Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa John Olaleye, olùkọ́ Oriire kẹta tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa ní àhámọ́?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Ẹti to kọja, to jẹ ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni awọn ologun doola awọn akẹkọọ ati olukọ ti awọn agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ninu oṣu Karun un, ọdun yii.

Inu ọpọlọpọ araalu lo dun lẹyin ti awọn eeyan naa pada wale.

Amọ o ṣeni laanu pe awọn agbesunmọmi ọhun ṣekupa olukọ mii, ti ọpọ araalu ko mọ.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ pa ọgbẹni Esiyan Adegboye lasiko ti wọn ya bo ile ẹkọ wọn lọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun yii.

Ọjọ kejilelogun, oṣu Karun un ni wọn sin oku naa nile ijọsin onitẹbọmi kan niluu Ogbomoso.

Lẹyin ti awọn eeyan naa de ahamọ ajinigbe ni wọn ge ori ọgbẹni Micheal Oyedokun, to jẹ olukọ mii, ti wọn si ka fidio iṣẹlẹ naa silẹ fun gbogbo aye lati ri.

Taa ni ọgbẹni Olaleye

Amọ o ṣeni laanu pe lẹyin ti awọn eeyan naa pada sile ti gbogbo mọlẹbi wọn ataraalu mii n dunnu pe wọn ti de ni a gbọ pe wọn pa ọkunrin ọhun ti araalu ko si mọ.

Gẹgẹ bii ohun ti arabinrin Rachael Alamu sọ, ọjọ Aiku, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii ni wọn pa ọgbeni Olaleye si igbekun.

Iṣẹ olukọ ni ọgbẹni Olaleye n ṣe ṣaaju iku rẹ.

O jẹ olukọ nile ẹkọ Community High School, Ahoro-Esinele, ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.

ọdun 2010 ni wọn gba siṣẹ gẹgẹ bii olukọ nile ẹkọ naa.

Ọkunrin naa wa lara awọn olukọ meje ti agbesunmọmi ji gbe ni Oriire.

Ẹsin Kristẹni ni oloogbe naa n ṣe ṣaaju iku ọhun, koda, diakoni ni ninu ijọ to n lọ.

Ọkunrin naa tun jẹ ẹni ti awọn eeyan n sọrọ rẹ gẹgẹ bii ẹni rere lawujọ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun

O ni iyawo, o si ni awọn ọmọ to n duro de ipadabọ rẹ ki iroyin to gbode pe wọn ti gbẹmi rẹ si igbekun agbesunmọmi.