VDM fẹ̀sùn kan Makinde pé ó san owó ìtúsílẹ̀ fun àwọn tó jí olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Oriire, wo ohun tí ìjọba sọ nípa rẹ̀

VDM ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/VDM/Seyi Makinde

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe irọ ni ọrọ Martins Vincent Otse, ti ọpọ mọ si VeryDarkMan tabi VDM pe oun ti san owo itusilẹ awọn olukọ ati akẹkọọ ti awọn agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ oriire.

Ṣaaju ni VDM ti kọkọ sọ ninu fidio kan gẹgẹ bii iṣe rẹ pe Aarẹ Bola Tinubu ti gbagbe ọrọ awọn ọmọ naa, ijọba ipinlẹ Oyo ti san owo itusilẹ wọn sibẹsibẹ awọn ajinigbe naa kọ lati tu awọn eeyan ọhun silẹ.

VDM ni oun sọrọ naa gẹgẹ bii iroyin to tẹ oun lọwọ to si jẹ ootọ.

O ni gbogbo araalu lo ti pa ọrọ awọn ọmọ naa ti bayii ti onikaluku si n ba iṣẹ oojọ rẹ lọ,

VDM sọ pe "A ko mọ irufẹ ipo ti awọn ọmọ naa wa bayii.

"A ko mọ boya awọn ọmọ ọhun ṣi wa laaye, a ko tilẹ mọ boya wọn ṣi wa ninu ipinlẹ Oyo tabi wọn ti ko wọn lọ si orilẹede mii."

Amọ nigba ti ijọba Oyo yoo fesi, o ni ko si ootọ kankan ninu ọrọ VDM.

Ninu atẹjade kan loju opo X, ijọba Seyi Makinde sọ pe awọn ko san owo itusilẹ kankan fun agbesunmọmi lati tu awọn ọmọ naa silẹ ninu igbekun.

Ijọba Oyo sọ pe kaka ki awọn san owo itusilẹ, niṣẹ lawọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn agbofinro lati wa ọna ti awọn eeyan naa ti wọn wa ni ahamọ yoo fi gba itusilẹ.

Wọn ni "Irọ ni o, Ijọba ipinlẹ Oyo ko fi akoko kankan san owo itusilẹ kankan lati gba itusilẹ awọn ọmọde ati olukọ wọn ti wọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire.

"Niṣe ni ijọba n fowọsowọpọ pẹlu awọn eleto aabo lati ri daju pe awọn eeyan naa pada wale layọ ati alaafia lati darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn."

Oni gan lo pe aadọta ọjọ ti wọn ji awọn olukọ atawọn akẹkọọ naa gbe ninu ọgba ile ẹkọ wọn niluu Ahoro Eshiele ati Yawota.

Ìjọba àti ẹgbẹ́ NUT ìpínlẹ̀ Oyo rọ àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n padà sílé ẹ̀kọ́

Seyi Makinde wọ asọ alawọ aro ati fila pupa

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

‎Kọmisona fun eto ẹkọ ipinlẹ Oyo, Segun Olayiwola ti rọ awọn olukọ ile ẹkọ kaakiri ipinlẹ Oyo lati pada si ẹnu iṣe wọn.

‎Segun Olayiwola ninu ipade to ṣe pẹlu awọn ti ọrọ eto ẹkọ kan nipinlẹ Oyo, ṣalaye wi pe, pẹlu iwa ijinigbe to waye nilu Ahoro Esinele ati Yawota, lootọ o bani ninu jẹ, ṣugbọn iṣe ijọba apapọ ni lati pese aabo fun gbogbo ọmọ Naijiria.

‎Olayiwola ni gbogbo eto lo ti wa nilẹ lati pese aabo fun awọn ile ẹkọ ni ipinlẹ Oyo, paapaa julọ awọn ile ẹkọ to wa ni awọn agbegbe ti oṣeeṣe ki awọn afurasi janduku ṣọṣẹ tabi ṣe ikọlu si.

‎Ninu ọrọ rẹ Olayiwola ni "dida lo da tọmọ wọgbẹ, iru eto oṣelu ta n lọ ni Naijiria ile iṣe ọlọpaa, ologun, iko abo ara ẹni labo ilu (NSCDC) labẹ ijọba apapọ ni wọn wa, ninu wa lari wi pe eto aabo yii ko to la ṣe da Amotekun silẹ.

Amotekun ati Man O War ni yoo pese aabo nile ẹkọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎"Eniti ko ba si ni ipinlẹ Oyo ni ko ni mọ pe Amotekun n ṣiṣẹ ṣugbọn ko to, awa ninu ipade pọ pẹlu awọn ikọ Man O war ki wọn maa mojuto aabo awọn ile ẹkọ wa, ṣe ẹ mọ wi pe fífi imu finlẹ gan ni eto aabo,

‎"Ti wọn ba ri nnkan ti wọn sọrọ soke, awọn eleto aabo yoo tete ṣiṣẹ won, ti ẹ ba lo si ẹgbẹ ile iṣe ijọba ẹ o ri ọkọ ayọkele Hilux ti ko din ni aadọta, a si tun n reti si, awọn ẹlẹsọ aabo na ni a o gbe fun".

‎O tẹnu mo wi pe ijọba ipinlẹ Oyo ti ṣe ikede jakejado awọn ilu to wa lagbegbe awọn ijọba ibilẹ ti oṣeṣe ki yanpọnyarin ti le sẹlẹ lati fi to awọn oṣiṣẹ alaabo leti ni kete ti wọn ba ri ohun to yatọ lagbegbe wọn.

‎Oludamoran pataki si gomina ipinlẹ Oyo lori eto ẹkọ, Abiodun Suraj Tiamy ni, gbogbo awọn olukọ to wa ni igberiko ni ijọba ipinlẹ Oyo yoo pese aabo to daju fun.

‎O rọ awọn olukọ ati obi lati jọwọ awọn akẹkọọ ki awọn olukọ si pada sẹnu iṣe wọn ki eto ẹkọ le bẹẹrẹ pada.

‎O ṣe idaniloju fun gbogbo awọn ọmọ bibi ipinlẹ Oyo wi pe, awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni akata awọn agbebon ni yoo wale laipe yii.

‎Ijọba ipinlẹ Oyo ti peṣe aabo - NUT

‎Alaga ẹgbẹ olukọ, NUT, ni nipinlẹ Oyo, Hassan Ajibola ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin ile iṣe BBC Yoruba ṣalaye wi pe, ninu gbogbo ipade ti ẹgbẹ oṣiṣẹ pẹlu ìjọba ipinlẹ Oyo ṣe lori ipese aabo ni o ti ni iyanju.

‎O ni ijọba ipinlẹ Oyo ati ẹgbẹ olukọ ti fẹnu ko ki ijọba ipinlẹ Oyo gbe eto aabo ile ẹkọ dìde ìyẹn "Safe Schol" ti ikọ NSCDC ti ipinlẹ Oyo yoo daari.

‎Ajibola sọ pe lara awọn ẹgbẹ ti yoo tun wa ninu iko ti yoo se amojuto eto aabo ni, awọn Amotekun, ẹgbẹ fijilante ati awọn ọdẹ ilu.

‎Alaga NUT naa sọ siwaju si ori bibẹ ko ni oogun ori fifo, nitori bi awọn akẹkọ ti wa ni ile lai ka iwe ko dara rara.

‎Oni gbogbo ile ẹkọ to wa ni igberiko ni awọn ẹsọ alaabo tuntun yii yoo de, nitori awọn to wa ni agbegbe naa ni yoo wa ninu awọn ẹsọ alaabo wonyi.

‎O pari ọrọ rẹ pe olukọ kọọkan ko gbọdọ woṣẹ niran, niwọn igba ti atẹjade ti jade lati ọdọ ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Oyo, kí wọn si pada sẹnu iṣe wọn lai fakoko ṣofo.