You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àjọ INEC kéde Muhammadu Buhari bíi ààrẹ fún sáà kejì
Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan
Saraki ní kùdìẹkudiẹ́ lásìkò ìbò kún ohun to fa ìjákulẹ̀ òun
Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki ti ṣalaye awọn idi ti oun atawọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara fi fidirẹmi, ninu eto idibo apapọ to waye ni ọjọ Satide.
Saraki sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita, to fi ki awọn to gbe'gba oroke nibi eto idibo naa ku oriire.
Saraki ni, bi o tilẹ jẹ wi pe alaafia jọba lasiko idibo naa, sibẹ aikun oju oṣuwọn awọn ẹrọ ayẹkaadi idibo wo, titẹka kọja iye ibo to yẹ atawọn iwa aitọ miran kaakiri awọn ibudo idibo ni ipinlẹ naa, kun ohun to faa ijakulẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara.
Esi ibo Anambra
Awọn sẹnetọ tun sun ijoko wọn siwaju
Awọn ọmọ ile aṣofin agba Naijiria pada sile loni fun ijoko wọn lẹyin ti wsn lọ fun isinmi ranpẹ ṣaaju eto idibo gbogboogbo
Ṣugbọn ṣaa, wọn tun ti sun ijoko wọn si ọjọ kejila, oṣu Kẹta ọdun 2019.
Esi ibo aarẹ ni Kaduna
Ta ni ibo awọn ipinlẹ yii yoo ja mọ̀ lọwọ.
Buhari ati Atiku n fa ibo ipinlẹ́ Kano, Katsina, Kaduna ati Kebbi mọ ara wọn lọwọ bayii.
Ibo naa ko fi sibi kan ju ibi kan lọ.
Amọ lẹyin o rẹyin, ta wa ni yoo ja mọ lọwọ bayii?
Esi ibo aarẹ ipinlẹ Jigawa ree
Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Niger
Esi ibo kika bẹrẹ pada ni Abuja
Oludije gomina APC Kwara bawọn eeyan Kwara yọ
Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahman ti sọ faraye pe, 'isẹgun eto idibo ọjọ Satide lo mu awọn olugbe ipinlẹ Kwara kuro loko ẹru Farao tilẹ Egypt.'
Abdulrazaq di aseyọri naa ru awọn eeyan ipinlẹ Kwara, to si ki wọn eeyan ipinlẹ naa 'ku oriire ajabọ loko ẹru.'
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Ilọrin, Abdulrazaq ni wọn ti kọ orukọ wọn sinu itan pe wọn wa lara awọn to jijagbara lati bọ ninu igbekun oselu nipinlẹ́ Kwara.
Ẹ maṣe bawọn ja lori esi ibo aarẹ ni Kano - Kwankwanso
Sẹnẹtọ Rabiu Musa ti parọwa si awọn ọmọlẹyin rẹ lati maṣe kọju ija si ẹnikẹni nitori esi ibo aarẹ ti wọn kede.
Gomina Kano tẹlẹri ohun fesi yii fun awọn akọroyin lẹyin ti wọn ṣe akojọpọ esi ibo Kano tan.
O ni awọn ti tẹle gbogbo igbeṣẹ to yẹ labẹ ofin lati tako esi naa ati pe, ohun ko fẹ ki awọn ọmọlẹyin kwankwansiyyah kọju ija sẹnikẹni bi kii ṣe ki wọn ma gbaradi de ibo Gomina to n bọ lọna.
Awọn olutọpinpin ibo ni akude wa ninu ibo Satide
Ajọ to n tọpinpin eto idibo labẹ ajọ isọkan ilẹ Europe, ti kede pe ajọ̀ eleto idibo ilẹ́ wa ni awọn kudiẹkudiẹ kan lori eto idibo to waye lọjọ Satide.
Bakan naa ni awọn onwoye ibo naa ni bi ẹ́mi eeyan to to marundinlogoji se bọ lọjọ Satide, ati bawọn ohun eelo idibo se pẹ de sawọn agọ idibo kan, wa lara awọn akude to ba INEC.
Maria Arena, tii se asofin lan labẹ ajọ EU lo gbe ọrọ naa kalẹ nilu Abuja nigba to n jabọ ohun toju rẹ ri lasiko eto idibo naa.
Abba Moro moke ninu ibo sile asofin agba ni Benue
INEC ti kede Abba Moro tẹgbẹ oselu PDP pe oun lo jawe olubori ninu ibo sile asofin agba lẹkun guusu ipinlẹ Benue.
Moro, tii se minisita tẹlẹ laye ijọba Jonathan, lo fi ẹyin alatako rẹ, Ochagwu Lawani janlẹ
PDP: 85,162
APC: 47,721
INEC ko ni se idibo mọ nijọba ibilẹ meji ni Rivers
Ajọ eleto idibo ko ni se eto idibo miran fun ibo aarẹ ati tawọn asofin apapọ nijọba ibilẹ Akuku Toru ati Bonny, nipinlẹ Rivers.
Alakoso eto idibo nibẹ, Ọjọgbọn Eniefiok Essien lo gbe esi ibo naa lọ silu Portharcourt.
Rogbodiyan nla lo waye nijọba ibilẹ mejeeji naa ljọ Satide eyi to mu kiajọ INEC pinnu pe lati mase fi awọn ohun eelo idibo ransẹ si agbegbe naa, ti eto idibo ko si waye rar nibẹ.
Saraki kò fi ipò kẹta tó dìmú ṣèlú l‘óore ní Kwara - Aráàlú faraya
Àjọ INEC so ìkede ìdìbò rọ̀ di agogo mẹ́wàá ọjọ́ Ìṣẹ́gun., Oorun ayọ̀ la ó sùn.
Ninu awọn ipinlẹ mọkanla ati olu iluu ilẹẹwa ti ajọ INEC kede ni ọjọ Aje, Abubakar Atiku ko ipinlẹ marun un, Muhammadu Buhari si ko ipinlẹ meje.
Atiku Abubakar: Enugu, Ebonyi, Abia, Ondo ati olu iluu ilẹẹwa, Abuja.
Muhammadu Buhari: Ekiti, Oṣun, Kwara, Nasarawa, Kogi, Gombe ati Yobe.
Esi ibo aarẹ ni Ebonyi
Esi ibo aarẹ ni Enugu
Buhari ṣe àbẹ̀wò sí olú iléeṣẹ́ ìpolongo rẹ̀ l'Abúja
Lẹyin to gunlẹ si ilu Abuja lọsan oni, aarẹ Muhammadu Buhariṣe abẹwo si olu ileeṣẹ ipolongo rẹ nilu Abuja nibi ti wọn ti fi bi esi idibo aarẹ to n lọ lọwọ tiṣe n lọ si.
Esi ibo aarẹ ni Yobe