Hezbollah kéde Naim Qassem gẹ́gẹ́ bíi olórí ẹgbẹ́ tuntun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ Hezbollah ti kede pe igbakeji akọwe ẹgbẹ naa, Naim Qassem, ni yoo di ipo olori tuntun mu bayii.

Naim Qassem ti wọn kede ẹ yii ni yoo rọpo Hassan Nasrallah, olori ẹgbẹ naa fun igba pipẹ, ko too pade iku ninu ikọlu Isreali kan to waye ni Beirut loṣu kẹsan-an .

Olori tuntun ti wọn kede ẹ yii jẹ ọkan lara awọn agba Hezbollah to ṣi ṣẹku, lẹyin ti ọpọ iku olori wọn ti ọwọ Isreali wa.

Iyansipo Naim n waye lasiko ti ogun to n lọ ni Lebanon n lagbara si i.

Naim Qassem ki i ṣe ọmọ ana ninu Hezbollah, o ti le ni ọgbọn ọdun to ti wa nipo akọwe ẹgbẹ naa, oju to pawo ninu Hezbollah ni.

Gẹgẹ bi ẹgbẹ yii ṣe wi, wọn ni igbimọ Shura lo yan Naim pẹlu ibamu ofin ẹgbẹ.

Ṣugbọn a gbọ pe ko sẹni to mọ ibi ti Naim wa bayii, bo tilẹ jẹ pe awọn iroyin kan sọ pe orilẹede Iran lo sa lọ nitori aabo.

Iran jẹ ibi isadi Hezbollah, nitori alatilẹyin ẹgbẹ naa ni wọn n ṣe.

Nigba ti wọn n kede igbega to de ba Qassem, Hezbollah fi atẹjade kan sita, ninu eyi ti wọn ti ṣapejuwe rẹ bii “olubukun to n lewaju".

Bakan naa ni atẹjade ọhun tun gboriyin fun olori to doloogbe, Nasrallah, pẹlu awọn mi-in ti wọn ti ba ogun ijagbara lọ.

Aṣiwaju ẹsin; Hashem Safieddine, ni wọn ko ba gbe ipo olori tuntun ti Naim gba yii fun, ṣugbọn wọn kede iku rẹ lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa.

Hezbollah fidi ẹ mulẹ pe ninu ikọlu Israeli kan ni Hashem ku si, ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin.

Àrọ̀nì ò wálé, Onikoyi ò sinmi ogun

Lati ọsẹ bii meloo sẹyin ni ikọlu Isreali si Lebanon ti n le si i, awọn ẹṣọ Hezbollah la si gbọ pe wọn doju ija naa kọ.

Bakan naa ni wọn ṣigun si awọn nnkan amayedẹrun to wa nibẹ lati ba wọn jẹ, ati awọn nnkan ija ogun wọn pẹlu.

Ni alẹ ọjọ Aje, ikọ ologun Isreali ju ado oloro si Ila-Oorun Lebanon, lori oke Bekaa, nibi ti awọn Hezbollah pọ si.

Gẹgẹ bi ẹka ilera Lebanon ṣe wi, ọgọta eeyan, (60) ni wọn ti ku ninu ikọlu naa, o si ju aadọta eeyan (50) lọ ti wọn fara pa.

Ikọ Israeli ko ti i sọ nnkan kan nipa ikọlu naa.

Wọn ni awọn fẹẹ ki awọn eeyan awọn to ha si ẹyin odi latari ikọlu Hezbollah pada wale lalaafia na.

Eeyan to din diẹ lẹgbẹrun mẹta, (2,700) lo ti ku ninu awọn ikọlu yii, ẹgbẹrun mejila ati ẹẹdẹgbẹta (12, 500) lo si ti fara pa gẹgẹ bi akọsilẹ ẹka ilera Lebanon ṣe sọ.

Hezbollah naa kọlu Isreali pẹlu ẹgbẹrun ado oloro lasiko kan naa, o si kere tan, eeyan mọkandinlọgọta (59), ku lapa Ariwa Israel, titi de ori apata Golan .