You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òǹyẹ̀ kan kò lè yẹ owó ìrànwọ̀ orí epo ‘sọ́búsídì’ tí a ń san – Ààrẹ Buhari
Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣe ìdádúró lórí yíyọ ìkúnpá orí epo bẹntiróòlù.
Ààrẹ ní ìpalára tí yíyọ epo bẹntiróòlù náà yóò ṣe fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pọ̀ púpọ̀ ju àwọn àǹfàní tí yóò mú wá lọ ni àwọn ṣe yẹ̀bá lórí ìpinnu náà.
Buhari ní àwọn ti parí gbogbo àwọn ohun tó yẹ kí àwọn ṣe lórí ìwé lórí bí yíyọ ìkúnpá orí epo náà ní ọdún 2021 ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ni àwọn ṣe da dúró.
Ó ní ìjọba ti ń ṣiṣẹ́ lórí ríri dájú pé àwọn èpò tí wọ́n ń pèsè jẹ́ ohun tí yóò tó ará ìlú lò àti pé àwọn ń gbìyànjú láti ri pé fífọ epo lábẹ́nú jẹ́ ohun tó ṣeéṣe.
Ó ní ìyàtọ̀ yóò tún bá ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù nígbà tí àwọn iléeṣẹ́ ìfọpo aládani bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títí ìparí ọdún yìí sí ọdún tó ń bọ̀.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ọ̀rọ̀ yíyọ ìkúnpá orí epo bẹntiróòlù yóò máa jà rànìnrànìn
Nínú oṣù Kọkànlá, ọdún 2021 ni ìjọba àpapọ̀ kéde pé àwọn yóò yọ ìkúnpá orí epo bẹntiróólù pátápátá.
Mínísítà fétò ìsúná àti ààtò ìlú, Zainab Ahmed nígbà náà ní àwọn yóò máa san ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà fún àwọn mẹ̀kúnù tí kò rí ọwọ́ họrí láwùjọ̀.
Ìjọba ní ọgbọ̀n tàbí ogójì mílíọ̀nù ènìyàn ni àwọn ń gbèrò láti fún nítorí ìnìra tí yíyọ ìkúnpá náà yóò mú bá àwọn ènìyàn.
Nínú oṣù Kẹfà ọdún 2022 ni ìjọba ní àwọn yóò fi ìpinnu léde lórí bóyà àwọn yóò tẹ̀síwájú lórí ìgbásẹ̀ náà.
Ìjọba tún yí ìpinu rẹ̀ padà
Ẹ̀wẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ọdún 2022, ìjọba tún yí ìpinnu yìí padà tí wọ́n sì ní àwọn kò ní yọ ìkúnpá orí epo mọ́ nítorí ó le ṣàkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé.
Mínísítà fétò ìsúná, Zainab Ahmed ní àkókò tí ìgbésẹ̀ yíyọ ìkúnpá náà bọ́ sí kò dára tó fún àwọn ènìyàn Nàìjíríà.
Ahmed ṣàlàyé pé ìjọba yóò ṣàgbéyẹ̀wò ètò ìsùnà ọdún 2022 kí wọ́n le ṣe àtúnṣe lórí bí wọ́n yóò ṣe fi fàyè gbàá.
Bákan náà ló ní àwọn yóò máa gbé ọkàn lé àwọn ilé ìfọpo aládani tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ láti máa pèsè epo lábẹ́lé.