Kehinde Ayooloa: Aya kọmíṣọ́nà ọ̀rọ̀ agbègbè ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀, Oluwakemi Ayoola ti jáde láyé

Oloogbe Kehinde Ayoola ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kehinde Ayoola

Published

Arabirnin Oluwakemi Ayoola, to jẹ aya kọmiṣọna fun ọrọ agbegbe nipinlẹ Oyo tẹlẹ, Kehinde Ayoola ti jade laye.

Iṣẹlẹ naa waye lẹyin nnkan bii oṣu mẹwaa ti ọkọ rẹ ọhun ti kọkọ fi aye silẹ.

Oluwakemi jẹ ọjọgbọn ni ẹka eto imọ nipa ọrọ agbẹ ni fasiti Obafemi Awolowo to wa ni Ile Ife, bakan naa lo tun jẹ oluwadii pẹlu ajọ IAR&T, eyii to wa ni Apata, niluu Ibadan.

Iroyin ni oloogbe naa ti kọkọ n ṣaisan tẹlẹ ki ọlọjọ to de, ṣugbọn aisan naa lagbara sii lẹyin ti ọkọ rẹ jade laye lasiko to n ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna ninu ijọba Amojuẹrọ Seyi Makinde to wa lori alefa ijọba ipinlẹ Oyo.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Karun un, ọdun 2020 ni ọkọ oloogbe naa fi aye silẹ, iyẹn lasiko to ku ọsẹ meji ki wọn ṣe ayẹyẹ ọdun kan gomina Makinde lori alefa.

Ọpọ awọn ẹbi, ọrẹ ati alabaṣiṣẹ lo ti bẹrẹ si n daro oloogbe ọhun.