Olùkọ́ tí wọ́n ló ń fipá bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lò pọ̀ l’Ógùn bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá

Published

Ọkunrin tiṣa kan, Ọlaniran Lateef Adewale, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu bayii lori ẹsun fifi ipa ba awọn akẹkọọbinrin lo pọ.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣe wi, ileewe Ebenezer Grammar School, Ibẹrẹkodo, l’Abẹokuta ni Ọlaniran ti n kọ awọn akẹkọọ lẹkọọ iṣiro. Ọmọ Ipokia si ni.

Ọjọ kẹrin oṣu kọkanla yii ni ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Kazeem Wọnuọla, ti kọkọ lọọ fi ẹjọ rẹ sun nileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin l’Ogun, lori ifipa ba akẹkọọ lo pọ.

Wọnuọla sọ pe Lateef maa n tan awọn akẹkọọbinrin wọle rẹ, yoo si fipa ba wọn lo pọ.

Bakan naa ni Kọmiṣanna to n ri si ọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ogun, Adijat Adelẹyẹ, ṣalaye pe lọjọ tawọn eeyan oun pelu awọn ọlọpaa de ile tiṣa yii lati mu un fun ẹsun akọkọ, ibi to ti n fipa ki ọmọbinrin akẹkọọ mi-in mọlẹ lawọn tun ba a.

Gẹgẹ bi Adelẹyẹ ṣe wi, ’’A gbọ ti ọmọbinrin kan n pariwo nigba ta a wọnu ọgba ile tiṣa, ọmọbinrin naa fẹsun kan an pe o fipa ba oun lo pọ, o si tun dunkooko pe oun yoo pa a bi ko ba pe awọn ẹbi rẹ lati fowo ranṣẹ soun.

’’Pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpaa, a mu Ọgbẹni Ọlaniran Lateef Adewale to n kọ wọn niṣiro nileewe Ebenezer Grammar School, Ibẹrẹkodo, Abẹokuta. Nọmba iwọṣẹ rẹ ni OGNO.3O650’’

Iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii bawọn ọlọpaa ṣe wi, afurasi tiṣa naa si ti wa lahaamọ ọlọpaa.

Bẹẹ ni Gomina Dapọ Abiọdun ti gba awọn araalu nimọran lati ma ṣe dakẹ bi wọn ba kẹẹfin ohun to lodi sofin.