Akẹ́kọ̀ọ́ FGC Yauri mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà t'awọn ológun àti ajínigbe kojú ará wọ́n
Awọn to ba BBC sọrọ sọ pe ninu ikọlu to waye laarin awọn agbebọn yi ati ọmọogun Naijiria ni awọn ọmọ yi ti padanu ẹmi wọn.
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Yetunde Olugbenga and Yemisi Oyedepo
Àrùn ń bẹ lóde, ẹ̀yin olùwọ́de EndSARS, ẹ ṣọ́ra fún Covid-19 - Ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀
Owó ìrànwọ́ Covid-19 dé, ìjọba fẹ́ san ₦75bn fún 54,000 olókoòwò
Ìrẹ̀wẹ̀sì ń bá wa torí ìdánwò NECO tẹ ń ṣún síwájú lọ́pọ̀ ìgbà - Akẹ́kọ̀ọ́, ọ̀gá iléèwé
Ọ̀rọ̀ ajé dẹnu kọ̀lẹ̀ yíká Nàíjíríà, àkẹ́kọ̀ọ́, olókoòwò àti òṣìṣẹ́ ọba jókòó sílé
Ìjọba da ológun sí Abuja láti dẹ́kun ìwọ́de, EndSars Protest: Àwọn ológun gba àkóso Abuja láti fòpin sí ìwọ́de
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe ijọba apapọ ti fi awọn smọ ologun ransẹ si igboro ilu Abuja lati dẹkun iwọde EndSARS to n lọ lọwọ.
Bakan naa, awọn ọmọ ologun yii ni wsn ti pasẹ fun lati mu awsn eeyan to n sewọde yii si ahamọ
Iroyin naa ni iwọde naa ti n gbọna miran yọ, to si seese ko jẹ pe awọn janduku ti gba akoso iwọde ọhun.
Iroyin kan tiẹ ni wọn gun ọkan lara awọn oluwọde ni ọbẹ, to si ku sile iwosan.
Koda, awọn afẹhonu han ọhun la gbọ pe wọn ti gbe igi da sna to wọ papakọ ofurufu ilu Abuja, tawọn arinrin ajo ko si le wọ baalu.

Oríṣun àwòrán, @AmnestyNigeria
Àkàrà tú sépo! Ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ BBC tú àṣírí bí SARS ṣe ń fìyà jẹ aráàlú
Èrò ọ̀nà gbẹ̀bí aláboyún ìbejì, tìyá, tọmọ jáde láyé, Child Mortality in Nigeria: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá n wá ẹbí aláboyún tó kú
Arabinrin alaboyun kan ti padanu ẹmi rẹ ati t'awọn ibeji to bi saarin oju ọna niluu Eko.
Iṣẹlẹ to ba ni ninu jẹ yii salaye pe, obinrin naa, Bunmi Muri bi awọn ọmọ yii lopopona Ogo Oluwa, Oke Oshodi, Bariga l'owurọ ọjọ Aiku.
Bunmi la gbọ pe o n lọ wo ọkọ rẹ to n ṣiṣe ladugbo Ogo Oluwa, nigba ti ọmọ sadede mu.
Awọn ara adugbo kan lo sare gbe si ẹgbẹ kan, lati gbẹbi fun, ko le bi awọn ọmọ naa.
Ṣugbọn o se ni laanu pe ati iya ati awọn ọmọ naa ni o padanu ẹmi wọn.
Aladugbo kan salaye pe, obinrin naa bi ọmọ akọkọ lẹrọ ṣugbọn nigba to fẹ bi ikeji lo gb'ẹmi mi.
O ni aisi ẹni to mọ nipa gbigbẹbi lo ṣokunfa iku wọn.
Alukoro ọlọ́pàá nilu Eko Muyiwa Adejobi ti fidi iṣẹlẹ yi mu'lẹ.
Adejobi ni awọn ti gbe oku abiyamọ naa ati t'awọn ọmọ mejeeji lọ si ile igboku pamọ si nile iwosan nla to wa ni Yaba.
O ni awọn n gbiyanju lati wa mọlẹbi arabinrin naa kan.

Oríṣun àwòrán, Operation Blessing
Ẹ wo tọkọtaya tí kò ríran amọ́ tí wọn jẹ́ olùkọ́
Iná jó dórí kókó, Buhari pe Lawan, Gbajabiamila sí ìpàdé lórí ìwọ́de àwọn ọ̀dọ́
Láàrin wákàtí mẹ́ta, wọ́n dá ₦4m fún àkàndá ẹ̀dá tó kópa nínú ìwọ́de
Lizzy Anjorin ń kiri àgọ́ ọlọ́pàá láti gba ọ̀dọ́ afẹ̀hónúhàn, tó wà láhàámọ́ sílẹ̀
Òkú tó jí lọ́jọ́ kejì ní mọ́ṣúárì padà kú síléèwòsàn
Wọ́n kéré sí nọ́mbà, Guardiola jẹ́wọ́ ọ̀gá fún Arteta
Ṣé lóòtọ́ ni àjọ ọlọ́pàá dá Abayomi Shogunle àti Dolapo Badmus dúró?
Salah gbá góòlù ọgọ́rùn ún wọlé, àyẹ̀wò ìgbàlódé VAR d'òkúta sí gààrí Liverpool
Àwọn ọmọ Nàìjíríà fi èpè àti àdúrà ránṣẹ́ sí àwọn adarí pé: ó tó gẹ́!
Wo àfiwé owó oṣù Ọlọ́pàá Nàìjíríà pẹ̀lú akẹgbẹ́ wọn lókè òkun
Alákatakítí ẹ̀sin Islam ló bẹ́ olùkọ́ kan lórí nílùú Paris- Emmanuel Macron, Terror attack: Ààrẹ Emmanuel Macron ní alákatakítí ẹ̀sin Islam ló bẹ́ olùkọ́ kan lórí nílùú Paris

Oríṣun àwòrán, EPA
Aarẹ orilẹede Faranse, Emmanuel Macron ni agbesunmọni alakatakiti ẹsin Islam lo bẹ olukọ kan lori lana nilu Paris.
ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe niṣe lagbesunmọmi ọhun n kigbe "Allahu Akbar" lẹyin to bẹ ori olukọ naa tan.
Amọ, oro to dami ni mo da ọ lawọn ọlọpaa fi ṣe fun un lẹyin ti wọn yibọn pa oun naa nigba to kọju ija si wọn.
Iroyin sọ pe Olukọ ọhun ti fi aworan Anọbi Muhammad han awọn akẹkọọ rẹ.
Aarẹ Macron ni alakatakiti ẹsin naa pa olukọ yii nitori o n kọ awọn akẹkọọ ni ominira lati sọ ohun to wa ninu wọn.
Madron sọ pe awọn alakatakiti kọ ni bori, o ni ijọba yoo maa gbe igbesẹ ni gbogbo igba.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa bayii..
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 181 pẹ̀lú Olùkọ́ lùgbàdì Covid 19 níléèwé aláàdáni kan nípinlẹ̀ Eko
