Agbofinro mu Galadima ni Abuja, Wọn ti mu Bala Galadima nilu Abuja
Awọn agbofinro ti fi pakute ofin mu agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP, Buba Galadima nilu Abuja lọjọ Aiku.
Ọkan lara mọlẹbi rẹ to ba BBC sọrọ sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo DSS lo mu u nile rẹ lọsan ọjọ naa lasiko to jade.
Ṣaaju lọjọ Abamẹta ni agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo ibo fun Muhammadu Buhari, Festus Keyamo pe fun fifi panpẹ ofin mu Galadima, nitori pe ‘o kede oludije PDP gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori lasiko ti wọn ṣi n ṣe akojọpọ esi idibo lọwọ.
Amọ ṣaa, ajọ DSS ko ti sọ nkankan lori ọrọ naa.
Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti n polongo fun itusilẹ rẹ.
Buba Galadima wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ to fi APC silẹ lati da igun kan ti wọn pe ni R-APC silẹ.