Janmole sọ fún mi kó tó kú nípa ohun tó fẹ́ ṣe pẹ̀lú àbíkẹ́hìn rẹ̀ láìmọ̀ pé ikú ti súnmọ́ - Alfa

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ eeyan lo n wa omi ẹkun mu nibi eto adura ọjọ kẹjọ fun gbajugbaja oṣere tiata, Janmọlẹ ni agbegbe Odo Ẹran, nilu Oyo.

Ana ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹsan osu Kẹfa ọdun yii ni adura ọjọ kẹjọ naa waye.

Adura ọjọ kẹjọ naa ni wọn se ni iranti gabjumọ osere tiata, Oloogbe Fatai Okiki Adeshina Oshin, ti ọpọ eeyan mọ si Janmọlẹ.

‎Tẹẹ ba gbagbe, oloogbe Janmole jade laye lọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 2026, ninu ijamba ọkọ lati ilu Ibadan si ilu Oyo.

‎Ninu Waasi rẹ, Imamu Gazali Sulaimon ran awọn eeyan leti wi pe gbogbo eeyan ni yoo ku, igba, akoko ati ilu ti yoo ti ṣẹlẹ nikan lo le yatọ.

‎Gazali ni oloogbe Fatai Adeshina ti gbe igbe aye, to si ti lọ sinmi, ṣugbọn bayii gbogbo iṣẹ ọwọ rẹ ni yoo sọ iru eeyan to jẹ nigba ti o wa laye ati lẹyin iku rẹ.

‎Alufa naa wa ran awọn eniyan leti pe wọn ni anfani lati tun igbese wọn ṣe, ki wọn si maa rin ọna to tọ nitori atunbọtan.

‎Bakan naa lo rọ awọn oṣere tiata lati nifẹẹ ohun aye mọ niwọn, ki wọn ma ba ṣi aye gbe, ati pe ohun ti yoo tan ni gbogbo rẹ.

Mo fẹ ki abikẹhin mi lọ gbe pẹlu akọbi mi obinrin - Janmọlẹ sọ̀rọ̀ silẹ, ko to ku

‎Ọkan ninu ohun ti oloogbe naa sọ silẹ ko to ku ni nipa aato idile rẹ.

Janmọlẹ ni oun fẹ ki abikẹhin ohun lọ maa gbe pẹlu akọbi obinrin oun ni ilu Iseyin.

Alufaa Gazali Sulaimon lo fidi ọrọ yii mulẹ nigbati o n sọ awọn ọrọ ti oloogbe naa ba a sọ ni kọrọ, ko to jade laye.

‎Suliamon ni "Okiki Oshin sọ fun mi wi pe ti saa ẹkọ ti a wayi ba ti dopin, ọmọ mi abikẹhin, Nasimat, ni mo fẹ ko lọ gbe pẹlu akọbi mi lobinrin nilu Iseyin.

Lẹyin irun asunba lo so ọrọ yẹn fun mi lai mọ wi pe ko ni pẹ, ti yoo fi ku."

‎Ninu ọrọ rẹ gbajugbaja oṣere tiata ẹni ti Ọpọ eeyan mọ si Ajanbadan kede wi pe awọn eeyan ṣetan lati gbe ẹru oloogbe náà, papajulọ awọn ọmọ ti oloogbe fi saye lọ.

Ọdun mẹtalelogun ni emi ati oloogbe ti wa papọ, lati igba ti mo ti wa ni ọdọ ni mo ti n jo lẹyin rẹ ninu ere tiata - Monsuru ọmọ Alfa

Ayanfe Adekunle, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Monsuru Ọmọ Alfa, ni ọdun mẹtalelogun ni oun ati oloogbe ti jọ wa papọ.

‎O ni ifẹ to wa laarin oun ati oloogbe pọ gan nitori nigbati oun jẹ ọdọ ni oun ti ma n jo lẹyin ologbe ti wọn ba n ṣe ere ori itage.

‎Ayanfe Adekunle ni oju ọna Ilu Ijebu Ode ni oun wa, ti iroyin iku oloogbe fi kan oun lara, o ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi igi to tọ, ti ko pẹ ninu igbo.

‎Iku Janmole lo si jẹ iyalẹnu fun ọpọ ololufẹ rẹ papaa julọ pẹlu bi ori ṣe ko o yọ ninu ijamba ọkọ kan ni nnkan bi ọdun kan sẹyin.

Amọ o wa padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ miran lọdun yii.

"Oriyomi ṣeleri lati gbe bukata eto ẹkọ awọn ọmọ oloogbe de ẹkọ ile ẹkọ giga, TAMPAN fun wọn ni N1.5m"

‎Lara awọn to ṣeleri lati tọju awọn ọmọ oloogbe ni, Okiki Marketers to ṣeleri lati ma fun abikẹhin oloogbe naa ni ogoji naira losooṣu.

Ẹlomiran ti wọn fi orúkọ bo lasiri tun ṣeleri lati maa san owo ile ẹkọ awọn ọmọ oloogbe naa meji, to wa ni ile ẹkọ giga.

‎Lara awọn miran to tun ṣeleri iranlọwọ fun ẹbi oloogbe Janmọlẹ ni Oriyomi Hamzat to tun jẹ gbajugbaja sọrọsọrọ n'ilu Ibadan.

Oriyomi lo ṣeleri lati ran awọn ọmọ ologbe naa lo si ile ẹkọ titi ti wọn fi pari ẹkọ ile ẹkọ giga yoo wu to ba wu wọn.

‎Awọn agbarijọpọ awọn oṣere tiata ipinlẹ Oyo lo peju sibi adura ọjọ kẹjọ fun oloogbe naa.

Alaga ẹgbẹ TAMPAN ni ipinlẹ Oyo, arabinrin Bose Akinola wa kede pe awọn oṣere tiata fun awọn idile oloogbe naa ni millionu kan aabọ naira.