Wo bí ìséde tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun kéde yóò ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, TWITTER/ ADEGBOYEGA OYETOLA
Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti kede isede jakejado ipinlẹ naa.
Ninu ikede kan to fi sita lori ayelujara Facebook rẹ, Akọwe iroyin ati ikede fun gomina, Ismail Omipidan sọ pe loju ẹsẹ ni isede naa ti bẹrẹ.
Bakan naa lo sọ fun BBC pe alainigbedeke ni isede naa yoo jẹ.
O ni eyi waye nitori bi awọn janduku kan ṣe n kọlu awọn dukia ijọba, ati awọn ileeṣẹ ati ṣọọbu aladani lati ji wọn ni ẹru ko.
"Ijọba gbe igbesẹ yii lati ma le fi opin si iwa ti awọn janduku n hu, ati lati ri i daju pe wọn ko ba nkan jẹ kọja bi o ṣe yẹ."
Isede naa yoo ma a wa fun lati aarọ di alẹ.
Igba keji niyii ti ijọba ipinlẹ naa kede konile-o-gbele lati igba ti iwọde #EndSars ti bẹrẹ, ati rogbodiyan to tẹle.

