You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àṣírí ti tú nípa àwọn tó wà nídìí ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ àti Olùkọ́ Esinele, ìbẹ̀rù ti ń báwọn ajínígbé náà, a ti mọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn - Ẹ̀ṣọ́ aláàbò
Lọwọlọwọ yii, iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe òye ti n foju han nipa ibi ti awọn akẹkọ ati olukọ tawọn agbebọn ji gbe ni Yawota ati Ẹsinẹlẹ ni osu kan abọ sẹyin.
Awọn ẹṣọ to n dọdẹ awọn ajinigbe naa ni wọn sọ pe wọn ti n sunmọ ibi tawon eeyan naa ati ajinigbe wa.
Gẹgẹ bi awọn ẹka ẹṣọ aabo ṣe n fidi ẹ mulẹ, wọn ni ẹkọ ti n fi oju mimu han lẹyin ti wọn ti mọ awọn to wa nidii ijinigbe naa, atawọn alajọṣiṣẹ pọ wọn.
Iroyin naa ni jinni-jinni si ti n ba awọn agbebọn naa bi iroyin ṣe sọ.
Koda, awọn ẹṣọ alabo sọ pe idaamu ti ba awọn ajinigbe naa bayii, ti aṣiri awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti n tu, ti wọn si ri i pe awọn ẹṣọ ti mọ awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Olori ọmọ ogun ori ilẹ lorilẹede yii, Ọgagun Waidi Shaibu, sọ pe awọn ti n sunmọ bebe aṣeyọri lati gba awọn to wa nigbekun ajinigbe naa silẹ.
Bawo lawọn ẹṣọ ṣe dọdẹ awọn ajinigbe naa?
Gẹgẹ bawọn ẹṣọ aabo gbogbo to n wọgbo pọ lori ọrọ yii ṣe n wi, wọn ko deede mọ oju opo tawọn ajinigbe naa n tọ lojiji.
Ọpọlọpọ ọsẹ ti wọn fi ṣe iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, itọpinpin abẹnu latọdọ awọn DSS lo ṣokunfa bi wọn ṣe mọ awọn eekan ninu ẹgbẹ agbesunmọmi yii.
Lẹyin ti wọn ti mọ awọn onilu to n lu fun iromi awọn amookunṣika yoku ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe mọ ibi tawọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ naa wa kaakiri orilẹede yii.
Igbesẹ tuntun yii n waye lai ti i pe ọsẹ meji ti awọn ẹṣọ kede pe awọn ti di oju opo kan tawọn ajinigbe naa le gba sa lọ.
Wọn kede nigba naa pe awọn tun fi kun bawọn ṣe n ṣọ awọn ibi to ṣee ṣe kawọn ajinigbe naa maa farapamọ si lagbegbe Igbo ọba ipinlẹ Oyo, nibi to ṣee ṣe ki wọn ko awọn ti wọn gbe pamọ naa si.
"Ẹru ti n ba awọn ajinigbe naa, ọkan wọn o balẹ, wọn si ti n fi han bayii pe awọn ṣetan lati fi awọn ọmọ naa silẹ."
Ẹnikan ninu awọn to sunmọ awọn ẹṣọ naa lo sọ bẹẹ.
Bakan naa ni ẹlomi-in ṣalaye pe awọn DSS atawọn ologun ko fi awọn ajinigbe yii lọrun silẹ, wọn fẹ mọ ibuba wọn gẹlẹ.
Eyi ni yoo mu ki wọn ri awọn to wa nigbekun naa gba jade lai farapa bo ṣe sọ.
Tẹ o ba gbagbe, akẹkọọ mọkandinlogoji (39) ati olukọ meje ni awọn ajinigbe naa gbe wọgbo lọ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un ọdun 2026 yii.
Awọn ile ẹkọ mẹta to wa ni Ahoro Esienele, Yawota ati Alausa l'Ogbomoso ni won ti ko wọn lọ.