Àwọn olùdìbò sọ òkò pa ọkùnrin kan tí wọn ló da ìbò rú

Lónìí, ọjọ́ kẹtà oṣù kejì ọdún 2019 ni ìdìbò tí àjọ elétòìdìbò, INEC sún síwájú fún ààrẹ àti ilé aṣofin àgbà.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Ijoba Ibile Ado...o yà ká lọ di ó. Àwọn agunbaniro tí setan pelu ohun èlò idibo gbogbo láti máa lọ sí àwọn woodu wọn lè yọ ó soka

    Ado Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Ado Ekiti
  2. Iya arugbo yii ti ji jade ni ilu Ado Ekiti lati lọ tẹka.

    Ipinlẹ Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Ekiti
  3. Láti ìpínlẹ̀ Ekiti

      • Author, Foluke Ogunbayo
      • Role, Broadcast Journalist

    Awọn eeyan ti n tu jade ni wọọdu kẹwa ibudo idibo keje ni ilu Ado Ekiti ipinlẹ Ekiti.

    Lati owurọ kutu hai ni awn ara ipinlẹ Ekiti ti mu irinajo lati lọ dibo pọn.

    Ipinlẹ Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Ekiti
  4. Awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ idibo!

    Ó dé, ó dé, ìdìbò tà ń wí dé!

    Ẹ ku ojumọ gbogbo ọmọ kaarọ o jiire, gbogbo eto ti to a si ti bẹrẹ si ni jabọ bi gbogbo eto idibo ṣe n lọ lonii latẹnu Yetunde Olugbenga.

    Kẹrẹ kẹrẹ ọjọ idibo Naijiria ti wọle de. Lonii ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019 ni gbogbo ọmọ Naijiria yoo yan aarẹ ati awọn aṣoju ile igbimọ aṣofin agba.

    Kaakiri awọ́n ipinlẹ Naijiria lawọn akọroyin BBC ti wa lati maa mu iroyin wa fun un yin.