Ọkùnrin kan yìnbọn pa ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ márùn-ún kó tó pa ara rẹ̀

Published

Arakunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan ti pa eeyan meje ninu ẹbi rẹ, ko to o pa ara rẹ, ni ipinlẹ Utah, lẹyin ti iyawo rẹ jawe fun pe oun ko ṣe mọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ba oku awọn eeyan mẹjọ naa ninu ile wọn nilu Enoch City, ni alẹ ọjọ Ọjọru, lasiko ayẹwo ilu.

Wọn ni awọn oku naa ni iyawo ọkunrin naa, ọmọ rẹ marun-un, ati iya iyawo rẹ.

Nibi ipade to ṣe pẹlu awọn akọroyin ni Ọjọbọ, alamojuto ilu naa, Rob Dotson sọ pe Ọgbẹni Michael Haight, to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ adojutofo, yinbọn mọ iyawo rẹ, Tausha, ẹni ogoji ọdun, iya iyawo rẹ, Gail Earl, ẹni ọdun mejidinlọgọrin, ọmọ wọn marun-un, ati ara rẹ.

Awọn ọmọ marun-un na, obinrin mẹta (17,12,7), ati ọkunrin meji (7 ati 4).

Rob Dotson sọ pe awọn ọlọpaa ri oku wọn ni nkan bi aago mẹrin irọlẹ Ọjọru, lẹyin ti ẹnikan kegbajare lọ si agọ wọn pe iyawo ko yọju si ipade kan to yẹ ko lọ fun.

Eyi lo mu ki igbimọ to n ri si igbaye-gbadun araalu lọ si ile mọlẹbi naa, lati bẹ ẹ wo.

Ọgbẹni Dotson sọ pe gbogbo awọn oku naa lo ni ọgbẹ ibọn lara.

Awọn alaṣẹ sọ pe ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ni iyawo ja iwe ikọsilẹ fun nile ẹjọ.

Ẹnikan to jẹ ọrẹ mọlẹbi naa, Tina Brown, sọ fun ileeṣẹ iroyin KSTU-TV pe, ẹlẹyinju aanu eeyan ni Tausha, ti kii si sọrọ ọlọrọ lẹyin laida.

“O lawọ debi pe o le fun eeyan ni aṣọ kan ṣoṣo to ni, to si ma n yọnda ara rẹ fun anfaani ẹlomiran.”

Baalẹ ilu naa, Jeffrey Chestnut sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ to kan oun gbọn-gbọn, nitori pe alamuleti oun ni tọkọtaya naa.

“Awọn ọmọ wọn kekere ma n ṣere pẹlu awọn ọmọ mi ni ẹyinkule ile mi.”

Ilu enoch City ko tobi rara, eyi to mu ki iroyin iku ẹbi naa kan gbogbo eeyan bi ẹgbẹrun mẹjọ to n gbe nibẹ.

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ ti awọn ọmọ naa n lọ ti fi ikede sita lati kẹdun iku wọn.