WHO kéde ìkìlọ pàjáwìrì jakèjadò àgbáyé lórí ààrùn Monkey Pox

Published

Ajọ ilera lagbaye WHO ti fi ikede pajawiri sita lori aarun Monkey Pox lagbaye.

Ikede yi si ni eleyi to gajulọ ti ajọ naa le fi sita ko si sẹyin bi aarun naa ṣe kale kako lagbaye.

Ikede yi ti wọn sọ di mimọ lẹyin ipade ẹlẹẹkeji igbimọ pajawiri aarun naa sọ pe eeyan ẹgbẹrun mẹrindinlogun lo tilugbadi Monkey Pox lorileede marundinlọgọrin lagbaye.

Ọga agba WHO Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus lo sọ bẹẹ.

Nibi ọrọ de duro WHO sọ pe eeyan marun un ni o padanu ẹmi wọn latara arun yi.

Ni bayi, awọn arun to ni iru ikede pajawiri yi lagbaye ko ju meji lọ, Coronavirus ati igbiyanju lati mu opin ba aisan rọpa rọsẹ lagbaye taa mọ si Polio.

Dokita Tedros ni igbimọ pajawiri naa ko ti ribi fẹnuko boya ki wọn ka aarun Monkey Pox gẹgẹ bi aarun ti ajakalẹ rẹ kaakiri agbaye.

Ko fi gbogbo ara ye wọn bi itankalẹ aarun yi ṣe n gbalẹ gẹgẹ bi Dokita Tedros ti ṣe sọ.

O ni ''ayẹwo taa ṣe fihan pe ewu itankalẹ yi ko kọja agbara kaakiri agbaye ayafi lawọnn agbegbe ilẹ yuroopu nibi ti ewu yi ti lagbara ju''

''A ko ni ẹri pe aarun yi le tankalẹ jakejado agbaye a ko si le sọ pe yoo ṣakoba fun lilọ bibọ awọn eeyan lagbaye nitori eleyi ko kọja agbarta lasiko yi''

Ààrùn 'Monkeypox', bí mó ṣẹ lè kó àti òhun míì tó yẹ ní mimọ

O kere tan WHO ti kede pe wọn ri eeyan mejilelaadọrin to ti lugbadi aarun yi ni Yuroopu,Amẹrika,Canada,Australia.

Wọn si ti se iwadii eeyan mejidinlọgbọn ti wọn furasi pe o lugbadi aarun yi lawọn orileede mejila ti monkeypox kii saba ran kaakiri.

Sugbọn sa, awọn onimọ ni eleyi kii se bi ajakalẹ Covid-19 ati pe awọn ni ikapa lori ajakalẹ yi.

Ki ni Monkeypox?

Monkeypox jẹ aarun ti kokoro aifojuri monkeypox le sokunfa rẹ.

O yatọ si kokoro aifojuri smallpox sugbọn oun ko buru to arun igbona 'smallpox'.

Lagbegbe aarin gbungbun ilẹ Afrika lo wọpọ si ati iwọ oorun ilẹ Afrika ni paapa lawọn agbegbe ti igbo kijikiji wa.

Ni orileede DR Congo lawọn ibi ti igbo kijikiji wa, wọn ti kede pe o leni eeyan 1,200 to ti ko aarun yi lọdun yi nikan.

Wọn ni akọsilẹ eeyan mẹtadinlọgbọn to ku laarin ọjọ Kini osu kaarun 2022 gẹgẹ bi WHO se sọ.

Amọ lọwọ lọwọ bayi, awọn ilẹ Yuroopu lo wa ninu ewu julọ lọwọ arun yi bayi lagbaye.