Wọ́n yìnbọn pa ọkọ mini torí wọ́n ní kó wá rí olóṣèlú APC kan àmọ́ tó yarí kanlẹ̀ - Ìyàwó olóògbé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iyawo ọmọ egbẹ oselu Accord ti wọn pa ni ilu Esa-Oke, ijọba ibilẹ Obokun, ipinlẹ Osun ti n beere fun idajọ ododo lori iku ọkọ rẹ.

Obinrin naa, Tolulope Aderogba nigba to n sọrọ lasiko ti gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ṣe abẹwo ibanikẹdun sii lọjọru ṣalaye pe ni oju oun ni awọn janduku oloṣelu yinbọn pa ọkọ oun.

Gẹge bo ṣe ṣalaye, alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ni awọn janduku oloṣelu to fẹsun kan pe wọn n ṣiṣẹ fun oloṣelu kan, Wole Oke pa ọkọ oun.

Atẹjade kan ti gomina Adeleke fi soju opo X rẹ sọ pe Aderogba to jẹ iyawo Aderogba Ajayi sọ pe oun wa pẹlu ọkọ oun ni alẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.

"Ọkan lara awọn ọkunrin meji to bọ silẹ ninu mọto yinbọn mọ ọkọ mi ni ẹẹmẹta, ki ibọn naa to ba a, to si ṣubu silẹ"

O ni awọn wa papọ nigba ti ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Oladapo gbe ọkada de to si sọ fun ọkọ oun pe ko tẹle oun lọ ri ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Omoaje.

O sọ pe Oladapo n jẹ ko di mimọ pe Omoaje fẹ mu ọkọ oun mọ Wole Oke amọ ti ọkọ oun kọ jalẹ pe oun ko ni tẹle ati pe ti Omoaje ba fẹ ri oun, o mọ bi o ṣe maa pe oun.

Aderogba tẹsiwaju pe gbogbo bi Oladapo ṣe n gbiyanju lati yi ọkọ oun lọkan pada lati tẹle lọ sibi to n sọ ni ọkọ oun n kọ.

O ni ko pẹ pupọ ni ọkọ Toyota Sienna kan to ko ero bii mẹfa de bawọn nibi ti wọn ti n sọrọ naa tawọn ọkunrin meji ti wọn wọ aṣọ dudu si bọlẹ ninu ọkọ ọhun.

O fẹsun kan pe ọkan lara awọn ọkunrin meji to bọ silẹ ninu mọto naa yinbọn mọ ọkọ oun ni ẹẹmẹta, ni ibọn naa to ba a, to si ṣubu silẹ.

O ni nigba ti awọn eeyan fi maa ran oun lọwọ lati gbe de ile iwosan o ti jade laye.

Opo naa wa parọwa si Gomina Adeleke lati sa gbogbo ipa rẹ lati fi ba gba idajọ ododo lori iku oun, ki wọn si ṣe atilẹyin lati fi tọju awọn ọmọ mẹrin ti oloogbe naa fi saye.

Ọpọ igba ni mo ti fi fidio ati aworan ipaniyan ati ikọlu to n waye ni ipinlẹ Osun ranṣẹ si Kọmiṣanna ọlọpaa amọ ti ko ṣe ohunkohun sii - Gomina Adeleke

Nigba to n sọrọ, Gomina Adeleke ke pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Osun, Ibrahim Gotan lati ṣe iwadii to looorin lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi awọn to huwa laabi naa jofin.

Adeleke ni iwadii to munadoko gbọdọ waye lori iṣẹlẹ naa paapaa bi wọn ṣe ti darukọ awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun.

Gomina Adeleke ni ọpọ igba ni oun ti fi fidio ati aworan awọn ipaniyan ati ikọlu to n waye ni ipinlẹ Osun ranṣẹ si Kọmiṣanna ọlọpaa ti ko ni ṣe ohunkohun sii.

O tun ni oun ti yọju si ileeṣẹ aarẹ lori ẹsun kan naa bo ṣe fẹsun kan pe awọn olori ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Osun bii Oyetola, Wole Oke, Oyebamiji ati bẹẹ bẹẹ lọ n rọgun sapa awọn janduku ni ipinlẹ Osun lati maa ṣe iṣẹ ibi.

O fi kun pe oun n ka awọn ọmọ ẹgbẹ oun lọwọ ko lati ma ṣedajọ lọwọ ara wọn, ki wọn da gbogbo rẹ da ileeṣẹ ọlọpaa ṣugbọn to ni o ti n kọja afarada bayii.

Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan kan, ọpọ farapa nibi iwọde ipolongo APC

Ninu iroyin mii, eeyan kan ti jade laye ti ọpọ mii si farapa nigba ti tirela kan lọ kọlu awọn to n ṣe iwọde ipolongo fun oludije sipo gomina ipinlẹ Osun lẹgbe oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Oyebamiji.

Ni agbegbe Oke Gada, ilu Ede, ijọba ibilẹ Ede North ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọru gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.

Iroyin awakọ nla naa sọ pe ijanu ọkọ naa ni ko dede mu mọ ti ọkọ si ya lọ ba awọn to n ṣe iwọde ipolongo naa bi wọn ṣe n kọja lọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ni kete ti ijamba naa waye ni wọn sare gbe awọn to farapa lọ sile iwosan fun itọju.

Nigba to n sọrọ lori ijamba naa, agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu ni ipinlẹ Osun, Kola Olabisi fidi ijamba naa mulẹ to si ni ẹgbẹ oṣelu naa ti fi awọn eeyan ranṣẹ lati lọ ṣewadii ohun to waye nibi iṣẹlẹ naa.