Àwọn ológun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà sẹ́nu iṣẹ́ yawọ ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Osun, gba ọ̀pọ̀ fóònù, ohun ìní wọn - Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, others
Ileeṣẹ Ologun Naijiria tẹka ilu Osogbo ni ipinlẹ ti paṣẹ pe ki iwadii to loorin bẹrẹ lori ẹsun pe awọn oṣiṣẹ Ologun kan ti wọn ṣẹṣẹ gba sẹnu iṣẹ naa lọ yabo ile igbe awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti Osun State University.
Eyi lo n waye lẹyin ti Giwa agba ilẹ ẹkọ giga fasiti naa, Ọjọgbọn Clement Adebooye, awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa atawon akẹkọo ṣe iwọde ifẹhonuhan lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si di opopona Osogbo si Ikirun ni agbegbe Sasa ni ilu Osogbo.
Fidio kan to gba ori ayelujara lọjọ Iṣẹgun, Ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa ọdun 2026, ṣafihan ibi ti Ọjọgbọn Adebooye, to ṣaaju iwọde naa, ti n ba awọn akẹkọọ naa sọrọ to si juwe iwa ti awọn Ologun ọhun hu bi ohun to buru jai ti ko si yẹ ko maa waye laaarin ilu.
Awọn oluwọde naa n beere pe ki ileeṣẹ Ologun ṣawari awọn to wa huwa ibi sawọn akẹkọọ ati pe ekọ ni awọn wa kọ kii ṣe fun awọn Ologun lati maa fi ipa bawọn akẹkọọ obinrin sun.
Adebooye ninu fidio naa ni oun ti lọ ṣabẹwo si gbogbo awọn ibugbe akẹkọọ ti iṣẹlẹ naa ti waye ti awon nnkan ti oun ri ko dun mọ oun ninu rara.
"Mo lọ kaakiri ibugbe awọn akẹkọọ ni nnkan bii aago mẹjọ owurọ ti mo si ri bi wọn ṣe ba nnkan jẹ. Omi bọ loju mi pẹlu nnkan ti mo ri tawọn ologun naa ṣe fun awọn akẹkọọ wa paapaa awọn obinrin.
"Ohun to buru gbaa ni ki Ologun ni ki awọn obinrin bọ ara wọn si ihoho, ki wọn si maa fọwọ kan wọn lara lọna aitọ.
"Ọkan lara awọn ologu to ṣọṣẹ naa gbagbe fila rẹ, ko si ẹni to maa le sọ pe wọn kii ṣe Ologun.
"Wọn gba foonu, awọn power bank, owo ati ọpọ awọn dukia mii. Ogiri ni wọn fo wọnu ọgba awọn akẹkọọ, ti wọn si ni ki wọn wa gba foonu pada ninu baraaki Ologun to w ani ẹgbẹ ọdọ wa."
Adebooye fi kun pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti lọ fẹjọ sun ni baraaki awọn ologun Army Depot. O ni ileeṣẹ Ologun ti awọn ro pe o maa da aabo awọn akẹkọọ ni awọn oṣiṣẹ wọn hu iru iwa bẹẹ sawọn akẹkọọ.
A ti ri afurasi mẹta ninu awọn ologun to ṣiṣẹ ibi naa - ile ẹkọ fasiti Uniosun
Ṣaaju ni iroyin gbode ni ọjọ Iṣẹgun pe awọn Ologun lati baraaki Army Depot to wa niluu Osogbo yawọ ibugbe awọn akẹkọọ to wa ni agbegbe Oke Baale lalẹ ọjọ Aje ti wọn fi fiya jẹ awọn akẹkọọ, ko ohun ini wọn lọ.
Awọn akẹkọọ naa fẹsun kan pe foonu to le ni ọgọta atawọn ohun elo mii ni awọn ologun naa ko lọ.
Wọn fẹsun kan pe awọn ologun naa bọ awọn obinrin si ihoho, fọwọ tẹ wọn lara, ti wọn si na awọn ọkunrin lọna aitọ.
Agbẹnusọ ile ẹkọ naa, Ademola Adesoji sọ pe awọn akẹkọọ to le ni ogun ni awọn ti ṣawari gẹgẹ bi awọn ti Ologun naa ṣe ni ṣuta.
O ṣalaye pe meji ninu awọn akẹkọọ lo balẹ sile iwosan latari iya ti wọn fi jẹ wọn amọ ti ẹnikan ti pada sile ni tirẹ.
Adesoji ni wọn ti ṣawari afurasi mẹta pe wọn lọwọ ninu ikọlu naa ati pe ilẹ ẹkọ naa ti n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Ologun lati ṣawari awọn to huwa ibi naa.
Ileeṣẹ ologun bẹrẹ iwadii
Ileeṣẹ Ologun ti wa fesi sawọn ẹsun naa ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ Ologun tẹka Depot Army, Ọgagun Yahaya Ibrahim fi lede pe iwadii kikun ti bẹrẹ lori ẹsun naa.
Ọgagun Yahaya ninu atẹjade naa sọ pe ojuṣe ileeṣẹ Ologun ni lati da aabo bo awọn araalu paapaa awọn ọdọ to jẹ ọjọ ọla orilẹ ede, pe iwa to ba ti lodi si eyi jẹ ohun ti ko jẹ itẹwọgba nileeṣẹ Ologun.
O ni ko yẹ ki akẹkọọ kankan tabi araalu to n tẹle ilana ofin koju idunkoko tabi ifungunmọ latọwọ awọn to yẹ ko da aabo bo ẹmi ati dukia wọn.
O fi kun pe iwadii kikun ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa labẹ ilana ileeṣẹ Ologun Naijiria lati foju awọn to lọwọ ninu iwa ibi naa wina ofin.




























