Ṣé òótọ́ ni àwọn ọlọ́pàá ń kan sáárá sáwọn agbébọn lásìkò tí wọn ń kọjá lórí ọ̀pọ̀ ọ́kadà lójú pópó?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fidio kan ti n lọ lori ayelujara eyi to ṣafihan bi awọn eeyan kan, ti wọn pọ biba lori ọkada, ṣe n kọja lẹgbẹ awọn ọlọpaa, ti awọn ọlọpaa naa si n kan saara si wọn bi wọn ṣe n kọja.

Awọn eeyan naa ti a ko ri oju wọn daadaa, wa lori ọkada ti wọn n kọja, awọn kan lara wọn si gbe ibọn abalaye dani.

Akọle to wa lara fidio naa ni pe niṣe ni awọn ọlọpaa n gboriyin fun awọn ọlọpaa bi wọn ṣe n kọja ni ibudo ayẹwo awọn ọlọpaa ni ẹkun ariwa Naijiria.

Amọ se lootọ ni isẹlẹ yi waye ati pe, se lootọ ni awọn osisẹ ọlọpaa to wa loju popo naa n kan saara sawọn agbebọn ọhun?

Awọn fijilante atawọn ọlọdẹ to n ṣe iranwọ fawọn ẹṣọ alaabo lati koju awọn agbebọn nipinlẹ Katsina, lo n kọja lori ọpọ ọkada, kii se awọn agbesunmọmi - Ọlọpaa

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti wa sọrọ iroyin to gba ori ayelujara naa pe awọn ọlọpaa n yin awọn agbebọn to n kọja ni ẹgbẹ wọn ni ẹkun ariwa Naijiria.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ti wa jiyan ẹsun naa ti wọn si ni awọn eeyan to wa lori ọkada naa kii ṣe agbebọn, pe ọlọdẹ atawọn fijilante ti wọn forukọ silẹ pẹlu ijọba ni wọn.

O ni awọn fijilante atawọn ọlọdẹ naa to n ṣe iranwọ fun awọn ẹṣọ aabo lati koju awọn agbebọn to n ṣọṣẹ ni ijọba ibilẹ Musawa ati Matazu, ipinlẹ Katsina, lo n kọja lori ọkada naa.

Atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Anietie Iniedu fi lede lọjọru ni wọn ti ṣe afọmọ ọrọ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn eeyan naa n lọ si ibi ti wọn ti fẹ lọ ṣeranwọ fun awọn ẹṣọ aabo lati koju iwa ọdaran ati mimu aato to peye w ani agbegbe naa ni bi wọn ṣe n kuro nibẹ.

Iniedu ninu atejade fi kun pe ohun ti wọn kọ sori fidio naa jẹ ojuna lati ṣi awọn eeyan lọkan, ti wọn si n mọọmọ gbe iroyin ofege lati tabuku ileeṣẹ ọlọpaa.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn araalu lati ma tẹle awọn nnkan ti wọn kọ sori fidio naa, ki wọn si maa ṣewadii awọn iroyin ti wọn ba ri daadaa ki wọn to maa gba a gbọ.

Atẹjade naa tun ṣekilọ fun awọn to maa n gbe iroyin ofege lati jawọ ninu ṣiṣe bẹẹ tabi ki wọn foju wina ofin nitori wọn n ṣi awọn eeyan lọkan.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ṣekilọ fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ to ba n pese tabi pin iroyin ofege eyi to le da omi alaafia ilu ru, to si le ba iṣẹ awon ẹṣọ jẹ lati jawọ nitori a maa bẹrẹ si ni igbe igbesẹ ofin tako ẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n ṣe bẹẹ."

Bakan naa ni wọn tẹnumọ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tun maa tẹsiwaju lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn to ba le pese aabo, to si le ṣeranwọ fun awọn ẹṣọ aabo ni gbogbo ibikibi lojuna ati koju iwa ọdaran ati lati da aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan kaakiri Naijiria.