Agbẹjọ́rò Akwa Ibom lu ìyàwó rẹ̀ lálùbami, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan afurasí tó lù iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa Akwa Ibom

Published

Agbẹjọro kan ti tasẹ agẹrẹ ko si pampẹ awọn agbofinro lẹyìn ti fidio to ṣafihan bo ṣe lu iyawo rẹ lù sita.

Ileeṣẹ ọlọpaa Akwa Ibom sọ pe awọn mu arakunrin yi lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o fiya jẹ iyawo rẹ.

Ìṣẹlẹ yí waye nile wọn ladugbo Ewer Estate to wa ni Uyo olu ilu ipinlẹ Akwa Ibom.

Fonran fidio ṣafihan bo ṣe n lu iyawo rẹ tori kọkọrọ ile t'awọn alabagbe to koju rẹ si sọ pe ko ṣẹṣẹ maa lu arabinrin naa nilu bara.

Fidio yi to ti gbode ṣafihan bo ṣe n lu arabinrin naa ti ẹjẹ si n jade lara rẹ titi ti awọn aladugbo fi gba lọwọ rẹ.

Ninu atẹjade alukoro ọlọpaa SP Odiko MacDon sọ pe awọn ko ni faaye gba ki awọn eeyan si ẹtọ wọn lọ lo mu ki Kọmisana pàṣẹ ki wọn mu arakunrin yi ki awọn kan ma ba fi ọwọ ara wọn da seria fun.

Kọmisana naa tun kilọ fawọn to n fiyajẹni lati jáwọ ninu iwa ibajẹ yi to si rọ awọn mọlẹbi lati fi tubi n nubi yanju ọrọ laarin arawọn.

Ẹgbẹ agbẹjọro Uyo sagbekalẹ igbimọ iwadii

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn agbẹjọro NBA ẹka Uyo sọ pe awọn ti gbe igbimọ iwadii kalẹ lati tọ pinpin iṣẹlẹ yi to kan ọmọ ẹgbẹ wọn.

Alaga ẹka Uyo Augustine Udoh sọ pe awọn ko faramọ iwa ifiyajẹni kankan bi iru eleyi to wa ninu fọnran fidio to gbode.

Udoh sọ pe igbimọ iwadii yoo kesi ọkùnrin naa ati iyawo rẹ lati mọ ohun to sẹlẹ ṣaaju eyikeyi ijiya tàwọn yoo ba gbe kalẹ lati ọwọ igbimọ ẹgbẹ naa to wa nidi ibawi.