You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Àjọ INEC kéde Muhammadu Buhari bíi ààrẹ fún sáà kejì

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan

  1. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Bayelsa

  2. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Delta

  3. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Borno

  4. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Akwa Ibom

  5. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Cross river

  6. PDP pè fún ìwọ́gilé èsì ìdìbò ààrẹ ní ìpínlẹ̀ mẹ́rin

    Ẹgbẹ oṣelu PDP ti pe fun iwọgile awọn esi idibo aarẹ lati ipinlẹ Zamfara, Nasarawa, Bornu ati Yobe.

    Ẹgbẹ oṣelu PDP pe ipe yii nibi ipade kan ti wọn ṣe pẹlawọn oniroyin ni alẹ ọjọ iṣẹgun ni ilu Abuja.

    Ẹgbẹ oṣelu PDP ṣalaye pe ni ipinlẹ Yobe iye awọn eeyan to dibo pọ ju iye awọn oludibo ti wọn forukọ silẹ ni ipinlẹ naa.

    Kabiru Taminu Turaki to jẹ igbakeji oludari agba igbimọ ipolongo PDP ṣalaye pe nipasẹ ofin eto idibo orilẹede Naijiria, iru ibo bẹ ko lẹsẹ nlẹ.

  7. Wike ní àwọn ọmọogun fẹ́ 'dìtẹ̀ gbá'jọba' lọ́wọ́ òun

    Gomina Wike ti wi pe ileeṣẹ ọmọogun Naijiria n gbimọran ati ‘ditẹ gbajọba’lọwọ oun.

    Ni ọjọru ni Wike sọrọ yii lasiko to n fesi si ẹsun ti ileeṣẹ ọmọogun fi kan an pe o fẹ fi owo ra awọn oṣiṣẹ rẹ kan fun aṣemaṣe lasiko eto idibo apapọ ọjọ satide ko kọja.

    Ọrọ rẹ yii waye lẹyin ti ileeṣẹ ọmọogun ti fi ẹsun kan gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike pe awọn oṣiẹ ile ijọba kan wa ti wọn gbe owo ẹyin tọ awọn ọmọogun kan wa lati ṣe awọn iwa aits kan ti yoo gbe gomina naa lẹsẹ lasiko idibo ọhun.

    Wike ni oun ti pariwo sita lọpọ igba ṣaaju idibo apapọ to kọja lọ pe ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ti sọ ara wọn di ohun elo awọn eeyan kan lati ṣe magomago lasiko idibo naa ati lati da rukerudo silẹ ni ipinlẹ ọhun.

    O ni oun si tun sọọ sita nigba naa pe wọn n lepa ẹmi oun eleyii ti ko si ẹnikẹni lara awọn ọga ileeṣẹ ọmọogun Naijiria to fesi tabi gbe igbesẹ le lori.

  8. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Taraba

  9. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Katsina

  10. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Kano

  11. Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Plateau

  12. Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ Imo ree

  13. Wike fẹ́ lò wá láti da ìdìbò rú pẹ̀lú rìbá - Iléeṣẹ́ ológun

    Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti fẹsun kan gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike pe o gbiyanju lati fi owo ra awọn ọmọ ogun lasiko idibo to waye nipinlẹ Rivers.

    Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun fi sita, wọn ni Gomina Wike gbe owo banta-banta lọ fun awọn ọmọ ogun Ẹkun kẹfa ileesẹ ologun, lati da eto idibo ru fun anfaani ara a rẹ, to si tun n fi ẹsun ṣiṣe ègbè kan awọn ọga ileeṣẹ ologun.

    Wọn fi ẹsun kan pe awọn oluranlọwọ fun Wike gbe owo lọ si ọgba banki apapọ Naijiria to wa nilu Port Harcourt gẹgẹ bi owo ẹyin fun awọn ọmọ ogun to wa nibẹ lọjọ kẹtalelogun oṣu Keji, ti i ṣe ọjọ idibo.

  14. Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Edo

  15. Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Ogun ree

  16. , Esi ibo ipinlẹ Eko

  17. , Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Bauchi

  18. Ẹ kaabọ pada si kika esi ibo aarẹ

  19. Esì ìbò tí àjọ INEC ti kéde

  20. Èsì ìbò Adamawa rèé