You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àjọ INEC kéde Muhammadu Buhari bíi ààrẹ fún sáà kejì
Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan
Àkójọpọ̀ èsì ìbò ń lọ lọ́wọ́ ní Ekiti
Inec n palẹmọ awọn elo idibo to ṣẹku ni Owerri
Awọn ohun elo idibo wọn yi lo ṣẹku lẹyin idibo to waye ni ijọba ibilẹ Owerri Municipal nipinlẹ Imo.
Àwọn òṣìṣẹ́ INEC ti ń dá àlòkù ohun èèlò ìdìbò padà
Èèyàn mẹ́ta kú, méjì farapa ní Sapẹlẹ lásìkò ìdìbò
Ko din ni eeyan mẹta to jẹ Ọlọrun nipe ni agọ idibo kan lagbegbe Amukpe nilu Sapẹlẹ, nipinlẹ Delta lasiko eto idibo to waye lana.
Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ salaye pe, awọn eeyan to jẹ alaisi yii ni ẹmi wọn bọ lati ọwọ awọn afurasi janduku oloselu.
Wọn salaye siwaju pe, awọn janduku naa ni wọn ya wa si agọ idibo, ti wọn si n yinbọn mọ awọn oludibo.
Loju ẹsẹ ni eeyan meji ku, ti ikẹta si gbẹmi mi ni kete to de ile iwosan.
Lẹyin ibo,awọn ara Kano bẹrẹ ọja tita pada
Awọn ọlọja nilu Kano ko jafira lẹyin ti gbedeke irina lasiko idibo wa si opin.
Lawọn ọja ti akọroyin wa de,niṣe ni karakata n lọ lai si idiwọ kankan.
INEC yóò kéde àtúndì ìbò láwọn agbègbè kan torí rògbòdìyàn
Kọmisana kan labẹ ajọ eleto idibo eyi to wa fun eto ilanilọyẹ awọn oludibo, Festus Okoye ni, iroyin ti de eti ajọ Inec lori bi wọn se n ji apoti idibo gbe ni agbegbe Akokotoro ati Bonny nipinlẹ Rivers, Eko ati ni Anambra.
O ni awọn n duro de abọ nipa isẹlẹ ọhun lati ọdọ awọn kọmisana fun ajọ eleto idibo lawọn ipinlẹ.
Okoye ni o seese ki ajọ INEC sun ibo siwaju lawọn ipinlẹ yii.
Obasanjọ, Jonathan àti Abdulsalami dunnu sí bí ìbò ààrẹ ṣe lọ
Awọn olori orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oluṣẹgun Obasanjọ, Goodluck Jonathan ati ajagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar ti dunnu si bi idibo aarẹ ati tile aṣofin agba ṣe lọ.
Obasanjọ ni ẹnikan naa ni yoo bori ninu idije nigba ti ẹlomiran yoo fidi rẹmi.
Ninu ọrọ tiẹ, ajagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar, rọ awọn oludije lati jẹ ki ifẹ orilẹede Naijiria wa lọkan wọn ṣaaju ohun kohun miran.
Aarẹ ana miran Goodluck Jonathan, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa rọ awọn oludije lati fọwọ wọnu ti esi idibo ba jade.
Ibo didi n waye lọwọ ni agọ idibo mẹrin ni Plareau
Eto idibo ti n lọ lọwọ bayii ni agọ idibo mẹrin ni ipinlẹ Plateau.
Eyi waye nitori bi wọn se sun ibo aarẹ ati tawọn asofin agba siwaju di oni ni agọ mẹrin naa.
Gẹgẹ bi Osaretin Imahireogbo, tii se olori ẹka to wa fun ilanilọyẹ awọn oludibo fun ajọ INEC se wi, bi awọn ohun eelo idibo se falẹ, ki wọn to ko wọn de awọn agọ idibo yii, lo sokunfa bi wọn se sun ibo siwaju ni awọn agọ idibo naa.
Ẹ tún wo àwọn òṣèré tíátà míràn tó dìbò
Ọlọpaa Kano n wa ẹni to ji apoti ibo gbe
Article Information - Author, Mansur Abubakar
- Role, BBC Pidgin, Kano
Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa nilu Kano Abdullhi Haruna ti sọ fun BBC pe awọn n wa arakunrin kan ti wọn lo ji apoti ibo gbe ni ijọba ibilẹ Takai.
O ni awọn ni ireti wi pe ọwọ yoo tẹ ọdaran naa lọjọ aiku nitori pe awọn oludibo to wa ni agọ idibo to ti ji apoti gbe ni awọn mọ ọkunrin naa daada.
O tẹsiwaju pe lasiko ti oṣiṣẹ Inec fẹ gbe apoti ibo naa si inu ọkọ lo ja gba to si gbe salọ
Àwọn òṣèré tíátà náà dìbò
Àlàyé rèé lórí bí ìdàlúrú Ijẹbu-Jẹsa ṣe wáyé
Kọmisana Inec àti ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lóri ìdàlúrú Ijẹbu-jẹsa
Janduku oloselu da ilu ru mọjumọ ni Ijẹbu Jẹsa
Awọn osisẹ eleto idibo to le ni igba n sun lọwọ ni ileesẹ ajọ INEC to wa nilu Ijẹbu-Jẹsa nigba tawọn janduku oloselu dojukọ wọn.
A gbọ pe ko si ọlọpa tabi agbofinro kankan larọwọto eyi to mu kawọn janduku oloselu ọhun ri aye pa itu ọwọ wọn.
Iroyin naa ni awọn agunbanirọ meji to tun jẹ osisẹ eleto idibo nibẹ, ni ọta ibọn ba.
Ẹ kaabọ soju opo wa lati mọ bi esi ibo ṣe n lọ lọwọ