iriri to buru jai ni a ni ninu igbo pẹlu awọn ajinigbe.

Arabinrin Alamu ni ''awọn ajinigbe naa dẹru ba wa, wọn tun sọ wa pe ijọba ti gbagbe wa sinu igbo.

Wọn maa n lo foonu wọn lati ba oriṣiiriṣii awọn eeyan sọrọ.

Arabinrin Alamu sọ pe nnkankan tawọn gbagbọ ni pe awọn ọmọ Naijiria n gbadura fawọn.''

Ọga ile ẹkọ girama Esinele fikun ọrọ rẹ pe ọjọ keji ti wọn ko awọn de inu igbo lawọn ajinigbe naa ṣekupa ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe , oloogbe Michael Oyedokun.

Arabinrin Alamu ṣalaye pe wọn pa awọn olukọ meji lati le jẹ ki ijọba fun wọn ni nnkan ti wọn n beere fun un.

O ni nigba tawọn gbominira tan lawọn to mọ wi pe gbogbo agbaye lo fẹ kawọn bọ lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Apa ti wa ni ara wa bayii, amọ, a gbagbọ wi pe apa naa yoo san nigba to ba ya.

Arabinrin naa dupẹ lọwọ ijọba, awọn ẹṣọ eleto aabo ati gbogbo eeyan ti wọn kopa kan tabi omiran lati ri pe wọn gbominira lọwọ ajinigbe.

''Lọjọ ti a sin sọja tawọn ajinigbe naa pa ni a doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe''

Ẹwẹ, Ọgagun Chinedu Ralph Nnebeife to jẹ olori barike ologun to wa niluu Ibadan to ṣagbatẹru bawọn ẹṣọ eleto aabo ṣe doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ Oriire ṣalaye pe awọn ologun bẹ sinu igbo pẹlu awọn ọlọdẹ atawọn fijilante lẹyin toun gba ipe wi pe awọn janduku ajinigbe ti ṣọṣẹ ni Esinele ati Yawota.

''O kọkọ lati ṣawari ibi ti wọn ko awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa si ninu igbo pẹlu ẹrọ ''drone'' wag an an.

Lẹyin naa ni a tun lọ tun ara mu, amọ, sọja kan ku nigba ti awọn mii si farapa nibi ti a ti n gbiyanju lati doola awọn ti wọn ji gbe ninu igbo.

Bayii ni awọn oniruuru ikọ ọmọgun kaakiri orilẹede Naijiria darapọ mọ wa to fi mawọn ọlọpaa, DSS, NSDC, fijilante atawọn ọlọdẹ.

O ṣe pataki lati sọ pe awọn ọlọdẹ kan naa padanu ẹmi wọn sọwọ awọn ajinigbe yii.

O ṣeni laanu wi pe olukọ meji lo ku si akata awọn ajinigbe yii,'' Ọgagun Nnebeife lo sọ bẹẹ.

Oṣu kan gbako ni o gba wa lati ṣiṣẹ idoola awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe yii.

A ni lati maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn agbodegba awọn ajinigbe yii lawon ipinlẹ bii Adamawa, Kano atawọn ipinlẹ mii.

Ibanujẹ lo jẹ wi pe lọjọ ti a sin sọja tawọn ajinigbe nipinlẹ Adamawa ni a doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso ti darapọ̀ mọ́ ẹbí wọn lẹ́yìn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé

Awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso ti darapọ mọ ẹbi wọn bayii, lẹyin ti wọn gba ominira lọwọ awọn janduku ajinigbe.

Ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to lọ ni wọn ji awọn eeyan naa gbe lọ nile ẹkọ girama to wa ni Ahoro-Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ Yawota nijọba ibilẹ Oriire ni ipinlẹ Oyo.

Ọjọ mẹrindinlọgọta gbako ni wọn lo lakata awọn ajinigbe ninu igbo kawọn ẹṣọ eleto aabo to doola wọn lopin ọsẹ to kọja.

Ṣaaju ni Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ pe o ṣeeṣe kawọn eeyan naa darapọ mọ ẹbi lonii ọjọ Aje lẹyin ti wọn ba ti gba itọju fun ọjọ meji nile iwosan awọn ologun ti wọn gbe wọn lọ niluu Ibadan.

Ó ṣeéṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Oriire darapọ̀ mọ́ mọ̀lẹ́bí wọn lónìí

Oni ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2026 lo ṣeeṣe ki awọn akẹkọọ ati olukọ Oriire pada lọ darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn.

Ọjọ Ẹti to kọja lawọn eeyan naa gba itusilẹ lẹyin ti awọn ologun ya bo ibuba ti awọn agbesunmọmi naa ko awọn eeyan ọhun si ninu igbo kijikiji.

Ọjọ mẹrindinlọgọta gbako lawọn eeyan naa lo lakata awọn agbesunmọmi ọhun ṣaaju itusilẹ wọn.

Ile iwosan ologun 2 Division Nigerian Army Medical Services, to wa ninu ọgba ọmọ ogun ni Odogbo, niluu Ibadan ni wọn ti n gba itọju.

Lasiko ti gomina Seyi Makinde ṣabẹwo sawọn eeyan naa, o sọ pe wakati mejidinlaadọta ni wọn yoo fi gba itọju ki wọn to lọ darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn.

Makinde kéde ìgbà tó ṣeéṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Oriire darapọ̀ mọ́ mọ̀lẹ́bí wọn

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe awọn kan lara awọn akẹkọọ Oriire to ṣẹṣẹ gba itusilẹ n ṣaarẹ amọ wọn ti n gba itọju lọwọ.

Makinde lo sọrọ naa lọjọ Abamẹta lẹyin to lọ ṣabẹwo si awọn ọmọ atawọn olukọ ọhun ti wọn ṣẹṣẹ gba itusilẹ lakata ajinigbe.

Ile iwosan awọn ọmọ ogun, 2 Division Nigerian Army Medical Services, Odogbo, to wa ninu ọgba awọn ologun niluu Ibadan ni wọn ti n gba itọju.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, akẹkọọ mọkandinlogoji ni awọn agbebọn naa ji gbe pẹlu olukọ meje, amọ gbogbo wọn ni wọn ti pada wale bayii.

O fi ẹmi imoore han si Eledua, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria atawọn oṣiṣẹ agbofinro mii fun akitiyan wọn lati dola awọn ọmọ naa.

"Ọmọ ogun ku lasiko ti wọn n doola awọn eeyan naa"

Makinde ninu ọrọ rẹ sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe lootọ ni ijọba doola gbogbo awọn eeyan to wa lahamọ ajinigbe, ijọba padanu awọn ọmọ ogun kan to kopa ninu idoola ẹmi naa.

Gomina ọhun ṣalaye pe ifaraẹnijin awọn to padanu ẹmi wọn ki awọn akẹkọọ ati olukọ naa le pada wale ni ijọba ipinlẹ Oyo ko ni gbagbe lailai.

Lẹyin naa lo ba gbogbo mọlẹbi awọn to padanu ẹmi ki awọn akẹkọọ ọhun le pada wale kẹdun.

Igba wo lawọn akẹkọọ ati olukọ naa yoo lọ darapọ mọ mọlẹbi wọn?

O ni awọn ọmọ naa ti wọn ṣẹṣẹ de lati ahamọ agbesunmọmi yoo wa lakata awọn eleto ilera fun ọjọ meji gbako fun itọju ati ayẹwo.

Makinde sọ pe lẹyin ayẹwo ati itọju wọn ni ijọba yoo to jọwọ wọn fun awọn mọlẹbi wọn.

Gomina naa mẹnuba ọkan lara awọn ọmọ naa to n fi gbogbo igba bere iya rẹ ki wọn to pe iya rẹ ko wa ri.

O ni gbogbo atilẹyin to yẹ ni ijọba oun yoo ṣe fun awọn eeyan naa latari iriri aburu ti wọn ti la kọja lakata agbesunmọmi.

Lẹyin naa lo ṣeleri pe oun yoo bun gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo gbọ nipa bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ati bi ijọba ṣe doola wọn.