You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìrìnàjò mi le gan an, ìdí rèé ti mi ò fi gbádùn ayé ní kékeré - Kamo State
Gbajumọ adẹrinpoṣonu to maa n ṣe fọnran kekeke lori ayelujara ti wọn n pe ni sikiiti, Akinyọọla Ayọọla ti ọpọ mọ si Kamọ State ti sọ pe oun ko gbadun aye nigba toun wa ni kekere.
O ni eyi ṣẹlẹ tori iya oun nikan lo wo oun dagba.
Kamo ni ile baba iya oun gan an ni oun gbe dagba ni kekere.
''Inu yara kan ni mo n gbe nigba naa pẹlu aloku rọọgi ti mo tẹ silẹ.
Bẹẹdi ti mo fi n sun ko laṣọ lara, ko si ẹrọ amohunmaworan, ko si nnkankan.
Emi ti mo wa lati ibẹyẹn ni mo wa di ẹni tawọn ilumọọka n patẹwọ fun,'' Kamo State lo sọ bẹẹ.
Kamo State sọ fun BBC Yoruba wi pe irinajo naa le gan an, bakan naa ni o sọ pe ọpọ eeyan ni ko ni igbagbọ ninu oun.
Kamo ni ọpọ eeyan lo sọ pe oun ko le de ibi kankan ninu aye, amọ, oun jẹ alagidi eeyan.
Alawada naa ni Eledua si maa n de igbiyanju oun lade nigba naa.
''Elere ori itage ni iya to bi mi lọmọ, amọ, ṣọọṣi ni wọn ti maa n ṣere ti wọn.
Lati igba ti mo ti wa ni kekere yii ni mo ti maa n ṣere ori itage, wọn maa n lo mi ninu ere ti wọn ba ti nilo ọmọ kekere.
Mo maa n pa awọn eeyan lẹrin-in lai ṣe wi pe mo fi ṣiṣẹ ṣe tẹlẹ.
Lati ibẹ ni mo ti bẹrẹ sii ṣe ere ori itage lati pa awọn eeyan lẹrin-in.
Nigba to ya ni mo bẹrẹ sii ṣe ''skit'', ọdun 2012 ni mo ṣe ''skit'' mi akọkọ ti mo si gbe e sori Facebook.