You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lai Mohammed: Àtúntò yìí kò wà láti ga àwọn iléeṣẹ́ agbóhùnsẹáfẹ́fẹ́ lọ́rùn
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu àtúnto àwọn ilé iṣẹ́ ìròyin gbogbo lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ, lóri fífún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn orí ayélújára ni ìwé àṣẹ́.
Mínísítà fún ètò ìròyin àti àsà Lai Mohammed lo sọ̀rọ̀ náà, lásìkò tó ń gba àlejo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń ri si akoso igbóhùn sáfẹ́fẹ́ (BON) nílú Abuja.
- A kò fẹ́ 23% tẹ fẹ́ yà sọ́tọ̀ bíí owónàá fáwọn ìjọba ìbílẹ̀ - ALGON
- Á máa ṣíjú àánú wo ẹlẹ́wọ̀n láti mú àdínkù bá ọgbà ẹ̀wọ̀n - Ìjọba Ọyọ
- PFN: Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwádìí wa kò ṣe parí
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
- Ọlọ́wọ̀ tìlú Ọ̀wọ̀ tuntun gorí ìtẹ́, idà àlááfìà ló mú ní Ìpèbí
Ní ìdáhùn sí ìbéèrè ti àdárí BON bèèrè, minisita ní "Mo fẹ́ lo ànfàni yìí lati sọ fun yin pé, ààrẹ Buhari ti búwolu àtuntò ilana igbohun sáfẹfẹ ti yoo si moju to àwọn ibèerè yín"
Ní pàtàkì jùlọ ààrẹ ti buwọ́lu pé, o ti pọn dandan fún àwọn ilé ìròyìn ori ayélujura yala tẹlẹfisan tabi rediò, tó fi mọ awọn ti ilẹ okeere, tí ohun wọn n wọ orílẹ̀ èdè yìí, lati gba iwe aṣẹ lọdọ ijọba.
"Tẹ ba gbọ ọpọ ohun to n jade lori awọn redio ati tẹlifisan wa, ẹ ro pe ogun jija n waye lorilẹede yii ni, abi pe awọn Kristiẹni ati Musulumi ko lee gbe papọ, abi pe iyapa wa laarin ẹkun Guusu ati Ariwa Naijiria."
Lai Muhammed wa fọwọ idaniloju sọya pe igbesẹ naa ko wa lati ga awọn ileesẹ iroyin lọrun, to si rọ ajọ BON lati sugba ijọba nidi aayan rẹ lati mu agbega ba eto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria.