Mamman Daura kò rìn ìrìnàjò sí ìbi kánkan,ko ko ko lara le! - Bashir Ahmad

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Atotonu pọ lori boya Mamman Daura lọ si ilẹ Gẹẹsi lati lọ gba itọju,ṣugbọn bayi ọrọ ti jẹyọ pe ko lọ si ibi kankan.

Oluranlọwọ aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ ayelujara,Bashir Ahmad lo fi ọrọ sita loju opo Twitter rẹ pe ko lọ si ibi kankan.

Arakunrin Bashir sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ pe wọn gbe Mamman Daura lọ si ilẹ Gẹẹsi nitori ko ko ko lara rẹ le.

Bi a ko ba gbagbe lẹnu ọjọ mẹta yi ni iroyin gbode kan pe wọn ti gbe ibatan aarẹ Buhari Mamman Daura tdigba digba lọ si ilẹ Gẹẹsi lọ gba itọju.

Ninu awọn ti ọmọ Naijiria ni igbagbọ pe o lẹnu lọrọ ninu ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ni Mamman Daura wa.

Koda ọrọ bi o ti ṣe lagbara si ni ijọba yi jẹ eleyi to ti n mu fakinfa wa laarin awọn ọmọ rẹ ati iyawo aarẹ Aisha Buhari to ni wọn ko jẹ ki ọkọ ohun ri ijọba ṣe.