You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lo ojú òpó yìí láti mọ̀ bóyá o ní ìfúnpá gíga tàbí wà nínú ewu láti ní i
Yiyẹ ifunpa rẹ wo ni ọna to dara ju lati mọ boya o ni aisan ẹjẹ riru, nitori ọpọ eeyan ni ki i apẹẹrẹ to le tọka si pe wọn ni ẹjẹ riru.
O fere to idaji ninu eeyan 1.3 billion ti wọn ni aisan ẹjẹ riru yii ti wọn ko si mọ.
Ilẹ Africa ni ẹjẹ riru ọhun pọ si ju pẹlu ida mẹtadinlọgbọn (27%), nigba ti tawọn America kere julọ. Tiwọn wa ni ida mejidinlogun (18%), gẹgẹ bi ajọ eleto Ilera Agbaye, World Health Organization, ṣe sọ.
Fun awọn orilẹede ti wọn ko rọwọ họri atawọn ko-la-ko-ṣagbe, awọn ni wọn ni agbalagba ti ifunpa wọn maa n ga ju, eyi ri bẹẹ nitori awọn ohun to le gbe wọn lọkan soke to kun awọn ilu naa.
Bi eeyan ba ni aisan ẹjẹ riru ti ko si tọju rẹ, oun ni wọn lo n fa awọn ailera to ga ju bii aisan ọkan, rọparọsẹ, ati ki kindinrin daṣẹ silẹ.
Ọpọ awọn aisan yii ni wọn lo si le fa iku ojiji, bi WHO ṣe ṣalaye.
O ṣe pataki lati maa yẹ ifunpa wa wo deede, lati le tete mọ bi eeyan ba ti ni ẹjẹ riru ati bi yoo ṣe tọju rẹ.
Wo awọn aworan yii lati jẹ ki o mọ bi ifunpa rẹ ṣe n ga si ati itumọ rẹ, bi ajọ WHO ṣe gbe e kalẹ, yoo si tun ran ọ lọwọ nipa igbesẹ to kan to yẹ ki o gbe lori ilera rẹ.