Olubadan ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Alaagba, yí ìpinnu rẹ̀ padà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Published

Olubadan ti ilu Ibadan, Oba Lekan Balogun, CFR ti yi ipinnu rẹ pada lori igbesẹ to gbe lori ọdun Egungun niluu Ibadan lẹyin to se ipade pọ pẹlu Alaagbaas, to jẹ olori egungun nilẹ Ibadan.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Olubadan Ilẹ Ibadan, Ọba Balogun ti paṣẹ ki wọn so ọdun egungun to n lọ lọwọ rọ ni kiakia titi di ọjọ mii.

Aṣẹ oriade yi ko ṣẹyin iroyin to gbode pe awọn oni jagidijagan kan to ṣa sabẹ ọdun eegun yi n ṣe ikọlu, dana sun ile ti wọn si n fọ ṣọọbu awọn araalu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Oba, Oladele Ogunsola fi sita fun awọn akọroyin lọjọ Ẹti ni pe Olubadan ti yii pinnu rẹ pada lẹyin ti Aafin ati olori awọn egungun se ipade pọ lati ri pe jagidijagan ko waye lasiko ti Egun ba jade .

Bakan naa ni Aafin Olubadan ti fi iwe ransẹ si ileeṣẹ Ọlọpaa lati pe abo to peye lasiko ti egun ati ololufẹ ba n jade sita fun ọdun Egun niluu Ibadan.

"Olubadan ti ilẹ Ibadan ko ni fi aye gba iwe jagidijagan to le da alaafia ru niluu Ibadan."

Ninu ọrọ ẹbẹ si Olubadan, Alaagbaas to jẹ olori awọn egungun nilẹ Ibadan ni ki Oba Olubadab jẹ eburẹ, ko si siju aanu wo isẹlẹ naa.

"Ki i se ija laarin egungun meji lo waye sugbọn awọn janduku kan lo wọ aarin wọn ti wọn si da wahala naa silẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni ko ọja ọlọja.

"A wa ki i se oni jagidujagan, ti a setan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati ri pe alaafia jọba lasiko egun .

"A rọ awọn ololufẹ wa lati yago fun iwe panle nitori awọn ọlọpaa wa layika lati fi isinku ofin mu ẹnikẹni ti wọn ba ri to n