Lai Mohammed: Àtúntò yìí kò wà láti ga àwọn iléeṣẹ́ agbóhùnsẹáfẹ́fẹ́ lọ́rùn

Redio ati ẹrọ alatagba rẹ

Oríṣun àwòrán, @RadioToday

Published

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu àtúnto àwọn ilé iṣẹ́ ìròyin gbogbo lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ, lóri fífún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn orí ayélújára ni ìwé àṣẹ́.

Mínísítà fún ètò ìròyin àti àsà Lai Mohammed lo sọ̀rọ̀ náà, lásìkò tó ń gba àlejo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń ri si akoso igbóhùn sáfẹ́fẹ́ (BON) nílú Abuja.

Ní ìdáhùn sí ìbéèrè ti àdárí BON bèèrè, minisita ní "Mo fẹ́ lo ànfàni yìí lati sọ fun yin pé, ààrẹ Buhari ti búwolu àtuntò ilana igbohun sáfẹfẹ ti yoo si moju to àwọn ibèerè yín"

LAI

Oríṣun àwòrán, lAI MOHAMMED

Àkọlé àwòrán, Gbogbo àwọn oníròyìn ayálujara ni ó ma sanwo ori-Lai Mohammed

Ní pàtàkì jùlọ ààrẹ ti buwọ́lu pé, o ti pọn dandan fún àwọn ilé ìròyìn ori ayélujura yala tẹlẹfisan tabi rediò, tó fi mọ awọn ti ilẹ okeere, tí ohun wọn n wọ orílẹ̀ èdè yìí, lati gba iwe aṣẹ lọdọ ijọba.

"Tẹ ba gbọ ọpọ ohun to n jade lori awọn redio ati tẹlifisan wa, ẹ ro pe ogun jija n waye lorilẹede yii ni, abi pe awọn Kristiẹni ati Musulumi ko lee gbe papọ, abi pe iyapa wa laarin ẹkun Guusu ati Ariwa Naijiria."

Ileesẹ Redio ati ẹrọ alatagba rẹ

Oríṣun àwòrán, @RadioToday

Lai Muhammed wa fọwọ idaniloju sọya pe igbesẹ naa ko wa lati ga awọn ileesẹ iroyin lọrun, to si rọ ajọ BON lati sugba ijọba nidi aayan rẹ lati mu agbega ba eto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria.