You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọọba ilẹ̀ Jordan sẹ ìgbéyàwó, àwọn ènìyàn ní àgbáyé péjọ síbẹ̀
Ọmọọba orilẹede Jordan, Prince Hussein ti ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ.
Orilẹede Jordan ni igbeyawo naa ti waye, ti awọn eniyan jankan-jankan lati awọn orilẹede lagbaye si pejọ sibẹ.
Ọmọọba Ilẹ Gẹẹsi, Willam ati iyawo rẹ, Kate wa lara awọn to peju peṣẹ sibi igbeyawo naa.
Bakan naa ni iyawo aarẹ orilẹede Amẹrika, Jill Biden naa wa ni ibi igbeyawo naa pẹlu Ọba ilẹ Netherlands, to wa ni ikalẹ lati ṣe awọn tọkọ-taya si.
Ọmọọba Hussein lo ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ to jẹ onimọ nipa ile kikọ ti awọn oloyinbo n pe ni architect, Rajwa Aiself.
Olo-ilu orilẹede naa, Amma ni igbeyawo naa ti waye ni aafin ọbs Zahran Palace.
Aafin yii naa ni wọn ti ṣe igbeyawọ baba rẹ, Ọba Abdullah II, ni Ọjọ Kẹwaa, ọdun 1993.
Igbeyawo naa n waye lasiko ti aigbọraẹniye n ṣẹlẹni idile ọba naa, ti ija si waye laarin ọba ati aburo rẹ ti wọn jọ ni baba kan naa ti orukọ rẹ n jẹ Prince Hamza.