You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Àjọ INEC kéde Muhammadu Buhari bíi ààrẹ fún sáà kejì

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan

  1. Esi ibo aarẹ ni Abia

  2. Esi ibo aarẹ ni Ondo

  3. Saraki kùnà ìdìbò, ṣùgbọ́n kò kùnà ìfẹ́ ìyàwó rẹ̀

    "Àyò mi, olówó orí mi, ìwúrí àti ìdùnnú ńlá lo ń jẹ fún mi lọjọkọjọ"

    Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ látẹnu Toyin, ìyàwó Bukọla Saraki sí ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó pàdánù ìdìbò sílé aṣòfin àgbà.

  4. Ajimọbi ki alatako rẹ ku oriire pe o yege ibo

    Gomina Abiọla Ajimọbi to fidirẹmi ninu idibo sile aṣofin agba lẹkun idibo gusu ipinlẹ Ọyọ, ti ki oludije fẹgbẹ PDP, Kọla Balogun to bori ku oriire.

    Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun gomina Ajimọbi lori ọrọ ibanisọrọ, Bọlaji Tunji fi sita, Gomina Ajimọbi ni lootọ oun padanu ijoko aṣofin agba naa, sibẹ ijafafa ẹgbẹ oṣelu APC ninu awọn esi idibo yoku ko lee jẹ ki inu oun bajẹ.

    Gomina Ajimọbi ni, oun tẹwọgba esi idibo naa, oun si tun ki gbogbo awọn oludije ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa to jawe olubori ku oriire.

  5. PDP kọ èsì ìbò ààrẹ

    Ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ti sọ pe, ohun ko ni gba awọn esi idibo aarẹ ti ajọ eleto idibo INEC ti n kede rẹ.

    Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọọba Uche Secondus ni awọn esi ibo ti ajọ INEC n kede ko tọna rara.Ọmọọba Secondus sọrọ yii nibi ipade awọn oniroyin to waye niluu Abuja lọjọ Aje.

    Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC, Aarẹ Muhammadu Buhari lo yege nipinlẹ Ekiti, Oṣun, Kogi, Nasarawa ati Kwara gẹgẹ bi esi ti ajọ INEC kede.

    Ṣugbọn Atiku Abubakar to jẹ oludije fẹgbẹ alako PDP lo jawe olubori lolu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

  6. Esi ibo aarẹ ni Gombe

  7. Esi ibo aarẹ ni Kogi

  8. Ẹgbẹ oselu Mimiko tako esi ibo sile asofin agba l‘Ondo

  9. Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Nasarawa

  10. Esi ibo aarẹ ni Kwara

  11. INEC ko tii kede esi ibo Godswill Akpabio

    Oludari ajọ eleto idibo nipinlẹ Akwa Ibom, Mike Igini ti kede pe oun ko ti fi esi ibo sile asofin agba lẹkun Ikot Ekpene sita rara.

  12. Jimi Agbaje tako esi ibo ni Eko

    Oludije gomina fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Eko, Jimi Agbaje, ti fi aake kọri pe oun ko ni tẹwọgba esi ibo ti wọn ti tọwọ bọ loju.

    Agbaje ni wahala ati idunkoko mọni ẹgbẹ oselu APC ti pọ lapọju lawọn agbegbe ti ẹgbẹ PDP fidi mulẹ si bii Oshodi ati Ọjọ.

    O ni ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo ko sisẹ daada lawn agbegbe kan eyi to lọwọ magomago ninu.

    • Esi ibo aarẹ ni Abuja

    • Ibo kika n lọ lọwọ ni Abuja

    • INEC kede pe ibo Kogi East ko tii pari

      INEC kede pe ibo ẹkun idibo ila oorun ipinlẹ Kogi ko tii pari.

      Alaye Inec ni pe rogbodiyan waye lasiko ibo naa, ti awọn ibo ti wọn ko gba wọle si pọ lapọju.

      Amọ sa, akojọpọ esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Kogi ti pari, ti wọn si ti n gbe lọ si Abuja.

    • Esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Ọsun

    • Bí èsì ìbò ààrẹ ní Ekiti ṣe lọ

    • Obinrin akọkọ ninu ibo 2019 wọle sile asofin agba lẹkun ariwa

      Ẹkun idibo aarin gbungbun Adamawa.

      Aishatu Dahiru Ahmed (Binani) APC - 188, 526

      PDP - 96, 530

      ADC - 36, 030

      Aishatu Dahiru ni obinrin akọkọ ti yoo dibo wọle sile asofin agba lẹkun ariwa orilẹede yii ninu ibo ọdun 2019.

    • Ibo kika si n lọ lọwọ ni Eko

    • Gbajabiamila ni yóò jẹ àṣojúṣòfin Yorùbá akọkọ ti yoo lọ lẹ́ẹ̀marùn ún léra

      Olori ọmọ ẹgbẹ oselu to pọ julọ nile asofin tawọn asoju, Femi Gbajabiamila lo jawe olubori ninu ibo sile asoju sofin ni ẹkun idibo Surulere Kinni nipinlẹ Eko.

      Gbajabiamila to n soju ẹgbẹ APC lo gbo ewuro si oju Michael Adewara ti ẹgbẹ oselu PDP.

      Igba yii ni igba karun un ti Gbajabiamila a lọ