You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ nìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ti fòfin de ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ẹ̀kọ́ girama àti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀? Ohun tí a mọ̀ rèé
Ijọba ìpínlẹ̀ Ogun ti sọrọ lori iroyin to tan kalẹ lori ayelujara wí pé ìjọba ti fòfin dè ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ẹ̀kọ́ girama, ati JSS 3 to fi mọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ.
Ijọba ṣàlàyé ninu atẹjade kan ti o fi sita wi pe ko si otitọ ninu iroyin naa.
Ijọba ṣalaye ninu atẹjade ti ẹka to n ri si eto ẹkọ, sayẹnsi ati imọ ijinlẹ fi sita pe kii ṣe awọn akẹkọọjade ile ẹkọ girama, ati tawọn alakọọbẹrẹ ni ijọba fofin de ayẹyẹ ikẹkọọjade wọn.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe ṣalaye, kilaasi awọn ọmọ ikoko tawọn oloyinbo n pe ni Kindergarten ati Nursery ni ijọba ti fofin de wi pe wọn n gbọdọ ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade mọ.
Idi abajọ ni pe kikẹkọọ jade lawọn kilaasi yii kii ṣe opin ipele ile ẹkọ kan.
Amọ, atẹjade ọhun sọ pe awọn to ba kẹkọọ jade yala nile ẹkọ alakọọbẹrẹ tabi ni girama yoo si maa ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade tori ipele awọn ẹkọ yii tumọ si pe awọn to n kẹkọọ jade n lọ si ipele ẹkọ tuntun.
Ijọba ipinlẹ Ogun ko ṣai kilọ wi pe awọn ile ẹkọ ko gbọdọ gba owo gọbọi lọwọ awọn obi awọn akẹkọọ to ba fẹ ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade mọ..
Koda, nnkan ti ijọba ipinlẹ Ogun sọ ni pe awọn obi ko gbọdọ da owo kankan fun ayẹyẹ ikẹkọọjade ọmọ wọn.
Ijọba fofin de rira aṣọ ẹbi fawọn akẹkọọ to n jade, gbogbo inawo tawọn ile ẹkọ fẹ ṣe gbọdọ wa ni iwọn tun wọn si.
Ọpọ eeyan lo ti kọminu wi pe awọn ile ẹkọ maa n ra oniruuru aṣọ to wọn, wọn si maa n kan nipa fawọn obi lati ra iru aṣọ bẹẹ fawọn ọmọ wọn.
Ijọba ipinlẹ Ogun ni oun ṣe agbekalẹ ofin yii lati daabo bawọn obi lọwọ awọn ile ẹkọ to maa n sọ pe ki wọn ra aṣọ olowo nla fawọn ọmọ wọn.
Ijọba wa rọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ, awọn obi ati gbogbo araalu lati ka koko to wa ninu ofin ti ijọba ṣe agbekalẹ rẹ lori ayẹyẹ ikẹkọọjade ni ipinlẹ Ogun.
Ẹwẹ, ijọba ti wa rọ awọn oludasilẹ ile ẹkọ lati maa tẹle alakalẹ ofin yii, nigba to rọ awọn obi lati sọ fun ijọba ti wọn ba ri ile ẹkọ kan to tẹlẹ naa.