'Wọ́n ni kí a pa àwọn ajá wa ní tipátipá, ajá tó lé ní 400 ni wọ́n ti pa'

Aja to yan ahọn sita

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn olugbe ilu Hossana ni ẹkun aarin gbungbun orilẹ ede Ethiopia ti ni ọpọ awọn aja awọn ni wọn pa nitori iṣẹlẹ aja to maa n ge awọn eeyan jẹ to n waye lemọlemọ ni agbegbe naa.

Awọn ara adugbo atawọn alaṣẹ agbegbe naa ni pipa awọn aja naa bẹrẹ lẹyin ti awọn ọmọde mẹta jade laye latari aja to bu wọn jẹ.

Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye, awọn alamojuto agbegbe naa pa a ni dandan fun awọn olugbe agbegbe naa lati pa aja wọn koda to ba jẹ pe wọn ti gba abẹrẹ fun aja naa.

Wọn ni wọn mu ni dandan fun awọn to ni aja lati fi okun pa aja wọn tabi ki wọn lu wọn pa. Niṣe ni awọn to ba kọ maa san owo itanran 50,000 Birr ($300), ti wọn yoo si tun fawọn le awọn agbofinro lọwọ.

Ọkan lara awọn to n gbe agbegbe naa ti ko fẹ ki a darukọ oun sọ fun BBC pe wọn bẹrẹ si ni pa awọn aja ni agbegbe naa lẹyin ti aja bu ọmọ iya kan naa meji jẹ, ti awọn mejeeji si jade laye.

O ni wọn sọ fun gbogbo awọn to ni aja, pẹlu awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara fun aja wọn tabi bẹẹ kọ lati pa aja wọn, ti wọn si ṣe bẹẹ fun ọpọ ọjọ ki awọn alaṣẹ ilu naa to kọwẹ ranṣẹ sawọn alaṣẹ agbegbe lati da eto naa duro.

Ẹlomiran ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Alaazar Kebede, ẹni to jẹ onimọ nipa awọn ẹranko sọ pe wọn fi ọlọpaa mu awọn to kọ lati pa aja wọn.

Alaazar ni aja to le ni irinwo, 400 si 450 ni wọn pa laaarin ọjọ perete.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni awọn eeyan wọ aja wọn sita ti wọn si n pa wọn lọna to yani lẹnu.

"Kii ṣe ohun to jẹ itẹwọgba ninu ẹsin, aṣa tabi ofin. Kii ṣe ohun ta ba ofin mu rara to si yẹ ki wọn fi ọwọ to o. Awọn fidio ṣafihan bawọn eeyan ṣe n sunkun nigba ti wọn n pa awọn aja wọn.

"Gẹgẹ bi dokita awọn ẹranko, inu mi bajẹ gidi. Ni ọjọbọ ọsẹ to kọja ni wọn bẹrẹ pipa awọn aja naa, ti wọn si ṣe e fun ọpọ ọjọ, a si n gbọ iroyin pe wọn o tii dawọ duro."

Mayor ilu Hossana, Samuel Shigute fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ mẹta pada nu ẹmi wọn latari bi aja ṣe bu wọn jẹ, tawọn eeyan to si le ni ọgọrin wa ni ile iwosan ti wọn n gba itọju.

O ṣalaye pe kii ṣe awọn to n ṣe akoso ilu kọ lo paṣẹ pipa awọn aja, tawọn si tete da duro ni kete ti awọn gbọ laaarin ọjọ kan.

"Ninu ile kan, ọmọ meji ti ọkan wa ni grade 6 ati 8 jade laye, lẹyin naa ni ọmọ ọdun mẹrinla mii padanu ẹmi rẹ nigba tgi wọn fi maa gbe de ile iwosan. Eyi lo muj awọn ara adugbo maa pa aja lọna aitọ."

Ni Hossana, aja to le ni ẹgbẹrun mẹwaa (10,000) lo wa nibẹ, tawọn ẹgbẹrun meje (7,000) ninu wọn si ti gba abẹrẹ ajẹsara.

Shigute ni ilu kekere ni pipa awọn aja naa ti bẹrẹ amọ ti awọn fi awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo mii dawọn duro laaarin ọjọ kan.

O ni ko si ibi ti iṣẹlẹ pipa aja ti n waye ninu ilu naa bayii.